Ṣé lóòótọ́ ni pé àṣẹ máa ń wà lẹ́nu ọmọ tó bá kọ́kọ́ hu eyín òkè?

Àkọlé fídíò, Eyín òkè
Ṣé lóòótọ́ ni pé àṣẹ máa ń wà lẹ́nu ọmọ tó bá kọ́kọ́ hu eyín òkè?

Nígbà tí a bá bimọ́ tuntun, tí ọmọ náà sì ń dàgbà, lára ohun tí a máa ń retí lára ìdàgbàsókè ọmọ ni eyín híhù.

Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe máa ń jẹ́ eyí ìsàlẹ̀ ni ọ̀pọ̀ ọmọdé máa ń kọ́kọ́ hù ṣùgbọ́n èyí kìí rí bẹ́ẹ̀ ní gbogbo ìgbà bó ṣe jẹ́ pé àwọn ọmọ míì máa ń kọ́kọ́ mu eyín òkè jáde.

Ọ̀pọ̀ ìgbàgbọ́ ló sì rọ̀ mọ́ kí ọmọ kọ́kọ́ hu eyín òkè.

Ìgbàgbọ́ àwọn Yorùbá ni pé ọmọ tó bá kọ́kọ́ hu eyín òkè máa ń ní àṣẹ lẹ́nu, tó sì jẹ́ pé gbogbo nǹkan tí irú ẹni náà bá sọ ló máa ń wá sí ìmúṣẹ.

Se lóòtọ́ọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí bí?

Ọmọdé tó fẹ eyín rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Yorùbá máa ń pè iru ọmọ tó bá kọ́kọ́ hu eyín òkè ní awíyarè nítorí nǹkan tí ọmọ náà bá sọ, yóò máa wá sí ìmúṣẹ ni - Ifayemi Elebuigbon

Araba ìlú Osogbo, Olóyè Ifayemi Elebuibon sọ fún BBC News Yorùbá pé ọmọ tó bá kọ́kọ́ hu eyín òkè maa n ni aṣẹ lẹnu.

O ni Yorùbá máa ń pè iru ọmọ bẹẹ ní awíyarè nítorí nǹkan tí ọmọ náà bá sọ, yóò máa wá sí ìmúṣẹ.

"Awíyarè kìí wí tirẹ̀ kó má ṣẹ, tí ọmọ náà bá ti fi ahọ́n kan ọ̀gangan eyín náà, bó jẹ́ ẹyọ̀kan tàbí méjì ni, nǹkan tó bá wí máa ṣẹ."

Araba ni etutu wa ti maa n fi yọ iru eyin oke baa.

Ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì kò fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọmọ tó bá kọ́kọ́ hu eyín òkè yóò ní àṣẹ lẹ́nu - Dokita olùtọjú eyín

Àmọ́ àwọn dókítà, onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kò gba èyí gbọ́.

Comfort Ogundiran, tó jẹ́ dókítà nípa ìmọ̀ eyín sọ fún BBC pé, ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì kò fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọmọ tó bá kọ́kọ́ hu eyín òkè yóò ní àṣẹ lẹ́nu.

Dókítà Ogundiran ní gbogbo ọmọ ló ní àkókò tí wọ́n máa dàgbà, tí ẹ̀yà ara wọn kọ̀ọ̀kan máa jáde èyí tí àwọn olóyìnbó máa ń pè ní "development schedule".

Gbogbo ìgbà tí eyín kọ̀ọ̀kan bá dá, ló máa jáde, tó bá jẹ́ eyín òkè ló kọ́kọ́ máa jáde, ló máa jáde.

Nǹkan míì tí Dókítà Ogundiran tun sọ ni pé, tí ọ̀kan lára àwọn òbí ọmọ bá kọ́kọ́ hu eyín òkè, ó ṣeéṣe kí ọmọ náà kọ́kọ́ hu eyín òkè.