Tinubu sọ ìdáríjì Maryam Sanda tó pa ọkọ rẹ̀ di ẹ̀wọ̀n ọdún méjìlá, yọ ìdáríjìn fáwọn èèyàn tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn le gan

Aworan ibi ti wọn ti n mu Maryam Sanda lọ pẹlu fọto oun ati ọkọ rẹ

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Àkọlé àwòrán, Aworan ibi ti wọn ti n mu Maryam Sanda lọ pẹlu fọto oun ati ọkọ rẹ
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Nigba ti iroyin jade l'Ọjọru ana pe Aarẹ Bola Tinubu ti ṣe atunṣe si idajọ awọn eeyan to n jiya ofin to kede aforiji fun tẹlẹ, ohun to kọkọ gbode ni pe wọn ti yọ orukọ Maryam Sanda, obinrin to gun ọkọ rẹ pa ni 2017 kuro lara awọn ti yoo ri aanu naa gba.

Iroyin naa sọ pe atẹjade tuntun ti Bayo Onanuga, Olugbani-nimọran Tinubu lori eto iroyin fi sita, ti yọ orukọ Maryam ati awọn ọdanran ti ẹṣẹ wọn le gan-an kuro ninu awọn ti yoo ri idariji gba.

Eyi lo mu ọpọ eeyan maa ro pe idajọ iku ti kootu da fun obinrin naa ni 2020 yoo pada ṣẹ lori rẹ niyẹn

Ṣugbọn nigba ti yoo fi di ọwọ alẹ, ti afikun orukọ tun jade wa lati ọfiisi Aarẹ, ọrọ naa yi pada.

Iwe orukọ tuntun to jade ṣafihan orukọ Maryam Sanda gẹgẹ bii ọkan lara awọn ti ijọba din ijiya ẹṣẹ wọn ku, ki i ṣe pe wọn yoo pa a rẹ.

Ọwọ isalẹ pẹpẹ ni orukọ naa wa ninu atẹjade orukọ tuntun ti ijọba fi lede.

Lodi si bi ọpọ eeyan ṣe ti ro pe Maryam Sanda ti padanu anfaani naa nigba ti orukọ rẹ ko ti jade lakọkọ, ti wọn ro pe iku ni eyi tumọ si fun obinrin naa, ileeṣẹ Aarẹ ṣalaye pe ki i ṣe idajọ iku.

Ẹwọn odun mejila ni Aarẹ sọ ijiya Maryam da, dipo idajọ iku tabi ai ri idariji gba rara to kọkọ jade.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹ o ranti pe ṣaaju ni Aarẹ Tinubu ti kede pe oun da Sanda to gun ọkọ rẹ lọbẹ pa silẹ lẹyin ọdun mẹfa to ti lo lẹwọn.

Bakan naa ni Aarẹ kede orukọ awọn eeyan miran ti wọn n jiya idajọ lọwọ, pẹlu awon miran to tilẹ ti ku tipẹ bii Herbert Macaulay, Tinubu ni oun mu oju kuro ninu ẹṣẹ wọn.

Ṣugbọn ẹni ti ẹnu kun ju lori idariji ẹṣẹ naa ni Mariam Sanda, kaluku lo n sọ pe obinrin naa ko yẹ lẹni to yẹ ki ijọba dariji rara, nitori ọkọ to fẹ ẹ sile, to bimọ meji fun lo gun pa ni 2017.

Bakan naa ni awọn eeyan ti ẹsun wọn le pupọ bii apaayan, awọn to gbe oogun oloro, awọn to n ko ọmọ ọlọmọ ṣowo ẹrú, awọn awakusa lọna aitọ ati bẹẹ bẹẹ lọ ti ẹnikẹni ko lero pe wọn le gba itusilẹ, ri aanu gba ninu ikede akọkọ ti Tinubu ṣe.

Eyi di ariwo karikari.

Abajade ariwo ati kikoro oju si igbesẹ naa lo bi atunṣe tuntun yii.

Nigba to n ṣalaye nipa atunṣe orukọ tuntun naa, Bayo Onanuga sọ pe o ṣe pataki pupọ.

Olugba- Aarẹ nimọran lori iroyin naa ṣalaye pe lẹyin ipade pẹlu awọn igbimọ ipinlẹ ati ifilọ awujọ ni igbesẹ yii waye.

O fi kun un pe o tun jẹ ọna kan lati fi han pe idajọ ododo ati fifi ẹtọ awọn eeyan ti nnkan ṣẹlẹ si le wọn lọwọ jẹ dandan.

Onanuga ni bi ijọba ṣe ni ki Maryam ṣẹwọn ọdun mejila yii waye lati ara aanu ati bi obinrin naa ṣe ti yipada si daadaa.

O ni ti awọn ọmọ meji to bi fun ọkọ rẹ naa wa lara ohun ti ijọba wo ti wọn fi din ijiya rẹ ku, ko le baa le ṣe iya wọn lọjọ kan.

Wọ̀nyí ni orúkọ tuntun tí ìjọba Tinubu kede

Àwọn tó gba àforíjì

1Abilekọ Anastasia Daniel Nwaobia

2 Amofin Hussaini Alhaji Umar

3. Ayinla Saadu Alanamu

4. ỌnarebuFarouk M. Lawan

5. Herbert Macaulay

6. Major General Mamman Jiya Vatsa

7. Ken Saro Wiwa

8. Saturday Dobee

9. Nordu Eawo

10. Daniel Gbooko

11. Paul Levera

12. Felix Nuale

13. Baribor Bera

14. Barinem Kiobel

15. John Kpuine

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2

Àwọn tí wọ́n yí ìdájọ́ ikú padà sí ẹ̀wọ̀n gbére fún

1. Emmanuel Baba

2. Abubakar Usman

3. Khalifa Umar

4. Mohammed Umar

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 3

Àwọn tí wọ́n ṣíjú àànú wò nípa ìjìyà wọn

1. Oroka Michael Chibueze

2. Adesanya Olufemi Paul

3. Daniel Bodunwa

4. Hamza Abubakar

5. Buhari Sani

6. Mohammed Musa

7. Muharazu Abubakar

8. Ibrahim Yusuf

9. Saad Ahmed Madaki

10. Ex-Corporal Michael Bawa

11. Richard Ayuba

12. Adam Abubakar

13. Emmanuel Yusuf

14. Chinedu Stanley

15. Johnny Ntheru Udor.

O kere tan, orukọ bii aadọta (50) lo ti kuro ninu atunṣe ti wọn ṣe naa.