Hurricane Melissa: Ìjì líle wọ Cuba, àwọn aráàlú sá àsálà fún ẹ̀mí wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìjì líle, Hurricane Melissa ti balẹ̀ sí orílẹ̀ èdè Cuba, tó sì wà ní ìpele kẹta lòdì sí ìpele karùn-ún tó wà nígbà tó balẹ̀ sí Jamaica lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.
Àjọ tó ń mójútó ìjì líle ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà, US National Hurricane Center, NHC ló fìdí èyí múlẹ̀.
NHC tó ń lo Saffir-Simpson Hurricane Wind Scale láti ṣe ìgbéléwọ̀n bí ìjì náà ṣe lágbára tó, sọ pé ipele kìíní ló kéré jù nígbà tí ipele karùn-ún jẹ́ èyí tó lágbára jùlọ.
Bí ìjì náà bá ṣe ń fẹ́ sí ni wọ́n fi ń ka bó ṣe máa lágbára tó.
Àjọ NHC sọ pé 120mph ni ìjì Hurricane Melissa ti balẹ̀ sí Cuba ní nǹkan bíi aago mẹ́rin ìdájí tó dé orílẹ̀ èdè náà.

Oríṣun àwòrán, AFP
"Ìjì líle Hurricane Melissa jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìjì líle tí yóò kan Cuba láti ọdún 2017"
Wọ́n wòye pé ó léwu púpọ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ rẹ̀ kò le tó ti bó ṣe balẹ̀ sí Jamaica.
Àjọ náà ṣe ìkìlọ̀ fáwọn èèyàn agbègbè Granma, Santiago de Cuba, Guantanamo, Holguin, àti Las Tunas tó fi mọ́ àwọn èèyàn agbègbè gúúsù ìlà oòrùn àti ààrin gbùngbùn Bahamas láti gbáradì fún ìjì náà.
Akọ̀ròyìn ojú ọjọ́ BBC, Simon King sọ pé ìjì líle Hurricane Melissa jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìjì líle tí yóò kan Cuba láti ọdún 2017.
Lẹ́yìn èyí ni ìrètí wà pé ìjì náà yóò mórílé Bahamas àti Bermuda.
Níṣe ni àwọn èèyàn ní Haiti àti ìlà oòrùn Cuba ti ń kó ló sáwọn ilé ẹ̀kọ́ àti ilé ìjọsìn láti sá àsálà fún ẹ̀mí wọn.
Hurricane Melissa: Ẹ̀kún omi/ìjì líle ń dààmú Jamaica, mú ẹ̀mí lọ

Oríṣun àwòrán, CIRA/NOAA VIA REUTERS
Wọn ti gbọ pe yoo ṣẹlẹ, wọn si ti n gbaradi ṣaaju rẹ, iyẹn ẹkun omi alagbara kan ti wọn pe ni Hurricane Melissa, ti awọn onimọ nipa oju ọjọ sọ pe yoo ṣẹlẹ lorilẹede Jamaica.
Hurricane Melissa ọhun ti mu ẹmi eeyan mẹta lọ ni Jamaica, o kere tan.
Ni Haiti ati Dominican, eeyan mẹrin ni wọn fidi rẹ mulẹ pe wọn ti dagbere faye.
Ẹka to n ri si iṣẹlẹ yii, US National Hurricane Center (NHC), fidi ẹ mulẹ pe orilẹede Jamaica ti bẹrẹ si i koju iṣoro, yoo si fori sọ aaye kan loni ọjọ Iṣẹgun.
Apapọ ẹkun omi ati iji lile to ti pa awọn eeyan yii ni wọn lo wa ni ipele karun-un.
Bo si tilẹ jẹ pe maili marundinlọgọta (55 miles) (90 km) lo ti wa si erekusu, NHC ni awọn to wa ni maili ọgbọn si marundinlaadọta (30 to 45 miles) sibẹ naa yoo nipin ninu rẹ.
" Melissa yoo de Jamaica ati Guusu/ Ila-Oorun Cuba, gẹgẹ bo ṣe jẹ iji ẹlẹkun omi to le."
Ajọ to n ri si oju ọjọ l'America lo sọ bẹẹ.
Ẹkun omi yii ni wọn lo lagbara ju ninu iru rẹ to ti ṣẹlẹ lọdun yii, ati pe iru rẹ fẹrẹ ma ṣẹlẹ ri ni erekuṣu Jamaica.
Ọwọ lile ni iwọn 175mph (282km/h), ni Hurricane Melissa n gbe bi ajọ oloju ọjọ ṣe fidi rẹ mulẹ.
Awọn onimọ nipa iṣẹlẹ yii ti kilọ, pe Melissa yii le fa arọọda ojo rẹpẹtẹ lawọn agbegbe kan, eyi ti yoo mu ẹkun omi to le pa eeyan dani, ti ilẹ yoo si ya ni awọn ibi kan.
Ìṣẹlẹ yii ti mu ki ijọba paṣẹ pe ki awọn eeyan kuro ni apa ibi kan ni olu ilu ti i ṣe Kingston

Oríṣun àwòrán, Reuters
Bẹẹ ni gbogbo erekusu naa ni wọn ti ka si aaye to lewu.
Iforisọ aaye gbigbẹ rẹ ti wọn pe ni Hurricane landfall maa n ni agbara lori ilẹ.
Awọn nnkan bii iji lile, ojo ti ko ni i da bọrọ, omiyale ati bẹẹ bẹẹ lọ ni abajade Hurricane ti wọn ni o ṣee ṣe ko waye lọjọ Iṣẹgun.
Awọn eeyan to n gbe agbegbe Carribean ṣalaye fun BBC pe gbogbo ipa awọn lawọn n sa lati gbaradi, ṣugbọn wọn ni awọn ko ri iru eyi ri laye awọn.
Nigba ti Hurricane Melissa ba kan ilẹ gbigbẹ, ojo oniwọn ọgbọn(30 inches of rain (76cm) ni awọn onimọ sọ pe o le rọ ni Jamaica, ati iji to n ja ni iwọn 175mph (282km/h)
*Òye foju han pe idaamu nla ati ọṣẹ́ pupọ ni ẹkun omi yii yoo mu ba Jamaica, pẹlu bi awọn ile gbigbe ati ileeṣẹ, nnkan amayedẹrun gbogbo ṣe ti ṣegbe.
Ijọba ti ni ki wọn ti awọn ileewe ati papakọ ofurufu pa.
Yatọ si awọn mẹta to ti di oloogbe, eeyan mẹẹẹdogun mi-in ni wọn tun ti farapa nibi ti wọn ti n gbaradi fun ẹkun omi ati iji lile.
Olootu ijọba ilẹ Jamaica, Andrew Holness, ti paṣẹ ki wọn ko gbogbo awon eeyan to wa nibi to lewu ju kuro.
Bakan naa ni awọn alaṣẹ rọ awọn to n gbe nitosi omi lati wa aaye si ibo miran to ni aabo.
Ki ni Hurricane Melissa?

Oríṣun àwòrán, Reuters
Eyi jẹ iji akojọpọ iji, omi ati ara ti yoo maa san lakọlakọ nigba mi-in.
Awọn onimọ nipa iṣẹlẹ Hurricane yii gbagbọ pe bawọn ba n fun ijamba naa lorukọ bi eyi, awọn eeyan yoo le maa ranti rẹ, yoo si le maa ye wọn iru eyi to jẹ gan-an.
Orukọ ti wọn n fun Hurricane kọọkan da lori bi wọn ṣe n to wọn latigba to ti n ṣẹlẹ.
Ẹka US National Hurricane Centre lo bẹrẹ eto yii lati ọdun 1950.
Ṣugbọn latilẹ, ajọ agbaye, World Meteorological Organisation (WMO) lo maa n ṣeto orukọ ti wọn n sọ iṣẹlẹ Hurricane kọọkan.
Tẹlẹ, orukọ obinrin ni wọn maa n fi sọ Hurricane, titi di 1979 ti wọn wa fi orukọ ọkunrin naa kun un.
Bi iji ba bẹrẹ si i ja lọdun akọkọ, wọn yoo fun un lorukọ to bẹrẹ pẹlu A, bẹẹ ni yoo si maa tò lọ.
Melissa yii ni ẹlẹẹkẹtala to waye ni saa Atlantic lọdun yii, ti yoo pari loṣu Kọkanla.
Awọn Hurricane to ti ṣẹlẹ ri ni:Arlene, Bret, Cindy, Don, Emily, Franklin, Gert, Harvey, Irma, Jose, Katia, Lee, Maria, Nate, Ophelia, Philippe, Rina, Sean, Tammy, Vince, Whitney
Kí ni àwọn olùgbé agbègbè tí Hurricane ti ń wáyé lè ṣe?
Awọn alaṣẹ kilọ pe Hurricane Melissa yii yoo mu ina ọba lọ, yoo ba awọn nnkan amayedẹrun jẹ.
Wọn ni eyi yoo ri bẹẹ nitori Melissa yoo mu ojo to pọ wa, omi odo yoo si ga ni iwọn 13ft (4m) si ilẹẹlẹ.
Wọn ni ki awọn olugbe ibẹ sa asala, ki wọn wa aabo si ibo miran, ki wọn di yẹpẹ sinu apo ki wọn si fi kari inu ile ti wọn n gbe, ki wọn si ko awon ohun ti wọn ba nilo si arọwọto.
Hurricane Melissa yii ni ireti tun wa pe yoo ni iru ipa yii kan naa ni Haiti laaarin ọsẹ to n bọ, titi de olu ilu, Port au Prince, Dominican Republic ati Ila-Oorun Cuba.















