Ẹ̀sùn tí Kanu ń jẹ́jọ́ lé lórí kò ye, mo rọ̀ ọ́ láti kan sáwọn àgbà agbẹjọ́rò fún àlàyé kó tó pẹ́ jù - Adájọ́

Bile n jo, bi ole n ja, ẹni ebi n pa ko ni i yee wi.
Ohun ti olori ẹgbẹ to n pe fun idasilẹ Biafra (IPOB), iyẹn Nnamdi Kanu, n wi niyẹn bayii pẹlu bo ṣe ni ki ile ẹjọ yọnda oun tabi ki wọn gba oniduuro oun lati kuro ni ahamọ.
Nibi igbẹjọ Kanu to waye lanaa ọjọ Aje ni olori IPOB naa ti ni oun ko lẹjọ kankan lati jẹ lori ẹsun igbesunmọmi tijọba fi kan oun.
Nnamdi Kanu sọ pe jibiti ni ẹsun naa, o ni irọ pata ni gbogbo ohun ti wọn ka silẹ labẹ awọn ẹwọn ti wọn fi kan-an.
Olori IPOB naa fi kun un pe ,ara oun ko ti i ya, ki kootu wo iyẹn mọ oun lara.
Ẹ o ranti pe Kanu ti ni oun yoo gba ẹjọ ara oun ro, to si ni ki awọn agbẹjọro rẹ maa lọ.
Niwaju Adajọ James Omotosho, Kanu sọ fun kootu lanaa ode yii pe ki wọn fi oun silẹ, bo si jẹ wọn yoo fi aaye beeli silẹ foun ni.
"Ko si ofin kan pato lorilẹede yii ti ile ẹjọ le fi fidi ẹsun ti wọn fi kan mi mulẹ.
"Ti iru rẹ ba wa, ki Oluwa mi ka a jade fun mi.
Fun idi eyi, ko yẹ ki n maa wi awijare kankan fun ẹsun ti ko si labẹ ofin Naijiria kankan."
Nnamdi Kanu lo sọ bẹẹ.
O ni oun ti yẹ iwe ẹsun oun wo, oun si ri i pe ko si ẹsun kan to tako oun nibẹ.
Adájọ́ ṣàlàyé kíkún fún Kanu
Bi Nnamdi Kanu ṣe fẹ maa tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ, Adajọ James Omotosho, da a duro, o ni o yẹ ki oun fi oye ye e lori ilana igbẹjọ ni kootu.
Adajọ Omotosho ṣalaye pe ninu ẹjọ iwa ọdaran, ti olupẹjọ ba ti ṣiwe ẹjọ, ti wọn si ti sọ tiwọn, nnkan mẹta lo ku fun olujẹjọ lati ṣe.
Akọkọ ni lati kọwe pe ko si ẹjọ lati jẹ, bi wọn ko ba gba eyi wọle, ohun to kan ni lati bẹrẹ alaye ati awijare rẹ.
O ni nnkan kẹta ni pe bi olupẹjọ ba ni oun ko lẹjọ lati jẹ, o tumọ si pe, ohun ti olupẹjọ ba sọ lo fẹ gbe ara le niyẹn.
Ṣugbọn lẹyin alaye adajọ yii, Kanu tun yari pe ko si ẹsun kan to tako oun.
"Wọn n ti mi mọle lọna aitọ lori ẹsun ti ile ẹjọ to ga ju ti sọ pe ko yẹ ko ri bẹẹ.
Mo n bẹ Oluwa mi ko tu mi silẹ lonii tabi ki wọn fun mi ni beeli, nitori ara mi o ya."
Kanu lo sọ bẹẹ lẹyin alaye Adajọ Omotosho.
Ṣugbọn Adajọ Omotosho rọ ọ lati ṣọra lori ipinnu rẹ to gunle.
O wa parọwa si Kanu lati kan si awọn lọya to ni iriri nipa ẹsun iwa ọdaran, ki wọn le gba a nimọran gidi lori ohun to yẹ ko ṣe.
"Mo n gba olujẹjọ nimọran nitori mo mọ pe ojuṣe mi ni lati ṣe bẹẹ nigba ti ko ti ni agbejọro kankan mọ.
Mo si mọ pe Ọlọrun maa beere lọwọ mi ti mi o ba ṣalaye fun un. "
Adajọ Omorosho lo sọ bẹẹ.
Agbẹnusọ ijọba, Adegboyega Awomolo, sọ fun kootu pe ọjọ mẹfa ni olujẹjọ ni lati bẹrẹ, ko si pari ẹjọ rẹ, o si ti lo mẹta ninu rẹ.
O ni ninu ọjọ naa lo yẹ ki adajọ sun igbẹjọ rẹ si.
Ni pari, adajọ ni oun fun olujẹjọ ni ọjọ meje lati kan si awọn agba lọya to loye lori, lati ṣalaye ohun ti ẹsun iwa ọdaran jẹ fun un.
O sun igbẹjọ si ọjọ kẹrin, ikarun ati ikẹfa oṣu Kọkanla odun 2025, boya olujẹjọ yoo tẹle ẹsun to wa nilẹ, tabi yoo bẹrẹ awijare rẹ.














