Ìbẹ̀rẹ̀ ìyà tuntun rèé- Àwọn èèyàn Cameroon sọ èrò ọkàn wọn lórí àṣeyọrí Biya

Aarẹ Paul Biya

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aarẹ Paul Biya
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Bi wọn ṣe ti kede pe Aarẹ Paul Biya naa lo tun wọle ibo aarẹ ti wọn di lọsẹ meji sẹyin, awọn eeyan Cameroon ti n ṣalaye ero ọkan wọn.

Awọn eeyan ti wọn n gbe ni olu ilu Cameroon ti i ṣe Yaoundé, ni wọn n sọ ohun to ba wọn ju lori aṣeyọri Biya.

"A ṣẹṣẹ bẹrẹ iya tuntun mi-in ni bayii"

" Ọrọ aje wa n dojuru, ajẹbanu tan kalẹ, gbogbo nnkan lo n dori kodo."

Ọkan ninu wọn, Amungwa Nicodemus, lo sọ bẹẹ fun BBC.

Olugbe Yaoundé miran, Abolo Denis, rọ awọn eeyan Cameroon lati gba esi idibo naa wọle.

O ni alaafia ilu lo ṣe pataki ju.

Ṣaa, awọn awoye oṣelu ti n fi oju inu wo ijawe olubori rẹ naa, wọn ni ko daju pe yoo ba a kalẹ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Aṣeyọri Biya n mi lẹsẹ, pẹlu bi ọpọ araalu ṣe gba pe oun kọ lo wọle ibo naa."

Adari eto fun ẹgbẹ kan, International Crisis Group, Murithi Mutiga, lo sọ bẹẹ ninu atẹjade kan.

"A n pe Biya lati tete gbe igbimọ olupẹtu kan dide kia lati yanju ọrọ yii ko too di ariwo."

Mutiga lo ṣe afikun bẹẹ.

Bakan naa ni Francois Conradie, Onimọ nipa oṣelu ati ọrọ aje ni Oxford Economics, sọ fun ẹka iroyin Reuters pe :

"Ko le jọ wa loju bi wahala ba ṣẹlẹ lẹyin ọrọ yii pẹlu bi awọn eeyan Cameroon pupọ ṣe n kọ abajade esi idibo naa.

A wa ko si ri ijọba Biya yii bii eyi ti yoo pẹ rara."

Aráàlù tú jáde, fẹ̀hónù hàn

Latari ai gba esi idibo naa wọle, awọn araalu pada tu jade si agbegbe Douala to jẹ gbagede okoowo ni Cameroon, wọn n binu si esi idibo yii, wọn si n ju amọ lu patako to n kede Biya.

Bo tilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa gbiyanju lati koju wọn, awọn olufẹhonuhan naa ko gba rara.

Koda, ojo to n rọ ko da wọn duro, wọn dana si oju ọna, wọn si n kọrin pe awọn ko ni i gba.

Awon olufehonuhan naa

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Awon olufehonuhan naa

Àwọn agbébọn ń yìnbọn sí àwọn èèyàn -Alatako Biya, Tchiroma Bakary

Aworan awọn agbebọn lori ile ti Tchrioma fi soju opo Facebook rẹ

Oríṣun àwòrán, ISSA TCHIROMA BAKARY/FACEBOOK

Àkọlé àwòrán, Aworan awọn agbebọn lori ile ti Tchrioma fi soju opo Facebook rẹ

Alatako Paul Biya, Issa Tchiroma Bakary, ti kede loju opo Facebook rẹ pe awọn agbebọn kan n yinbọn nitosi ile oun.

Tchiroma Bakary sọ pe awọn agbebọn to da awọn boju naa jẹ marun-un.

O ni ile to wa niwaju ile oun ni wọn si duro si tibọn-tibọn ni Guusu ilu Garoua.

Tchiroma fi kun un pe wọn n yinbọn naa ni idojukọ ibi ti wọ fẹ .

Ṣaaju lati fi to yin leti pe awọn eeyan kan ti ku iku ojiji pẹlu ibọn to ba wọn, niwaju ile alatako Biya ti wọn jọ dupo, Issa Tchiroma Bakary.

Kókó ìtàn ayé Paul Biya, ààrẹ Cameroon tó wọlé ní 1982, ẹni ọdún 92, wọlé fún sáà kẹjọ, yóò parí ní 2032

Aarẹ Paul Biya

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aarẹ Paul Biya

Aarẹ orilẹede Cameroon ni Paul Biya, ẹni ọdun mejilelaadọrun-un (92) ni.

Ọdun mẹtalelogoji ni baba naa ti lo nipo aarẹ orilẹede Cameroon, nitori odun 1982 lo ti de ori aleefa naa.

Ni bayii, Paul Biya ni wọn tun kede gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori ninu ibo ti wọn di laipẹ.

Paul Biya yoo lo saa kẹjọ rẹ nipo, yoo si ti pe ẹni ọgọrun-un ọdun (100) nigba ti saa naa yoo ba fi ti ẹnu bọ ep oni 2032.

Ọdun 2008 ni awọn aṣofin ilẹ naa ṣe atunṣe ofin to fun Biya laye lati tun dupo aarẹ wọle fun saa keje

Ọjọ kẹtala, oṣu Keji ọdún 1933 ni wọn bi Paul Biya ni Guusu Cameroon

Aarẹ Biya ni aarẹ keji ti Cameroon ni.

Ọjọ kẹfa, oṣu Kọkanla ọdun 1982 lo di aarẹ fun igba akọkọ, iyẹn lẹyin ti aarẹ to jẹ ṣaaju rẹ, Ahmadou Ahidjo, kọwe fipo silẹ lọjọ kẹrin oṣu Kọkanla.

Ọdun 2008 ni awọn aṣofin ilẹ naa ṣe atunṣe kan to da ariyanjiyan silẹ, eyi to fun Biya laye lati tun dupo aarẹ, o si ṣe bẹẹ wọle fun saa keje.

O si tun wọle saa miran fun ọdun meje ni 2011 to ṣe di 2018.

Aroye pọ lori iwọle sipo rẹ ọhun nigba naa.

Ẹgbẹ oṣelu Biya ti a mọ si Cameroonian People's Democratic Movement (RDPC), lo maa n jawe olubori ninu awọn ibo ilẹ naa lati ọdun 1992.

Ọdun 1983 ni Biya fi ẹsun kan Ahidjo pe oun lo wa lẹyin iditẹgbajọba to lodi si oun

Ki Biya to di aarẹ, aarẹ to jẹ ṣaaju rẹ, Ahmadou Ahidjo, lo n ba ṣiṣẹ, ọdun 1975 lo si di Olootu ijọba.

Ọdun 1983 ni Biya fi ẹsun kan Ahidjo, o ni aarẹ iṣaaju naa lo wa lẹyin iditẹgbajọba kan to lodi si oun.

Bẹẹ lo si ṣe ti Ahmadou Ahidjo sa kuro lorilẹede naa.

Ni bayii ti Paul Biya tun ti ṣetan lati tukọ Cameroon bo ṣe dagba to, iṣẹ iyanu tuntun ti yoo ṣe fun won lawọn eeyan ibẹ n reti.

Iṣẹ ati oṣi, ebi ati airiṣẹṣe pẹlu ọwọngogo ọja ni awọn eeyan ilu naa n ke irora rẹ fun ọdun pipẹ ti Biya ti n ba a bọ, boya asiko yii ni yoo sanjọ fun wọn lai o le sọ.

Paul Biya, ààrẹ Cameroun wọlé ìbò ààrẹ fún sáà kẹjọ

Aarẹ Paul Biya n dibo

Aarẹ orilẹede Cameroon, Paul Biya tun ti bori ibo aarẹ orilẹede naa.

Ọjọ Kejila osu Kẹwa ọdun 2025 ni eto idibo aarẹ naa waye.

Igba kẹjọ ree ti aarẹ Paul Biya yoo wọle bii aarẹ fun ilẹ Cameroon.

Ninu esi ibo aarẹ ti alaga igbimọ to n ri si amusẹ ofin lorilẹede naa, Clément Atangana, ka nilu Yaounde, ni Paul Biya ti jawe olubori.

Ọdun 1982 ni Paul Biya kọkọ de ipo aarẹ ilẹ Cameroon, pẹlu bo se wọle ibo aarẹ fun saa kẹjọ yii, o di ọdun 2032 ko to kuro nipo.

Nigba to n kede esi ibo naa, Atangana ni ilana eto idibo naa lọ nirọwọ rọsẹ.

Ọrọ to sọ yii lo dabi eyi to ti n fesi pada fun alatako gboogi, Issa Tchiroma Bakary ati awọn alatilẹyin rẹ.

O wa n bu ẹnu atẹ lu awọn eeyan to ti kede esi ibo saaju ajọ naa, to si ni ọna kan soso ti wọn le gba ni lati lo ilana ofin pe ẹjọ kotẹmilọrun.

O kere tan, iwe ẹsun mẹea nipa magomago ibo ni ajọ ọhun ti kọ lati gba.

Esi ibo to n wa lati ẹkun mẹwa to wa nilẹ Cameroon ni ajọ ọhun kede.

Awọn oludije sipo aarẹ to n lewaju ree ati esi ibo ti wọn gba.

Ẹkun Adamawa - Issa Chiroma Bakary ni 56% esi ibo

Ẹkun Centre - Paul Biya ni esi ibo 70.14%

Ẹkun East - Biya ni esi ibo 73.88%

Ẹkun Far North - Biya ni 45.93%

Ẹkun Littoral - Tchiroma Bakary ni 64.5%

Ẹkun North region - Issa Tchiroma Bakary gba esi ibo to pọ ju pẹlu 43.51%

Ẹkun North-West - 52.5% awọn eeyan agbegbe ibi yii ni ko jade wa dibo - ọpọ ibo naa lo jẹ ti Paul Biya: 86.31%

Ẹkun West region - Paul Biya takes 46.21% to Tchiroma's 38.6%

Ẹkun South region - agbegbe ilu Paul Biya ree nibi to ti gba ibo to pọ julọ pẹlu ibo 90.86%

Ẹkun South-West - ida 53% awọn oludibo ni ko dibo ni ẹkun ti wọn ti n sọ oyinbo lorilẹede naa, ti esi ibo to pọ julọ nibẹ si jẹ ti Biya: 68.7%