Ilé alájà mẹ́ta tún dàwó l'Eko, èèyàn kan kú

Oríṣun àwòrán, LASEMA
Lẹyin ile alaja meji to wo lọjọ Aje ọsẹ yii ni Yaba, ipinlẹ Eko, ile alaja mẹta mi-in tun ti wo lulẹ ni Apapa Ajegunle.
Gẹgẹ bi ajọ LASEMA to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko ṣe ṣalaye, oni, ọgbọnjọ, oṣu Kẹwaa ọdun 2025 ni ijamba naa waye.
Ojule kejidinlọgbọn, Opopona Baale Alayabiagba ni ile to wo naa si wa bi wọn ṣe sọ.
Ọga agba ajọ LASEMA, Olufemi Damilola Oke -Osanyintolu, ṣalaye pe ẹnikan ti padanu ẹmi rẹ ninu ijamba naa, awọn eeyan kan si wa labẹ ile to wo naa .
O ni ọkunrin mẹjọ ni awọn ti ri gbe jade nibẹ laaye.
Báwo ló ṣe ṣẹlẹ̀ gan-an?

Oríṣun àwòrán, LASEMA
Ohun ti ajọ LASEMA fi lede ni pe awọn ara adugbo sọ pe awọn kan ni wọn n wo ile naa lọwọ ara wọn pẹlu ilana ti ki i ṣe lilo ẹrọ igbalode.
Nibi ti wọn ti n wo o lulẹ ni ile ọhun ti yẹ gẹrẹ to si dawo, to fa ijamba to mu ẹmi eeyan kan lọ.
Ẹsẹkẹsẹ ti awọn ajọ alaabo naa debẹ ni wọn ti ko awọn to farapa lọ si ileewosan ijọba to wa ni Ajeromi.
Wọn sare fi itọju pajawiri fun awọn kan pẹlu.
Gẹgẹ bi Osanyintolu ṣe wi, wọn ṣi n doola awọn eeyan mi-in lọwọ nibudo ijamba naa, bẹẹ ni iṣẹ ṣi n lọ lati gbe awọn to ba ṣi wa labẹ ile naa jade.
Awọn ikọ alaabo mi-in ti wọn dide si iṣẹlẹ naa ni
:Ileeṣẹ panapana ipinlẹ Eko, LNSC, LASAMBUS,LASBCA,NEMA ati awọn ọlọpaa
Ọkọ̀ tó kó epo bẹntiró 33,000 lítà dànù l'Eko, sìlíndà gáàsì gbaná, ọ̀pọ̀ dúkìá ṣòfò

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iṣẹlẹ meji ọtọtọ lo kọlu ilu Eko ninu eyi ti ẹnikan ti farapa ti ọpọ dukia olowo iyebiye si sọnu.
Iṣẹlẹ akọkọ ni ọkọ agbepo bẹntiro to danu, iṣẹlẹ keji ni silinda gaasi to bu gbamu.
Oju ọna marosẹ Apapa si Oshodi ni ọkọ agbepo to ko lita epo ti iye rẹ to ẹgbẹrun mẹtalelọgbọn ti danu, nigba ti gaasi to bu gbamu waye lagbegbe Orisunmibare, ni Orile-Iganmu.

Oríṣun àwòrán, LASEMA
Bi iṣẹlẹ gaasi to bu gbamu ṣe waye
Nnkan bii aago meji kọla iṣẹju mẹtala ọsan ni isẹlẹ gaasi naa waye ninu ọja Orisunmibare, ni Orile-Iganmu ni ṣọọbu kan ti ọpo silinda gaasi pọ si.
Gẹgẹ bii ohun ti adari ileeṣẹ panapana ipinẹ Eko, arabinrin Margaret Adeseye sọ ninu atẹjade kan, o ni iṣẹlẹ naa ko ba ṣakoba fun awọn ṣọọbu to sunmọ ibi ti ibugbamu ọhun ti waye amọ awọn kapa rẹ.
O ni "Ọpẹlọpẹ awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana Sari-Iganmu ati Ilupeju, ina naa ko ba ran lọ si awọn ṣọọbu to yi agbegbe naa ka.
"A ti pari iṣẹ wa nile itaja naa, ko si ẹnikẹni to ku nibi iṣẹlẹ mejeji, ayafi ẹnikan ti ina jo ọwọ rẹ ni ṣọọbu gaasi."
Adeseye ni ileeṣẹ panapana wa ni sẹpẹ lati dena irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ niluu Eko.

Oríṣun àwòrán, LASEMA
Ìṣẹ̀lẹ̀ ọkọ̀ agbepo to danu:
Ninu iṣẹlẹ miran niluu Eko yii naa ni ọkọ agbepo to ko epo bẹntiro ti iye rẹ to ẹgbẹrun mẹtalelọgbọn lita ti danu loju ọna marosẹ Apapa-Oshodi, lẹba ọja ti wọn ti n ọkọ ayọkẹlẹ ni Berger.
A gbọ pe Apapa ni ọkọ agbepo naa ti n bọ ko to fori sọ ọkọ ayọkẹlẹ Mercedes-Benz to ni nọmba idanimọ LSR-606HX kan ati awọn ọkọ meje mii ti wọn wa lẹba ọna fun tita.
Nigba ti Adeseye n sọrọ nipa rẹ, o ni ileeṣẹ panapana ni ko jẹ ki iṣẹlẹ naa pọ ju bo ṣe waye lọ.
O ni "A ti n gbọn epo naa pada sinu ọkọ agbepo mii, iṣẹ si ti n lọ lọwọ lati ko awọn ọkọ to bajẹ kuro nibẹ ki iṣẹ wa le pari."
Àlàyé rèé lórí bí ilé alájà méjì ṣe dàwó l'Eko lásìkò táwọn èèyàn inú rẹ̀ ń sùn, tí ẹ̀mí sì ṣòfò, ọ̀pọ̀ farapa

Oríṣun àwòrán, Others
Ni owurọ ọjọ Aje ni ariwo gbalẹ pe ile alaja kan ti dawo lulẹ ni ilu Eko.
Ojule 54, Opopona Cole, Oyingbo ni ile to da wo naa wa.
Lasiko ti a n kọ iroyin yii, ko ti i si ẹni to le fi onka iye eeyan to ti di oloogbe ninu iṣẹlẹ ile to dawo laaarọ ọjọ Aje oni, nipinlẹ Eko, mulẹ.
Atẹjade ti Margaret Adeseye, Adari ileeṣẹ panapana ipinlẹ Eko fi sita laaarọ ọjọ Aje naa, fidi ile wiwo naa mulẹ.
Adeseye sọ pe ẹsẹkẹsẹ ni ikọ panapana lati Sari-Iganmu ti lọ sibẹ, lẹyin ti awọn gba ipe ẹ gba wa ni nnkan bii aago mejila kọja ogun iṣẹju lọjọ Aje naa.
Ajọ panapana sọ pe ile naa ti n fi apẹẹrẹ han tẹlẹ pe o le wo nigbakugba.
Nigba ti yoo si pari iṣẹ lọjọ Aje, awọn eeyan to n gbe nibẹ ṣi wa ninu rẹ ti wọn sun.
Eyi lo fa a ti ọpọ eeyan fi ha sinu rẹ, ti ẹmi to ba a lọ ko si ti i ṣe e sọ bo ṣe jẹ ile nla.
"Ijọba ti ṣe ami silẹ naa tẹlẹ, lati kilọ ewu to rọ mọ ọn ko to wo le awọn olugbe ibẹ lori."
Bẹẹ ni atẹjade ajọ panapana Eko wi.
''Wọ́n ti ri èèyàn mẹ́ẹ̀ẹ́dógún gbé jáde''
Iroyin sọ pe eeyan mẹẹẹdogun ti wọn jẹ ọkunrin meje, obinrin mẹrin ati awọn ọmọde mẹrin ni wọn ti gbe jade labẹ ile naa.
Awọn eeyan naa ti farapa lọna ọtọọtọ, wọn si ti gbe wọn lọ sileewosan ijọba apapọ to wa ni Ebute-Meta, ati ti Odan, lerekuṣu Eko.
Iṣẹ ṣi n tẹsiwaju lori ati ko awọn to ha sabẹ ile naa jade.
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ilé wíwó tó ti wáyé ṣáájú nílùú Eko
Iṣẹlẹ ile didawo maa n waye ni Naijiria, ṣugbọn o fẹrẹ jẹ pe ilu Eko lo ni akọsilẹ iṣẹlẹ naa ju.
Ọpọ igba ni awọn ile to wo naa si maa n jẹ alaja meji tabi ju bẹẹ lọ. Ọpọ ẹmi lo si maa n ba a rin pẹlu.
Kikọle pẹlu awọn eroja ti ko kun to, kikọ ju iye ti aja ti ajọ to n ri si ile kikọ fi ọwọ si, ai si abojuto ati bẹẹ bẹẹ lọ, wa lara ohun to n fa ile didawo naa.
Wọnyi ni diẹ ninu awọn iṣẹlẹ ile to ti dawo nipinlẹ Eko ṣaaju
Ọjọ kin-in-ni, oṣù Kọkanla ọdun 2021
Ile alaja mọkanlelogun kan ti wọn n kọ lọwọ loju ọna Gerrard, Ikoyi, dawo lojiji.
Ọkunrin olowo nla kan, Femi Osibona, lo n kọ ile naa.
Iroyin sọ pe aja mẹrindinlogun ni ajọ to n ri si ile kikọ nipinlẹ Eko yọnda rẹ fun un lati kọ, ṣugbọn Oloogbe Osibona ṣe afikun àjà naa si mọkanlelogun.
Lọjọ ti ile ọhun wo, ko din ni eeyan mejilelogoji (42) to ba a lọ.
Lara wọn ni ọmọbinrin agunbanirọ kan to n sinru ilu, Femi Osibona paapaa si pada di ẹni ti wọn ri oku rẹ labẹ ile naa.
Ọjọ Kejila, oṣu Kẹrin ọdun 2023
Ile alaja meje kan daw oni Banana Island. Adugbo awọn olowo niluu Eko.
Eeyan meje ni a gbọ pe o fara kaasa ijamba naa.
Loṣu Kẹsan-an ọdun 2025 yii, ile alaja mẹrin kan naa dawo ni Yaba, ọpọ eeyan lo ku sabẹ ile ti wọn n kọ lọwọ naa.
Iwadii kan fidi ẹ mulẹ nibẹrẹ ọdun 2025 yii, pe ilu Eko lo gba ida marundinlọgọta (55% ) ninu ibi ti ile ti n wo ju ni Naijiria lati 1974.
Laaarin oṣu Kẹwaa ọdun 1974 si oṣu Kin-in-ni 2025, o kere tan, iṣẹlẹ ile didawo to le ni ẹgbẹta (640) lo ti waye kaaakiri Naijiria, idaji ninu rẹ lo si ṣẹlẹ l'Eko bi akọsilẹ naa ṣe wi.














