Kí ló rọ́ mọ́ ète ìdìtẹ̀ gbàjọba ní Nàíjíríà tó di ariwo, báwo ló ṣe kan Mínísítà tẹ́lẹ̀, táwọn afurasí ológun fi ya bo ilé rẹ̀, ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́?

Iroyin to n tẹ wa lọwọ sọ pe awọn oluwadii nileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria ti n fi ọrọ wa ọkan lara awọn adari ileeṣẹ ijọba apapọ kan, ni iha ila oorun lẹnu wo, lori ohun to mọ nipa igbiyanju awọn ologun kan, lati gba ijọba mọ Aarẹ Bola Tinubu lọwọ.
A gbọ pe wọn mu afurasi naa lori ẹsun pe o fi obitibiti owo ranṣẹ si minisita fun ọrọ epo bẹntiro tẹlẹ, Timipre Sylva, eyii to jẹ ọkan lara awọn ti wọn ni o n ṣagbatẹru iditẹgbajọ ọhun.
Iroyin ni igbagbọ wa pe owo naa ni wọn pinnu lati fi ṣagbateru igbiyanju lati fipa gba ijọba lọwọ Tinubu.
Timipre Sylva, to tun jẹ eekan ẹgbẹ APC, ko si ni Naijiria lasiko ti wọn ya bo ile rẹ lori ẹsun iditẹgbajọba
Ileeṣẹ iroyin abẹle Punch jabọ pe eeyan meji ninu ileeṣẹ ọmọ ogun amọ ti wọn ko fi orukọ wọn lede lo fidi ọrọ naa mulẹ.
Wọn ni "Adari ileeṣẹ ijọba naa (ti wọn ko darukọ rẹ) fi obitibiti owo ranṣẹ si Sylva.
"Igbagbọ awọn oluwadii ni pe iditẹgbajọba ni wọn fẹ lo owo naa fun, wọn ti n fi ọrọ wa a lẹnu wo bayii lati sọ ohun ti owo naa wa fun."
A gbọ pe alẹ ọjọ Abamẹta lawọn agbofinro ya bo ile Sylva to wa niluu Abuja, ti wọn si fi kele ofin gbe aburo rẹ ọkunrin, Papa, ati awakọ rẹ.
Minisita tẹlẹri naa, to tun jẹ eekan inu ẹgbẹ oṣelu APC, ko si ni Naijiria lasiko ti wọn ya bo ile rẹ.
Amọ awọn oluwadii nileesẹ ologun ni erongba rẹ ni lati pada wale ti wọn ba ti gbajọba tan.
Sugbọn o ti kọ lati pada wale bayii lẹyin ti aba iditẹgbajọba ọhun lulẹ.
Lọjọ kẹrin, oṣu Kẹwaa ti a wa yii ni agbẹnusọ ileeṣẹ ologun Naijiria, Markus Kangye, sọ ninu atẹjade kan pe, awọn ti fi ṣikun ofin mu ọmọ ogun mẹrindinlogun lori aṣemaṣe lẹnu iṣẹ.
Amọ iroyin ni eredi mimu awọn ologun ọhun ko ṣẹyin iditẹgbajọba ti wọn n gbero rẹ.

Oríṣun àwòrán, Timipre Sylva
Mi o mọ nnkankan nipa iditẹgbajọba – Sylva
Ẹwẹ, Timipre Sylva funra rẹ, to ti fi akoko kan jẹ gomina ipinlẹ Bayelsa, ti sọ pe oun ko mọ nnkankan nipa iditẹgbajọba ti wọn n sọ.
Sylva ni irọ lasan ni iroyin naa, ko si ootọ kankan ninu rẹ, o si lọwọ oṣelu ninu.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Julius Bokoru fi lede, o ni Sylva ko ni nnkankan ṣe pẹlu iditẹgbajọba naa.
O fikun pe oloṣelu ni, o si n fẹ ilọsiwaju Naijiria gẹgẹ bii ọmọ Naijiria rere ni.
Bokoru sọ pe, "ẹsun iditẹgbajọba naa wa lara igbiyanju awọn alatako Sylva lati ba orukọ rẹ jẹ, ṣaaju eto idibo gbogbogbo ti yoo waye lọdun 2027."
Agbẹnusọ naa fidi rẹ mulẹ pe, lootọ ni awọn kan ya bo ile Sylva, ti igbagbọ si wa pe wọn jẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ ọmọ ogun lati Defense Headquarters, ti wọn si ba ọpọ dukia jẹ.
O pari ọrọ rẹ pe, wọn ko sọ fun Sylva tabi ẹnikẹni ninu ile rẹ eredi ti wọn fi ya bo ile ọhun.
Ki ni awọn iroyin to suyọ lori iditẹgbajọba ni Naijiria ti orukọ Silva fi jẹyọ?
Ni gbogbo ọjọ kinni, oṣu Kẹwaa ni ijọba Naijiria maa n ṣajọyọ ọjọ ominira nibi ti awọn ologun ti maa n yan fanda.
Amọ lọdun 2025 yii, ijọba apapọ wọgile ayẹyẹ iyanfanda naa bo tilẹ jẹ pe Aarẹ Bola Tinbu ba araalu sọrọ lọjọ ọhun.
Lẹyin igbesẹ lati wọgile ayẹyẹ iyanfanda yii ni iroyin gbode pe igbesẹ ọhun ko ṣeyin igbiyanju awọn ọmọ ogun kan lati fi ipa gba ijọba lọwọ Tinubu.
Iroyin naa ni ileeṣẹ ọmọ ogun ti jawe ẹ lọ gbele yin fun awọn ọmọ ogun kan ti ipo wọn wa nipo Captain si Brigadier General.
Iroyin naa ni wọn ti ko awọn ọmọ ogun naa lọ si ahamọ ajọ Defence Intelligence Agency lori erongba lati ja ijọba gba lọwọ Tinubu.
Ṣugbọn nigba ti ileeṣẹ ọmọ ogun yoo sọrọ, o ni ko si ohun to jọ igbiyanju lati ditẹgbajọba, ati pe aṣemaṣe kan lawọn ọmọ ogun ti wọn mu ṣe lẹnu iṣẹ, wọn yoo si koju ofin to de awọn ọmọ ogun.
Ẹwẹ, agbẹnusọ Aarẹ Tinubu, Sunday Dare naa sọ pe ko si ohun to jọ iditẹgbajọba.
Nigba to n sọrọ ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin TVC, Dare ni ijọba gba ohun ti ileeṣẹ ọmọ ogun sọ wọle pe ko si igbiyanju kankan lati ja ijọba gba lọwọ Aarẹ Tinubu, nitori naa ko si ọrọ nibẹ mọ.















