Àjọ elétò ìdìbò kéde Samia Suluhu Hassan gẹ́gẹ́ bíi ẹni tó jáwé olúborí nínú ètò ìdìbò Ààrẹ Tanzania

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
Aarẹ Samia Suluhu Hassan ti orilẹede Tanzania ni ajọ eleto idibo lorilẹede naa ti kede gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori ninu eto idibo aarẹ to waye lorilẹede Tanzania.
Hassan, ẹni to jẹ obinrin lo bori eto idibo naa pẹlu ida 97.66% pẹlu apapọ ibo 31,913,866 lati fi bori eto idibo naa.
Ẹgbẹ oṣelu ti Hassan n soju Chama Cha Mapinduzi ni o ti wa ni ipo agbara fun ọpọ ọdun bayii, ti igbagbọ si wa pe wọn yoo bori eto idibo naa.
Ọpọ awọn alatako Hassan ni wọn wa ni ẹwọn tabi ofin ko gba wọn laye lati dije, eyi lo fa ti awọn ẹgbẹ oṣelu yooku fi fẹsun kan ijọba Hassan pe ko faye gba ijọba awarawa lorilẹede Tanzania.
Awọn ẹgbẹ oṣelu ni ọpọ eeyan lo padanu ẹmi wọn lasiko ti iwọde bẹẹ silẹ lorilẹede Tanzania ṣugbọn ijọba ko ti sọ ohunkohun nipa eyi tabi fidi rẹ mulẹ.
Samia Suluhu Hassan di aarẹ obinrin akọkọ fun orilẹede Tanzania ni ọdun 2021 lẹyin iku aarẹ to wa lori jokoo lasiko naa John Magufuli.
Bí rògbòdiyàn ṣe ń le sí i lọ́pọ̀ agbègbé ní Tanzania, Hussein Ali Mwinyi jáwé olúborí nínú ìdìbò ààrẹ lágbègbè Zanzibar

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ajọ eleto idibo Zanzibar (ZEC) ti kede pe Ọmọwe Hussein Ali Mwinyi, lo jawe olubori gẹgẹ bii aarẹ ninu idibo to waye l'Ọjọruu, ni Erekusu Archipelago, Zanzibar lorilẹede Tanzania.
Ọmọwe Mwinyi lo dije labẹ ẹgbẹ oṣelu to n ṣejọba lọwọ ti i ṣe ẹgbẹ CCM.
Ẹgbẹ CCM yii ni akọsilẹ sọ pe wọn ko padanu ibo ri latigba ti orilẹede naa ti gba ominira.
Gẹgẹ bi a ṣe mọ, ẹkun Zanzibar yii da duro bii ilẹ olominira to ni ijọba tirẹ ni Tanzania ni, bi ibo si ṣe waye ni Tanzania l'Ọjọru ni awọn naa di tiwọn ni Zanzibar.
Ọjọ kẹta oṣu Kọkanla ọdun 2020 ni Huissein Ali Mwinyi kọkọ di aarẹ Zanzibar, lẹyin to jawe olubori nibi idibo to waye loṣu Kẹwaa ọdun naa.
Oun ni aarẹ kẹjọ nigba naa, ọwọ ẹni to si ti gba ipo ni Ali Mohamed Shein.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ààrẹ Samia Suluhu ń léwájú, rògbòdiyàn ń le sí i lọ́pọ̀ agbègbé ní Tanzania
Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, nnkan ko fararọ ni ọpọ agbegbe ni orilẹede Tanzania, latari Aarẹ Samia Suluhu to n lewaju ninu idibo aarẹ to waye l'Ọjọru.
Ṣaaju ni ẹgbẹrun awọn oluwọde ti ya bo awọn agbegbe kan, ti wọn dana si oju popo, ti wọn si n fa awọn iwe alẹsode to n polongo Aarẹ Samia ya.
Iroyin sọ pe ida 95% ni Samia fi n lewaju ninu esi idibo naa, eyi ti ko dun mọ ọpọ eeyan to n fẹhonu han ninu.
Koda, rogbodiyan ọhun ti de apa kan Kenyan, awọn ọlọpaa si sọ pe eeyan meji lo ti dagbere faye.
Awijare awọn olufẹhonu han naa ni pe ijọba Samia n da oju dẹmokresi bole, ko fẹ alatako, o si fẹẹ maa ṣejọba lọ pẹlu ipa.
L'Ọjọbọ ni rogbodiyan naa tun le si i, nigba ti awọn eleto idibo bẹrẹ si i ka esi idibo, ti Aarẹ Samia si n lewaju ni ẹkun Guusu- Iwọ-Oorun Mbea.
Bẹẹ naa lo si tun n lewaju ni awọn agbegbe mi-in pẹlu.
Iro ibọn n dun lakọlakọ ni Ariwa ilu Mwanza, bẹẹ ni rogbodiyan bẹ silẹ ni olu ilu; Dodoma ati igboro Dar es Salaam, nibi ti wọn ti di ọpọlọpọ ọna pa.
Ṣugbọn orilẹede Kenya ti kilọ fun awọn eeyan rẹ lati ma ṣe lọwọ si ifẹhonuhan ni ẹbu ibode ilu naa ti i
se Namanga,nibi ti karakata ti dẹnukọlẹ wayi.
Latari rogbodiyan yii, ijọba ti paṣẹ pe kawọn oṣiṣẹ ṣiṣẹ nile titi di ọjọ Ẹti, ki won ma ṣe wa si ibi iṣẹ rara.
Bakan naa ni wọn kede ofin konile-o-gbele lọwọ alẹ ni Dar es Salaam, bi BBC ṣe gbọ pe niṣe ni wọn n ru awọn to farapa lọ sile iwosan Muhimbili, biba.
Ìfẹ̀hónúhàn bẹ̀rẹ̀ níbi ìdìbò Tanzania, ọ̀pọ̀ èèyàn farapa

Bi ifẹhonuhan ṣe bẹ silẹ nibi idibo to n lọ lọwọ lorilẹede Tanzania, ni apa Dar es Salaam to jẹ igboro, ọpọ eeyan lo ti fi ara pa.
Eyi ni iroyin sọ pe o fa a ti awọn ọlọpaa fi bẹrẹ si i yin tajutaju si wọn lati tu wọn ka.
Bi idibo ọhun ṣe n lọ, aridaju wa pe Aarẹ Samia Suluhu to n dari naa ni yoo jawe olubori.Eyi ri bẹẹ pẹlu bi alatako rẹ ninu oṣelu ṣe wa ni ahamọ lori ẹsun iditẹmọ ijọba.
Ohun to si n bi awọn araalu naa ninu leyi.
Awọn olufẹhonuhan naa kora jọ si awọn opopona nla nla, wọn n pariwo pe awọn n fẹ atunto ilana idibo ati ẹtọ lati le ṣe oṣelu lọna to yẹ.
Wọn dana si oju ọna, wọn ba ọpọ bọọsi jẹ, wọn si ba awọn nnkan amayedẹrun tijọba ṣe si ibudo iwọkọ araalu jẹ.
"O ti su wa, a fẹ ajọ eleto idibo to da duro, ki gbogbo ọmọ Tanzania le yan olori ti wọn fẹ."

Bayii ni awọn olufẹhonuhan naa ṣalaye fun BBC, pe awọn ko fẹ ilana idibo oloju opo kan ṣoṣo yii mọ. Wọn ni aruwuju ni.
Kọmiṣanna ẹkun Dar es Salaam, Alfred Chalamila, kilọ pe ijọba yoo fi ọwọ lile mu awọn to n da alaafia ilu run naa.
Bakan naa ni ẹka Internet watchdog NetBlocks, royin pe oju opo ayelujara ko ṣiṣẹ mọ ni Tanzania nitori idibo yii.
Iroyin sọ pe awọn araalu ko jade pupọ lati dibo ọhun ni Dar es Salaam, nigba ti eto gbogbo bẹrẹ l'Ọjọru.
Ohun ti wọn lo fa a naa ni pe kaluku n bẹru aabo to ṣee ṣe ko ma si, ki ọrọ naa ma si di rogbodiyan mọ wọn lọwọ.
Eyi to ti pada ṣẹlẹ bayii.
Ṣé Samia Suluhu, ààrẹ obìnrin ní Tanzania yóò wọlé fún sáà kejì, bí ìbò gbogbogbò ṣe wáyé lónìí?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ètò ìdìbò sípò ààrẹ ti waye ní orílẹ̀ èdè Tanzania níbi tí èèyàn mílíọ̀nù 37.7 ti fi orúkọ sílẹ̀ láti dìbò, láti yan ẹni tí yóò máa darí orílẹ̀ èdè náà.
Àwọn ibùdó ìdìbò tó lé ní 99,000 ló wà ní ṣíṣí ní gbogbo ẹkùn olú ilẹ̀ Tanzania àti Zanzibar feto idibo naa.
Àwọn èèyàn Tanzania dìbò láti yan ààrẹ, àwọn aṣòfin àtàwọn alága ìjọba ìbílẹ̀.
Ètò ìdìbò náà ló wáyé bí ẹnu àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò kò ṣe kò lórí bóyá kí wọ́n kópa níbi ètò ìdìbò náà tàbí kí wọ́n má kópa.
Aago méje òwúrọ̀ ni àwọn ibùdó ìdìbò ti wà ní ṣíṣí, tí ètò ìdìbò sì wá sópin ní aago mẹ́rin ìrọ̀lẹ́.
Ààrẹ Suluhu tó jẹ́ obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò ṣe ààrẹ ní orílẹ̀ èdè náà, lẹ́yìn ìpapòdà ààrẹ John Magufuli lọ́dún 2021, ń wá sáà kejì
Bákan náà ni ètò ààbò gbópọn káàkiri gbogbo orílẹ̀ èdè náà báwọn aláṣẹ ṣe rọ àwọn èèyàn láti fara balẹ̀, kí wọ́n sì jẹ́ kí ètò ìdìbò náà lọ ní ìrọwọ́ rọsẹ̀.
Àwọn olùdíje mẹ́tàdínlógún ló ń du ipò ààrẹ Tanzania, èyí tí Ààrẹ Samia Suluhu Hassan, tí ẹgbẹ́ òṣèlú Chama Cha Mapinduzi (CCM) wà lára wọn.
Ààrẹ Suluhu tó jẹ́ obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò ṣe ààrẹ ní orílẹ̀ èdè náà, lẹ́yìn ìpapòdà ààrẹ John Magufuli lọ́dún 2021, ń wá sáà kejì.
Ètò ìdìbò gbogbogbò keje tí yóò wáyé ní Tanzania láti ìgbà tí orílẹ̀ èdè náà ti padà sí ètò ìṣèjọba àwaarawa lọ́dún 1992.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àjọ elétò ìdìbò INEC ni Tanzania ,fòfin de ẹgbẹ́ alátakò gbòógì Chadema, tí adarí ẹgbẹ́ náà Tundu Lisu sì ń kojú ẹ̀sùn ìdìtẹ̀ sí ìjọba
Àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò ní Tanzania ìyẹn Independent National Electoral Commission, INEC, sọ pé lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta ni èsì ìbò náà máa jáde.
Àwọn lámèyítọ́ ti fẹ̀sùn kan ìjọba tó wà lóde pé wọ́n ń dojú ètò ìṣejọba àwaarawa orílẹ̀ èdè náà délẹ̀ bí wọ́n ṣe fòfin de àwọn olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò, Tundu Lissu (Chadema) àti Luhaga Mpina (ACT-Wazalendo) láti má kópa níbi ètò ìdìbò náà.
Èyí tó jẹ́ kó ku àwọn ẹgbẹ́ kéréje mẹ́rìndínlógún láti kópa níbi ètò ìdìbò náà láti kojú ẹgbẹ́ CCM tó ti ń ṣe ìjọba ní Tanzania fún ọdún pípẹ́.
Àjọ elétò ìdìbò INEC fòfin de ẹgbẹ́ alátakò gbòógì Tanzania, Chadema, tí adarí ẹgbẹ́ náà Tundu Lisu sì ń kojú ẹ̀sùn ìdìtẹ̀ sí ìjọba.
Ó ń pè fún àtúntò ètò ìdìbò ní Tanzania, kí wọ́n tó nawọ́ gan nínú oṣù Kẹrin, tí ẹgbẹ́ òṣèlú náà sì ti ní àwọn alátìlẹyìn àwọn kankan kò gbọdọ̀ kópa níbi ètò ìdìbò náà.
Pẹ̀lú àìsí alátakò kan tó ṣe gbòógì, àwọn kan sọ pé níṣe ni ètò ìdìbò náà dàbí ìwúyè fún ààrẹ Samia Suluhu Hassan.















