Wo àwọn nǹkan mẹ́jọ tí kò tọ́ láti máa ṣe ní ẹ̀gbẹ́ gáàsì ìdáná

Obìnrin tó ń dáná ní ilé ìdáná pẹ̀lú gáàsì

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Aisha Babangida
    • Role, Broadcast Journalist
    • Reporting from, BBC News, Abuja
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ní ọ̀pọ̀ ilé lóde òní pàápàá ní àwọn ìlú lílo gáàsì ìdáná ti rọ́pò lílo èédú, igi àti kẹrosíìnì láti fi dáná nítorí gáàsì jẹ́ ọ̀kan tó ń mú ìgbé ayé rọrùn fáwọn èèyàn.

Àmọ́ lílo gáàsì gba ẹ̀sọ̀ nítorí gáàsì, tí èèyàn kò bá kíyèsí ara pẹ̀lú rẹ̀, ó le ṣokùnfà ìbúgbàmù ìjàmbá iná èyí ló le fa ṣíṣe òfò ẹ̀mí àti dúkìá.

Èyí ló mú kí BBC kàn sí igbákejì tẹ́lẹ̀ rí fún iléeṣẹ́ panápaná, Tijjani Muhammad Abba láti ṣe àlàyé àwọn ohun tó tọ́ láti ṣe àti àwọn ohun tí kò tọ̀nà nígbà tí èèyàn bá ń lo gáàsì lọ́wọ́.

Tijjani ṣàlàyé pé ọ̀pọ̀ èèyàn ní kìí kọbi ara sí àwọn ìlànà tó tọ́ nígbà tí wọ́n bá ń lo gáàsì wọn, tó sì jẹ́ pé lílo gáàsì kò gbà bẹ́ẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ, kò sí ààyè fún ṣíṣe àìní àkàsí ní ẹ̀gbẹ́ gáàsì nítorí ó léwu tó sì yára máa ń fa ìjàmbá iná.

Kí ni àwọn nǹkan tí kò tọ́ ní ẹ̀gbẹ́ gáàsì?

Agolo gáàsì ìdáná ní ilé ìdáná

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan ni kò yẹ kí èèyàn máa ṣe lẹ́gbẹ̀ẹ́ gáàsì gẹ́gẹ́ bí Tijjani ṣe sọ, tí ara wọn sì jẹ́:

  • Lílo fóònù nílé ìdáná

Ọ̀gá àgbà nídìí iṣẹ́ panápaná náà sọ pé èèyàn gbọdọ̀ dèna lílo fóònù tàbí títanná sí sìgá ní ẹ̀gbẹ́ gáàsì.

Ó ní iná kékeré látara iná sìgá tàbí wáyà kan le ṣokùnfà ìjàmbá iná tó lágbára.

  • Gbígbe ohun ìbúgbàmù sí ẹ̀gbẹ́ gáàsì
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Tijjani Muhammad Abba sọ pé èèyàn kò gbọdọ̀ máa gbé àwọn ohun tó lè fa ìbúgbàmù sí ẹ̀gbẹ́ ibi tí gáàsì bá wà.

Ó ní àwọn ohun bíi gasoline, àwọn kẹ́míkà tó lè tètè gba iná kò gbọdọ̀ máa wà ní ẹ̀gbẹ́ gáàsì.

  • Àwọn ọmọdé

Onímọ̀ nípa iná náà sọ pé kò yẹ kí àwọn ọmọdé máa súnmọ́ ilé ìdáná tàbí ṣeré lẹ́gbẹ̀ẹ́ ibi tí gáàsì bá wà.

"Àwọn ọmọdé kò mọ ìtumọ̀ ewu tó bẹ́ẹ̀, fún ìdí èyí, ṣíṣe eré ní ẹ̀gbẹ́ ibi tí gáàsì wà léwu púpọ̀.

  • Àì máa pa gáàsì nígbà tí èèyàn bá ń jáde

Ó ní kò yẹ kí èèyàn máa fi ilé ìdáná sílẹ̀ láì pa gáàsì lára agolo gáàsì.

Ó wòye pé ohun tó léwu le ṣẹlẹ̀ tí kò bá sí iná tó mọ́lẹ̀ tó ní ilé ìdáná tí nǹkan bá ṣẹlẹ̀.

  • Títi ilẹ̀kùn ilé ìdáná lásìkò tí èèyàn ń lo gáàsì lọ́wọ́

Tijjani ṣàlàyé pé ilẹ̀kùn ilé ìdáná gbọdọ̀ máa wà ní ṣíṣí lásìkò tí èèyàn bá ń lo gáàsì fi dáná lọ́wọ́.

Ó ní afẹ́fẹ́ tó ń wọlé àti èyí tó ń jáde tí èèyàn bá ń dáná lọ́wọ́ yóò dènà kíkójọ òórùn àti afẹ́fẹ́ gáàsì máa ń pèsè.

  • Ye fi agolo gáàsì sínu ilé ìdáná

Onímọ̀ nípa iná náà fi kun pé kò yẹ láti máa gbé agolo gáàsì sínú ilé ìdáná nítorí àti mú àdínkù bá ìjàmbá tó lè fà.

"Ó sàn kí èèyàn gbé agolo gáàsì sí ìta, kí èèyàn mọ odi yi ká láti mú àdínkù bá ewu rẹ̀."

  • Dènà títan iná mọ̀nàmọ́ná nígbà tí gáàsì bá ń rùn

Nígbà tí èèyàn bá ń gbọ́ òórùn gáàsì, kò tọ́ láti tan tàbí pa iná mọ̀nàmọ́ná.

Títan tàbí pípa iná mọ̀nàmọ́ná le ṣokùnfà ìjàmbá iná gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ.

  • Dènà fífi agolo gáàsì tó ń jò sílé

Tijjani ṣèkìlọ̀ gbígbé agolo gáàsì tó ń jò sílé nítorí ewu tó máa ń fà.

"Ní kété tí èèyàn bá ti mọ̀ pé agolo gáàsì òun ń jò ló ti gbọdọ̀ gbe lọ sí ibi tí wọ́n ti máa ba tun ṣe lójúnà àti dènà ìjàmbá iná.

Wo àwọn ọ̀nà láti dá ààbò bo ara rẹ

Agolo gáàsì tí ọwọ́ ń yí ibi ṣíṣí rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Tijjani ṣàlàyé àwọn nǹkan tí èèyàn gbọ́dọ̀ ṣe láti dá ààbò ara wọn nígbà tí wọ́n bá ń lo gáàsì ìdáná.

  • Lára àwọn nǹkan tó kà ni:
  • Ṣíṣe àyẹ̀wò agolo gáàsì lóòrèkóòrè
  • Ri dájú pé atẹ́gùn wà nílé ìdáná
  • Pa agolo gáàsì nígbà tí o bá dáná tán
  • Ṣé ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí lílo gáàsì fún àwọn ẹbí rẹ
  • Jẹ́ kí àyíká ilé ìdáná rẹ máa wà ní tónítóní ni gbogbo ìgbà
  • Dènà àwọn ọmọdé láti máa wọ ilé ìdáná lásìkò tí o bá ń lo gáàsì lọ́wọ́

Tijjani Muhammad Abba tẹmpẹlẹmọ pé èèyàn gbọdọ̀ mú ètò ààbò ní òkúnkúndùn lásìkò lílo gáàsì nítorí ó léwu ju epo bẹntiróòlù lọ.