Àlàyé lórí bíi ìbátan Ọba Faisal Saudi Arabia ṣe yìnbọn pa á nígbà tí wọ́n ń kí ara wọn

Ọba Faisal bin Abdulaziz Saudi Arabia n sọrọ nibi apero kan niluu London lọdun 1967

Oríṣun àwòrán, C Maher/Daily Express/Hulton Archive/Getty Images

Àkọlé àwòrán, Lọjọ kẹẹdọgbọn oṣu Kẹta ọdun 1975 ni wọn yinbọn pa Ọba Saudi tẹlẹ,Ọba Faisal niluu Riyadh ti i ṣe olu ilu orilẹede naa.
    • Author, Louise Hidalgo
    • Role, BBC World Service
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Lọjọ kẹẹdọgbọn oṣu Kẹta ọdun 1975 ni wọn yinbọn pa Ọba Saudi tẹlẹ,

Ọba Faisal niluu Riyadh ti i ṣe olu ilu orilẹede naa.

Koda, ibatan rẹ gan an lo yinbọn pa a, ọmọ rẹ obinrin, Dokita Mai Yamani sọ fun BBC pe ''n ko le gbagbe ọjọ naa laelae.

Mo si n rani iku baba mi titi di oni, ẹni to duro lẹgbẹ rẹ naa lo yinbọn pa a.''

Igba mẹta ọtọọtọ ni ibatan rẹ yinbọn fun un nigba ti o fẹ fẹnu ko ọmọkunrin naa lẹnu.

Wọn gbe Ọba Faisal to jẹ ọba kẹta Saudi digba digba lọ sile iwosan, amọ, eleeru ti sungi.

Ọgọọrọ eeyan nibi eto isinku Ọba Faisal lọdun 1975 niluu Ruyadh.

Oríṣun àwòrán, Claude Salhani/Sygma/Getty Images

Àkọlé àwòrán, Igba mẹta ọtọọtọ ni ibatan rẹ yinbọn fun un nigba ti o fẹ fẹnu ko ọmọkunrin naa lẹnu.

Mai Yamani n duro de baba rẹ ni nnkan bii mẹẹli meloo kan si aarin ilu.

''O ri ijokoo ni mo wa ninu ile baba mi nigba ti o wọle ti oju rẹ si koro.

Lẹyin igba diẹ to ti wọle tan ni o sọ nnkan to ṣẹlẹ fun ọmọbinrin rẹ.

''O yẹ ki igbimọ to n ri si ọrọ epo rọbi lati Kuwait ri Ọba Faisal ni nnkan bii ago mẹwaa owurọ.

Eyi lo jẹ ki baba mi gẹgẹ bi minisita ọrọ epo rọbi lọ sọdọ Ọba Saudi lati ṣalaye fun un.

Ọmọba Faisal Ibu Musaed darapọ mọ igbimọ to wa lati Kuwait, bayii ni Ọba Faisal bẹrẹ lati ki ibatan rẹ,

Lẹyin naa ni Faisal ibu Musaed yọ ibọn jade ti o si ṣina ibọn bolẹ fun Ọba Saudi nigba mẹta ọtọọtọ.

Yamani ba Ọba Faisal lọ ile iwosan nibi tawọn dokita ti sọ pe o ti ku.

Ọba alatunṣe

Lọdun 1964 ni Faisal jọba Saudi, ọpo si ṣapujuwe rẹ gẹgẹ bi ọrẹ ilẹ Gẹẹsi nilẹ Araabu nitori o fẹ sọ ọpọ nnkan di ti igbalode ni Saudi, amọ, ibeere ti akọroyin BBC David Dimbleby beere ni pe ṣe erongba rẹ ko ni yọ ọ loye.

Abdulaziz Al Saud to jẹ ọkan lara awọn ọmọkunrin rẹ to dagba ju fita fita lasiko ipolongo baba rẹ ki iṣọkan le wa lorilẹede naa.

Eyi gan an lo si jẹ ki wọn maa orilẹede naa ni Saudi Arabia ni nnkan bii ọgbọn ọdun sẹyin.

Faisal pada jẹ Olootu ijọba nigba ti ẹgbọn rẹ jẹ ọba lẹyin ti baba wọn ku.

Ọpọ lo ri Faisal gẹgẹ bi olori ti yoo mu ayipada rere pa Saudi nigba to jọba, pẹlu gbogbo nnkan to ti n ṣe tẹlẹ.

Amọ, gbogbo nnkan ti Faisal n ṣe ko tẹ awọn ẹgbẹ kan lọrun, fun apẹẹrẹ, awọn kan ṣe ikọlu si ileeṣẹ tẹlifisan akọkọ ti Faisal ṣi ni nnkan bii ọdun 1965.

Ọba Faisal tun ṣe ifilọlẹ eto ẹkọ fawọn ọmọbinrin, Dokita Yamani sọ pe Olori Iffat to jẹ iyawo keji Faisal lo bẹrẹ ile ẹkọ fawọn ọmọbinrin.

Minisita epo rọbi Saudi Arabia, Sheik Ahmed Zaki Yamani n sọrọ nibi apero kan lọdun 1978.

Oríṣun àwòrán, Bettmann Archive/Getty Images

Àkọlé àwòrán, Lati ọdun 1960 ni Yamani ti bẹrẹ sii ṣiṣẹ fun Faisal, Yamani ko wa lati idile ọba ni tootọ, amọ agbẹjọro to kawe daadaa ni.

Lati ọdun 1960 ni Yamani ti bẹrẹ sii ṣiṣẹ fun Faisal, Yamani ko wa lati idile ọba ni tootọ, amọ agbẹjọro to kawe daadaa ni.

Ọba ka awọn iwe apilẹkọ kan ti Yamani kọ, ''baba mi kọ oniruuru iwe apilẹkọ gẹgẹ bi amofin, eyi to fi n beere fun ijọba awarawa.

Nigba to ya ni Faisal beere pe ta ni ọkunrin yii gan an tori o n wa oludamọran lori ọrọ ofin.''

Faisal yoo pada fi ọkan ninu Ahmed Zaki tabi Sheikh Yamani jẹ minisita epo rọbi.

Bayii ni Faisal ati iṣọmọgbe rẹ ṣe agbekalẹ ofin ti yoo jẹ ki orilẹede Saudi Arabia di awokọsẹ nilẹ Araabu.

Ayipada ijọba

Saudi Arabia to jẹ orilẹede to lepo to pọju lọ lagbaaye lo epo rẹ bii ohun ija lọdun 1973 nigba ti ogun bẹ silẹ laarin Saudi atawọn orilẹede mii to wa ni ayika rẹ.

Adinku ba iye epo ti wọn n gbe lọ sawọn orilẹede to n ṣatilẹyin fun Israel, eyi si jẹ ki owo epo lọ soke lagbaaye.

Yamani sọ pe bi owo epo ṣe lọ soke yoo mu ayipada ba ibaṣepọ laarin awọn orilẹede to ti goke agba atawọn kekeke.

Sheik Yamani si wa nipo minisita epo rọbi Saudi Arabia fun mọkanla titi di ọdun 1986.