Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa bàlúù ọmogun ATR 42-500 tó já l'Ondo tó fi mọ́ ìgbà tí Naijiria rà á

Oríṣun àwòrán, Getty Images
NAF 931 ni nọmba idanimọ baluu ileeṣẹ ọmọogun ofurufu orilẹede Naijiria to ja nitosi ibudo awọn ọmọogun oju omi to wa niluu Igbọkọda nijọba ibilẹ Alaje nipinlẹ Ondo lọjọ Aje ọjọ karun un oṣu Kẹwaa yii.
Eeyan mejilelọgbọn lo wa ninu baalu ileeṣẹ ọmogun naa to ja sinu ira ni Igbokoda.
Baluu to ja yii jẹ ọkọ ofurufu ileeṣẹ ọmogun ofurufu orilẹede Naijiria eyi to ni nọmba ATR 42 ni iru rẹ.
Ileeṣẹ kan to jẹ ti orilẹede France ati Italy lo ṣe baluu ọmogun ofurufu ATR 42 to ja naa lọjọ Aje l'Ondo.
Wọn bẹrẹ sii ṣe irufẹ baluu ATR 42-500 yii lati ọdun 1995 si 2006, ọpọ orilẹede lo si n ra a lati maa lo.
Irufẹ baluu yii le gbe aadọta eeyan rinrin ajo, amọ, iwadii fi idi rẹ mulẹ pe lọdun 2010 ni orilẹede Naijiria ra baluu to ja yii.
Baluu yii jẹ ọkọ ofurufu ATR 42-500 MP tawọn ọmogun maa n lo lati maa ṣe amojuto ohun to n ṣẹlẹ kaakiri lori eto aabo ori omi.
Eyi ni wọn fi pe e ni ATR 42-500 tori ohun ni wọn maa n lo lati mojuto agbegbe ti omi ba wa.
Amọ, iwadii fi han pe oriṣiiriṣii nnkan lawọn ologun ti lo baluu naa fun.
Baluu yii ni wọn fi ko awọn akẹkọọbinrin ileeṣẹ ọmogun ofurufu loṣu Kẹrin ọdun 2025.
Ohun naa ni wọn maa fi gbe awọn akẹkọọ ile ẹkọ ọmogun kaakiri orilẹede Naijiria fun iwọle igbẹkọ tuntun loṣu Kẹsan an ọdun yii.
Ileeṣẹ ọmogun Naijiria ra baluu ATR 42-500 lati maa gbogun ti iwa ọdaran lori omi pẹlu ajọṣepọ ajọ NIMASA.
Wọn ṣe ifihan baluu yii ni olu ileeṣẹ ọmogun ofurufu to wa niluu Eko lọjọ kọkandinlogun oṣu Kẹjọ ọdun 2014.
Ajọ NIMASA ṣẹṣẹ ra oriṣiiriṣii satalaiti lati le maa fi gbogun ti awọn ọdaran ori omi pẹlu ajọṣepọ ileeṣẹ ọmogun ofurufu ati ọmogun ori omi Naijiria.
Awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi si n gbiyanju lati ṣawari awọn to wa ninu baluu ọhun.

Oríṣun àwòrán, Nigeria Air Force
Gbogbo àwọn èèyàn 32 tó wà nínú bàlúù iléeṣẹ́ ọmọogun Nàìjíríà tó já l'Ondo ló kú, Ààrẹ Tinubu ránṣẹ́ ìbánikẹ́dùn sí ẹbí wọn
Aarẹ orilẹede Naijiria, Bọla Ahmed Tinubu ti ranṣẹ ibanikẹdun si ẹbi awọn eeyan marundinlọgbọn ati oṣiṣẹ baluu naa meje to ku ninu ijamba ọkọ baluu to ja n agbegbe ilu Igbọkọda ni ipinlẹ Ondo lọjọ Aje.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ fun aarẹ,Bayọ Ọnanuga fi sita nirọlẹ Ọjọ Aje, Aarẹ Tinubu ni ọgagun agba ileeṣẹ ọmọogun ofurufu lorilẹede Naijiria, Sunday Kelvin Aneke ti fi ẹkunrẹrẹ iroyin ijamba naa to oun leti, oun si ti ni ki iwadi to rinlẹ o bẹrẹ nipa ohun to ṣokunfa ijamba naa 'lati le dena irufẹ rẹ lọjọ iwaju'.
"Akoko ibanujẹnla gba a niyi fun awọn ọmọogun wa ati fun gbogbo orilẹede yii lapapọ. Awọn ologun ofurufu wa fi ẹmi wọn lelẹ lojoojumọ lati daabo bo orilẹede Naijiria. A ko ni gbagbe ifẹmiaraẹni rubọ wọn."
Bakan naa lo gbadura fun awọn to ku naa ki Ọlọrun le tu awọn ẹbi wọn ninu.
Àkànṣe iṣẹ́ ológun ni bàlúú tó já pẹ̀lú èèyàn 32 l'Ondo ń gbéra láti Benin lọ ṣe l'Eko – Iléeṣẹ́ ọmọogun ofúrufú Nàìjíríà
Ileeṣẹ ọmọogun ofurufu lorilẹede Naijiria ni oun ti bẹrẹ eto wiwa ati didoola awọn eeyan to wa ninu baluu ologun to ja ni agbegbe Igbọkọda ni ipinlẹ Ondo, lowurọ ọjọ Aje.
Ninu atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ ọmọogun ofurufu, Ọgagun Ehimen Ejodame fi sita, o ni iṣẹ aṣayan kan ni baluu naa gbera nilu Benin lati lọ ṣe nilu Eko ti ajalu ijamba naa fi waye.
Ọgagun Ehimen Ejodamen tun ṣalaye siwaju sii ninu atẹjade naa pe igbesẹ wiwa awọn eeyan to wa ninu baluu naa ti bẹrẹ ni ifọwọsowọpọ pẹlu awọn ajọ ijọba gbogbo to yẹ.
Lowurọ ọjọ aje oni, ọjọ karun-un oṣu Kẹwaa ọdun 2026 ni iroyin jade pe ọkọ baluu kan ti ja lorilẹede Naijiria.
Ohun ti a mọ nipa iṣẹlẹ ijamba baluu naa ree.
Owurọ ọjọ Aje ni baluu naa gbera ni Ilu Benin to si n lọ si ilu Eko pẹlu eeyan mejilelọgbọn ninu rẹ. Marun ninu wọn jẹ awọn awakọ ati oṣiṣẹ baluu naa ti awọn marundinlọgbọn yoku jẹ ero to ko.
Nnkan bi agogo mẹsan kọja iṣẹju mẹtala ni atọna rẹ sọnu loju ofurufu ti ibudo atọna baluu ko si rii kan simọ.
Ko pẹ pupọ si asiko yii ni iroyin jade pe baluu naa ti ja lulẹ nitosi ibudo awọn ọmọogun ojuomi to wa ni ilu igbọkọda ni ipinlẹ Ondo
Alaye ti minisita fun irinna ofurufu, Festus Keyamo ṣe ni pe nọmba idanimọ baluu naa ni NGR 931 tabi NAF 931, Ẹya baluu ATR-42-500MP Surveyor ni baluu naa.
Iwadii ti a ṣe fihan pe irufẹ awọn baluu yii jẹ ẹlẹnjini meji ti wọn maa fi n ṣe amojuto ati idaabobo awọn etido atieti omi gbogbo,
Awọn ọmọogun oju omi ati araalu ṣi nwa awọn eeyan to wa ninu rẹ lẹyin ti wọn ṣawari ibi ti baluu naa ja si
Lọwọ ti a n ko iroyin yii jọ, ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ ni awọn iroyin nipa ijamba naa ṣi n jẹyọ lẹyọ ẹyọ ni ati pe iwadi nlọ lọwọ.



























