Ìdí rèé tí owó gáàsì ìdáná fi gbówó lórí

Ọkùnrin kan gbé agolo gáàsì ìdáná sórí, àwọn ọkọ̀ àti èrò wà ní ibi tó wà

Oríṣun àwòrán, Tolu Owoeye/Getty Images

    • Author, Andrew Gift
    • Role, BBC News Pidgin
    • Author, Adesola Ikulajolu
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Láti bíi ọjọ́ méjì báyìí ni àwọn èèyàn ti ń pariwo pé àwọn kò rí gáàsì ìdáná pàápàá ní ìpínlẹ̀ Eko àti láwọn agbègbè míì káàkiri Nàìjíríà.

Owó gáàsì náà ló ti gbẹ́nu sókè láti bíi N1,200 tí wọ́n ń ta kílógíráàmù kan tẹ́lẹ̀ di N2,500 báyìí ní àwọn agbègbè kan ní ìpínlẹ̀ Eko.

Àwọn ilé ìtajà kan ń ta kílógíráàmù kan gáàsì ní ẹgbàá náírà (N2,000) nígbà tí àwọn míì ń tà á jù bẹ́ẹ̀ lọ.

Ní àwọn agbègbè kan ní ìlú Abuja, owó gáàsì ti gbẹ́nu sókè di N1,800 kílógíráàmù kan láti N1,000 tó wà tẹ́lẹ̀. Àwọn kan ń tà á ní N1,700.

Ní àwọn agbègbè kan ní ìpínlẹ̀ Ogun, N2,200 ni wọ́n ń ta kílógíráàmù gáàsì kan.

Ní ọ̀pọ̀ agbègbè ní ìpínlẹ̀ Eko tí BBC News Pidgin ṣe àbẹ̀wò sí, ọ̀pọ̀ àwọn ibi tí wọ́n ti máa ń ta afẹ́fẹ́ ìdáná gáàsì ni wọn kò tajà, tí ọ̀pọ̀ àwọn míì tí wọ́n ní ọjà náà sì kọ̀ láti máa tà wọ́n.

Àwọn agolo tí wọ́n ń rọ afẹ́fẹ́ gáàsì ìdáná sí

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọ̀gbẹ́ni Chika Umodu tó ń ta gáàsì sọ fún BBC pé òun ní gáàsì àmọ́ iye tí òun ní kò lè tó iye àwọn oníbàárà tí wọ́n fẹ́ rà á.

Ó ní èyí ló mú kí òun máa ṣe ìgbéléwọ̀n iye tí òun ń tà fún ẹnìkọ̀ọ̀kan.

"Ẹni tó bá fẹ́ ra kílógíráàmù mẹ́wàá, a máa ta kílógíráàmù mẹ́rin kó le kárí àwọn èèyà tó kù nítorí mo ní àwọn oníbàárà tó pọ̀ tí mo fẹ́ tà fún," Umodu sọ.

Òntàjà gáàsì míì tí kò fẹ́ kí a dárúkọ òun sọ pé láti bíi ọjọ́ márùn-ún sẹ́yìn ni òun kò ti ní ọjà. Ó ní òun òun ṣẹ̀ṣẹ̀ gba ọjà, èyí ló sì fà á tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi kún ilé ìtajà òun.

Ó wòye pé ìyanṣẹ́lódì tí àwọn òṣìṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ epo àti gáàsì gùnlé ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ló ṣokùnfà bí gáàsì ṣe wọ́n gógó lásìkò yìí.

Bákan náà ni owó gáàsì tí wọ́n ń lò sí ọkọ̀ ìyẹn CNG ti gbówó di N380 lítà kan láti N230 tí wọ́n ń tà á tẹ́lẹ̀.

A kò lè sọ ohun tó ṣokùnfà ọ̀wọ́n gógó gáàsì àti bí kò ṣe sí lọ́jà yìí àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń sọ pé kò ṣẹ̀yìn ìyanṣẹ́lọdì ẹgbẹ́ Pengassan tó wáyé lọ́sẹ̀ tó kọjá.

Ọkùnrin kan tó wọ aṣọ pupa bẹ̀rẹ̀ síwájú afẹ́fẹ́ gáàsì ìdáná

Oríṣun àwòrán, Gift Andrew/BBC

'Àwọn èèyàn ló mọ̀ọ́mọ̀ mú àlékún bá owó gáàsì'

Ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ tó n rí sí èpò ní Nàìjíríà, NNPCL, Bayo Ojulari sọ pé ìyanṣẹ́lódì ẹgbẹ́ Pengassan tó wáyé fún ọjọ́ méjì ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ló fa ìyanṣẹ́lódì náà.

Ojulari sọ èyí nígbà tó ṣe àbẹ̀wò sí ààrẹ Nàìjíríà, Bola Tinubu láti ṣàlàyé bí nǹkan ṣe ń lọ lẹ́ka epo.

Ó sọ pé àlékún tó bá owó gáàsì kìí ṣe ohun tó wáyé láti ọwọ́ ìjọba bíkòṣe àtọwọ́dá.

Ó ní ìyanṣẹ́lódì tó wáyé náà kò jẹ́ kí wọ́n le gbé gáàsì fún ọjọ́ méjì sí ọjọ́ mẹ́ta.

"Ìdí nìyí tí a fi ń rí ipa rẹ̀ báyìí, ó máa gba àkókó díẹ̀ láti ri pé gáàsì ìdáná dé gbogbo àwọn ibi tó yẹ."

Ó ní àwọn tó ní gáàsì lọ́wọ́ tẹ́lẹ̀ ni wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ gbé owó le nítorí kò sí bí wọ́n ṣe máa gbé àwọn míì lásìkò tí Pengassan ń yanṣẹ́lódì.

Ọ̀gá NNPCL náà ní òun gbèrò pé owó gáàsì máa padà sí iye tó wà tẹ́lẹ̀ kó tó di pé ìyanṣẹ́lódì náà wáyé.