Àwọn ẹ̀gbọ́n ṣekúpa àbúrò wọn àti olólùfẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ ẹlẹ́sìn ọ̀tọ̀

- Author, Abhishek Dey
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Fún ọdún pípẹ́ làwọn èèyàn ìlú Umri, ní àríwá ìpínlẹ̀ Uttar Pradesh, orílẹ̀ èdè India ti ń gbé ní àlááfíà kó tó di pé ìṣẹ̀lẹ̀ ikú tọkọtaya Kajal àti Arman sọ àwọn èèyàn ìlú náà sínú ìpayà wáyé.
Níṣe ni wọ́n bá òkú Kajal, ẹni ọdún makàndínlógún, tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Hindu àti Mohammad Arman, ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n, tó jẹ́ mùsùlùmí tí wọ́n sin sẹ́gbẹ̀ẹ́ odò kan lọ́jọ́ Kọkànlélógún, oṣù Kìíní, ọdún 2026.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn ẹ̀gbọ́n Kajal ló lù wọ́n títí tí ẹ̀mí fi bọ́ lọ́rùn wọn, tí wọ́n sì sọ pé àwọn afuarsí náà ti wà ná àhámọ́ àmọ́ àwọn afurasí náà kò ì tíì sọ ohunkóhun lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ìròyìn ikú àwọn tọkọtaya náà ti ń fa inú fu, àyà fu ní ìlú Umri, ìlú tó wà ní máìlì 113 sí Delhi, olú ìlú orílẹ̀ èdè India. Àwọn ìdílé -tó jẹ́ àpapọ̀ àwọn ẹlẹ́sìn Hindu àti mùsùlùmí - tó tó irinwó ló fi ìlú náà ṣe ibùjókòó.
Àwọn aráàlú sọ fún BBC pé àwọn ti ń gbé papọ̀ ní àlááfíà fún ìgbà pípẹ́ láì sí ìjà ẹ̀sìn kankan.
Igbákejì ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ náà Muniraj sọ fún BBC pé ìgbàgbọ́ wà pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà jẹ́ ìpànìyàn látọwọ́ àwọn ẹbí Kajal láti fìyà jẹ wọ́n nítorí pé ó lọ fẹ́ èèyàn tí kìí ṣe ẹlẹ́sìn rẹ̀.
Ní ọdún 2014 ni àjọ India's National Crime Records Bureau bẹ̀rẹ̀ àkọ́ọ́lẹ̀ irúfẹ́ ìpànìyàn báyìí níbi tí wọ́n ti rí àkọ́ọ́lẹ̀ méjìdínlógún, tó sì jẹ́ pé àkọ́ọ́lẹ̀ méjìdínlógójì ni wọ́n rí lọ́dún 2023.
Àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn sọ pé ó ṣeéṣe kí ìṣẹ̀lẹ̀ náà pọ̀ ju iye àkọ́ọ́lẹ̀ tó wà lọ.
Ará ìlú Umri kan, Mahipal Saini sọ fún BBC pé Kajal àti Arman ni àkọ́kọ́ àwọn ẹlẹ́sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ méjì tó máa fẹ́ra wọn ní ìlú náà.

Olùkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ aládàni kan ni Kajal ní Umri, tí Arman sì ṣẹ̀ṣẹ̀ padà sí ìlú náà ní nǹkan bíi oṣù márùn-ún sẹ́yìn lẹ́yìn tó lo ọdún mẹ́rin ní Saudi Arabia níbi tó ti ṣiṣẹ́ nílé oúnjẹ kan.
A kò mọ bí Kajal àti Arman ṣe pàdé tàbí iye ìgbà tí wọ́n ti fẹ́ra wọn gẹ́gẹ́ bí tọkọtaya àmọ́ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ pé àwọn méjéèjì súnmọ́ ara wọn dáadáa.
Wọ́n ní ilé Kajal ni wọ́n ti ṣekúpa wọn ní òru ọjọ́ Kejìdínlógún mọ́jú ọjọ́ Kọkàndínlógún, oṣù Kìíní nígbà tí àwọn ẹ̀gbọ́n Kajal rí Arman tó lọ ṣàbẹ̀wò síi.
Àwọn ẹ̀gbọ́n Kajal, Rajaram, Satish àti Rinku Saini ti wà ní àhámọ́ ọlọ́pàá tí bàbá wọn Ganpat Saini sọ fún BBC pé òun àti ìyàwó òun kò sí nílé nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé. Ó fi kun pé òun ṣọ̀fọ̀ ọmọ òun lọ́wọ́.
Ẹ̀gbọ́n Arman, Farman Ali sọ pé Arman jáde nílé lálẹ́ ọjọ́ náà lẹ́yìn tó jẹun alẹ́ tán pé òun fẹ́ lọ wá ògùn fáwọn òbí òun tàwọn kò sì ri kó dé di ọjọ́ kejì.
Ali sọ pé nígbà tí fóònù rẹ̀ kò lọ mọ́ ní ọjọ́ kejì ni àwọn bẹ̀rẹ̀ sí ní bẹ̀rù èyí tó mú àwọn lọ fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn ọlọ́pàá létí èyí tó mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní wá wọn.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá fẹ̀sùn kàn pé àwọn ẹ̀gbọ́ Kajal fẹ́ da ọ̀rọ̀ rú mọ́ àwọn ọlọ́pàá lójú bí wọ́ ṣe lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá pé àwọn ń wá àbúrò àwọn pẹ̀lú ẹ̀sùn pé Arman ló jí í gbé.
Wọ́n ní ibi tí àwọn ti ń ṣèwádìí làwọn ti ṣàwárí ibi tí wọ́n sin òkú Kajal àti Arman sí.
Bàbá Kajal kò fèsì bóyá ó mọ̀ pé Kajal àti Arman ń fẹ́ ara wọn àmọ́ àwọn ẹbí Arman ní àwọn kò mọ̀.
"Kò sọ ohunkọhun fún wa. Nígbà tí a bẹ̀rẹ̀ sí ní wa lawọn ọ̀rẹ́ kan sọ fún wa pé òun àti Kajal ti ń fẹ́ra wọn fún bíi oṣù méjì sẹ́yìn."
Àwọn aráàlú ní àwọn ìgbìmọ̀ olórí ìlú ni wọ́n máa ń lọ fẹjọ́ sùn tí èdè àìyedè bá wáyé.
Mahipal Saini sọ pé òun gbàgbọ́ pé tí àwọn ẹbí Kajal bá ṣe bẹ́ẹ̀ ni irú ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé náà kò ní ṣẹlẹ̀.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn ọlọ́pàá ti wà ní ìlú náà láti ri dájú pé wàhálà ẹ̀sìn kò wáyé, àwọn aráàlú náà sọ pé nǹkan ti ń padà sípò díẹ̀díẹ̀.
Aráàlú míì Arif Ali sọ pé òun kò gbàgbọ́ pé irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ le wáyé ní ìlú Umri, tó sì jẹ́ pé, tó sì jẹ́ pé àwọn aráàlú sì ti ń ní èrò pé kò sí ààbò tó bẹ́ẹ̀ fáwọn.
Ìdá mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn-ún ìgbéyàwó tó máa ń wáyé ní India ló máa ń jẹ́ èyí tí wọ́n tọkọtaya fúnra wọn tí ẹni tó bá sì lòdì sí irúfẹ́ ìgbéyàwó bẹ́ẹ̀ máa ń nílò láti wá ààbò lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́pàá.
Òfin India fààyè gba kí èèyàn yan olólùfẹ́ tó bá wù ú tí ìjọba sì pàṣẹ káwọn ilé ẹjọ́ kọ ilé sí ẹkùn kọ̀ọ̀kan láti fi máa dá ààbò bo àwọn tọkọtaya tó bá fẹ́ra láti ẹ̀sìn ọ́tọ̀ọ̀tọ̀.
Síbẹ̀ ìwà ipá sáwọn tó bá ní irúfẹ́ ìgbéyàwó ń wáyé ní gbogbo ìgbà.
Ìwádìí fi hàn pé ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ní India ni kò faramọ́ ìgbéyàwó láti ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
Òṣèré Nakul Singh Sawhney tó kọ́kọ́ ṣe àkọ́ọ́lẹ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ́dún 2012 sọ pé àkọ́ọ́lẹ̀ tó wà lórí ìpànìyàn bẹ́ẹ̀ kò tó bó ṣe ń ṣẹlẹ̀.
Bákan náà ni ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn, Kavita Srivastava sọ pé àìsí ìgbéléwọ̀n tó péye lórí ìwà yìí kò jẹ́ kí ìjọba gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ lórí rẹ̀.
Ó ní báwọn obìnrin ṣe ń jà fún ẹ̀tọ́ láti yan ẹni tó wù wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọkọ síbẹ̀ wọ́n ṣì ń kojú ìwà ipá láwujọ.
























