Ilé ẹjọ́ ti sún ìgbẹ́jọ́ lórí awakọ̀ Anthony Joshua síwájú lẹ́ẹ̀kan sí

Ile ẹjọ Magistrate to n jokoo niluu Sagamu nipinlẹ Ogun ti sun igbejọ Kayode Adeniyi siwaju, Ọjọ kẹtala oṣu kẹta ọdun 2026
Agbẹjọro olujẹjọ ba BBC Yoruba sọrọ nipa idi ti wọn fi sun igbẹjọ naa siwaju.
O ni o da bi pe ijọba ipinlẹ Ogun nifẹ si igbẹjọ, ti wọn si fẹ gba akoso igbẹjọ naa lọwọ ọlọpaa
Ẹkunrẹrẹ ohun to waye ni ile ẹjọ n bọ...
Awakọ̀ Anthony Joshua, tó wa ọkọ̀ tó ṣe ìjàmbá tó pa ọ̀rẹ́ akànṣẹ́gbayì náà, padà sí ilé ejọ̀ lónìí

Loni ni Ọgbẹni Kayode Adeniyi, awakọ to wa ọkọ to ṣeku pa awọn ọrẹ gbajugbaja abẹṣẹkubiojo ọmọ Naijiria ni, Anthony Joshua, yoo foju ba ile-ẹjọ.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ogunjọ, osu Kinni, ọdun yii ni Adeniyi foju ba ile-ẹjọ Majisireeti akọkọ to wa niluu Ṣagamu, ipinlẹ Ogun fun igba kẹta lori ẹsun ere asapajude.
Adeniyi lo wa ọkọ ayọkẹlẹ Lexus SUV to gbe Anthony Joshua ati awọn ọrẹ rẹ meji to padanu ẹmi wọn lọdun to kọja, Ayodele Kelvin Olu ati Gami Sina.
Onidajọ Olufunmilayo Somefun to gbọ ẹjọ naa lo paṣẹ pe ki wọn pada wa loni, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun 2026.
Agbefọba Richard Nigiwe to fẹsun kan Adeniyi niwaju ile-ẹjọ lo rọ adajọ pe oun yoo nilo lati ṣe ẹda awọn iwe ẹsun naa sọwọ.
Nigiwe sọ pe lara awọn igbesẹ ti awọn n gbe lori ẹjọ naa ni ti awọn ti awọn fẹẹ gba lati ọdọ ajọ DPP tii ṣe Director of Public Prosecution.
Kókó ẹ̀sùn mẹ́rin tí wọ́n fi kan awakọ̀ Anthony Joshua nílé ẹjọ́
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti ṣalaye koko ẹsun mẹrin ti wọn fi kan awakọ Lexus SUV ti Anthony Joshua atawọn alabaṣiṣẹpọ rẹ meji wa ninu rẹ, eyi to ni ijamba lọna marosẹ ilu Eko si Ibadan lọjọ Aje ọsẹ yii.
Lonii ọjọ keji oṣu Kinni ọdun 2026 ni awakọ naa, Adeniyi Kayode, foju ba ile ẹjọ majisireeti to wa niluu Sagamu nipinlẹ Ogun.
Ẹsun akọkọ ti wọn fi kan awakọ naa ni pe o wa ọkọ lọna to lewu eyi to ṣokunfa iku awọn eeyan.
Eleyii ni igbimọ olupẹjọ sọ pe o tako abala 5(1) ofin ọna marosẹ ijọba apapọ ti ọdun 2004.
Ẹsun keji ti wọn fi kan Ọgbẹni Kayode ni ẹsun aibikita ati wiwa ọkọ ni iwakuwa eyi to lodi sofin ọna marosẹ ijọba apapọ ti ọdun 2004.
Wiwa ọkọ lai na-an ni nnkan to le ṣẹlẹ lẹsun kẹta ti wọn fi kan Ọgbẹni Kayode, ati pe wọn lo tun ṣakoba fawọn to wa ninu ọkọ naa ti wọn fi farapa.
Labẹ ẹsun yii kan naa ni wọn tun ti sọ pe awakọ naa ba dukia jẹ eyi to lodi si abala 7(1) ofin ọna marosẹ ijọba apapọ ti ọdun 2004.
Ẹsun kẹrin ti wọn fi kan awakọ Anthony Joshua ni pe o n wa ọkọ lai ni iwe ẹri iwakọ to yanranti lọwọ, eyi to lodi abala 10(1) ofin ọna marosẹ ijọba apapọ.
Lẹyin o rẹyin, ile ẹjọ fun awakọ naa ni beeli pẹlu miliọnu marun un naira (N5m) ati oniduro meji.
Ile ẹjọ ni Ọgbẹni Kayode yoo wa ni ahamọ titi ti yoo fi pese nnkan ti ile ẹjọ ni ko san fun beeli rẹ.
Ogunjọ oṣu Kinni yii ni igbẹjọ yoo tun waye.
























