BBC ṣèwádìí àwọn ọkùnrin tó ń ya fídíò àwọn obìnrin ní bòńkẹ́lẹ́ lálẹ́ láti fi pawó lórí ayélujára

- Author, Shona Elliott
- Author, Abi Smitton
- Role, BBC News Investigations
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7
Ìwádìí BBC ti fi hàn pé àwọn ọkùnrin kan máa ń ya fídíò àwọn obìnrin ní bòńkẹ́lẹ́, tí wọ́n sì ń fi àwọn fídíò náà pa owó lórí ayélujára.
Àwọn fídíò náà tí wọ́n máa ń fún ní orúkọ oríṣiríṣi ni wọ́n máa ń gbé sáwọn orí ìkànnì bíi YouTube, Facebook, TikTok àti Instagram. Àwọn obìnrin tí wọ́n sábà máa ń ṣe nǹkan báyìí fún ni àwọn obìnrin tí wọ́n bá wọ kaba kékeré tàbí tí síkẹ̀tì wọn kò bá gùn.
Wọ́n sábà máa ń ya àwòrán àwọn obìnrin náà láti ẹ̀yìn tàbí láti abẹ́ èyí tó fi máa ṣàfihàn àwọn ẹ̀yà ara wọn.
A ṣe àwárí àwọn obìnrin bíi àádọ́ta tí wọ́n ti ya fídíò wọn, tí a sì ri pé ọ̀pọ̀ wọn ni kò mọ̀ pé wọ́n ya àwọn.
Obìnrin kan, ẹni ọdún mọ́kànlélógún, tí wọ́n ya fídíò rẹ̀ láti abẹ́ láti ṣàfihàn síkẹ̀tì rẹ̀, ní bí òun ṣe ń rí àwọn fídíò òun lórí ayélujára ti ń ní ipa lórí òun nítorí kìí fẹ́ jáde nílé òun mọ́.
BBC tún ṣàwárí àwọn ìkànnì márùndúnláàádọ́rin (65) míì tí wọ́n ń gbé irú àwọn fídíò báyìí jáde tó sì jẹ́ pé iye ìgbà tí wọ́n ti wo àwọn fídíò náà ti lé ní bílíọ̀nù mẹ́ta láàárín ọdún mẹ́ta báyìí.
Lára àwọn ìlú tí wọ́n ti ń ya àwọn fídíò yìí jùlọ ni London, Oslo, Miami àti Bangkok – àmọ́ èyí tó gbajúmọ̀ jùlọ ni Manchester.
Ikọ̀ ìròyìn BBC ya àwọn ọkùnrin kan bí wọ́n ṣe ń ya fídíò àwọn obìnrin ní bòńkẹ́lẹ́ ní ìjáde alẹ́, tí a sì rí àwọn èèyàn tí a tọpinpin wọn sí ojú òpó méjìlá.
Awakọ̀ èrò kan àtàwọn ọkùnrin méjì tí wọ́n ṣe ìrìnàjò láti Sweden lọ sí UK láti ya fídíò àwọn obìnrin wà lára wọn. Àwọn ọkùnrin méjì míì tí ojú òpó wọn ní Monaco àti Norway ni wọ́n fi ṣe ibùgbé wà lára wọn.
Ìwádìí yìí tún jẹ́ àfihàn báwọn ọkùnrin ṣe máa ń ya àwòrán àwọn obìnrin tí ìta gbangba láìsí ìmọ̀sí wọn.
Ní oṣù tó kọjá ni ìwádìí BBC kan ṣàwárí báwọn ọkùnrin kan tí wọ́n máa ń sọ pé àwọn ń fún àwọn obìnrin nímọ̀ràn ń lo ìgò ojú láti fi gba ohun wọn sílẹ̀, ti wọ́n sì máa gbé sórí ayélujára. Òṣìṣẹ́ Home Secretary, Shabana Mahmood sọ pé ìjọba kò ní fi ààyè gba àwọn ìmọ̀ ẹ̀rọ tí wọ́n ń lò láti fi hu ìwà ipá sáwọn obìnrin àti ọmọdé.
Kìí ṣe ìwà ọ̀daràn láti ya fídíò ní ìta gbangba ṣùgbọ́n agbẹjọ́rò kan tó ń rí sí lílo àwòrán àwọn èèyàn sọ pé àwọn èyí ṣe é kà sára àwọn ìwà kò tọ́.
Ọ̀pọ̀ àwọn fídíò yìí ló ṣì wà lórí YouTube ṣùgbọ́n wọ́n yọ ojú òpó àwọn èèyàn méjì kan kúrò lẹ́yìn tí a ṣe àfihàn ìwádìí yìí fún wọn.
TikTok náà ti yọ ojú òpó mẹ́rin. Àwọn fídíò tó wà lórí ìkànnì Facebook àti Instagram ṣì wà níbẹ̀.
Ní ìparí oṣù Kẹwàá ọdún tó kọjá ni Grace, kìí ṣe orúkọ rẹ̀ gangan, wà níwájú ilé ijó kan ní Manchester, tó ń fi fóònù rẹ̀ ya fọ́tò lásìkò ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó pé ọdún mọ́kànlélógún. Àbúrò rẹ̀, Sophie, a ti pàrọ̀ orúkọ tiẹ̀ náà, ẹni ọdún méjìdínlógún, tó ń lọ sílé ijó fún ìgbà àkọ́kọ́ wà pẹ̀lú wọn.
Grace ní àwọn kàn jáde ní ti wọn, àwọn ò mọ̀ pé èèyàn kan ń ya àwọn ní bòńkẹ́lẹ́.
Nígbà tí a kàn síi ni ó tó mọ̀ pé wọ́n gbé fídíò rẹ̀ sórí YouTube. Fídíò náà ṣàfihàn bí síkẹ̀tì rẹ̀ ṣe tik á sókè táwọn èèyàn tó sì ti wò ó ti lé ní mílíọ̀nù mẹ́ta.
Ó ní òun ri dájú pé aṣọ tí òun wọ̀ lọ́jọ́ náà bo ara òun ṣùgbọ́n bí wọ́n ṣe ya fídíò náà ya òun lẹ́nu, ó túmọ̀ sí pé onítọ̀hún súnmọ́ òun dáadáa.
"Mi ò tíì máa jáde nítorí ẹ̀rù ń bà mí, kò yẹ kí nǹkan báyìí wáyé rárá."

Grace àti Sophie wà lára ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin tí a rí nínú àwọn fídíò náà lásìkò ìwádìí wa.
Ìbéèrè tó gba ẹnu Sophie àti Grace ni pé ta ni àwọn tó ń yà wọ́n àti pé kí nídìí tí wọ́n fi ṣe é?
Púpọ̀ lára àwọn fídíò tí wọ́n yà ní Manchester ṣàfihàn báwọn obìnrin ṣe ń rìn láàárín ilé ijó àti jíjókòó, tí fídíò sì ń ṣàfihàn bí wọ́n ṣe ń ṣe aṣọ wọn dáadáa. Onírúurú àwọn àríwísí làwọn èèyàn ńk sábẹ́ àwọn fídíò náà.
Lára ohun táwọn èèyàn ń sọ ni pé "wo bí wọ́n ṣe múra, nítorí rẹ̀ ni wọ́n ṣe máa ń ṣe ìkọlù sí wọn", "orí títì ni ilé àwọn wọ̀nyí" àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn obìnrin tó wà nínú àwọn fídíò ṣe é tètè dámọ̀, ó ṣòro láti tètè ṣàwárí àwọn ọkùnrin tó ni àwọn ojú òpó náà níorí wọn kìí lo orúkọ wọn gangan lórí ayélujára.

Ojú òpó tó gbé fídíò Grace àti Sophie jáde ni a ṣàwárí pé ọkùnrin kan, Florjan Reka, ẹni ọdún márùndínlógójì, tó ń gbé ní Sweden ló ni ojú òpó náà.
Ó ní ọ̀pọ̀ àwọn ojú òpó YouTube bẹ́ẹ̀ tí àwọn èèyàn tó máa ń wo fídíò níbẹ̀ lé ní igba mílíọ̀nù, táwọn tí sì ń tẹ̀lé ìkànnì náà dín díẹ̀ ní ẹgbẹ̀rún irinwó. Bákan náà ni àwọn tó ń tẹ̀le lójú òpó Facebook lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀ta.
Láti mọ bó ṣe ń ṣiṣẹ́, a tẹ̀le lásìkò Halloween ní Manchester. Ní ọjọ́ àkọ́kọ́, a rí Reka tó ń rì pẹ̀lú ọkùnrin kan tí a padà mọ̀ pé àbúrò rẹ̀ ni, Roland.
Wọ́n ṣebí ẹni pé àwọn ń wo fóònù wọn ṣùgbọ́n ẹ̀rọ ayàwòrán míì wà lọ́wọ́ wọn tí wọ́n fi ń ya fídíò àwọn obìnrin tó bá kọjá níbi tí wọ́n wà.
Kò pẹ́ lẹ́yìn ìgbà náà làwọn fídíò kan ń jáde lórí ayélujára èyí tí a mọ̀ pé Florjan Reka ló yà wọ́n.
Lára àwọn fídíò náà ṣàfihàn bí obìnrin kan ṣe ń fa síkẹ̀tì rẹ̀ sílẹ̀. Àwọn fídíò ṣàfihàn ìdí àwọn obìnrin bí wọ́n ṣe ń rìn kọjá. Òmíràn ṣàfihàn àyà obìnrin kan tó ń tún aṣọ rẹ̀ ṣe níbi ọyàn.
Nínú gbogbo fídíò náà, ó dàbí pé àwọn obìnrin náà kò mọ̀ pé wọ́n ń ya àwọn.
A gbìyànjú láti kàn sí Florjan Reka lẹ́yìn Halloween ṣùgbọ́n kò dáhùn. A wa lọ sí Sweden láti ba sọ̀rọ̀ àmọ́ ó kọ̀ láti dáhùn gbogbo ìbéèrè tí a bi í.

Lásìkò Halloween náà ní Manchester, a tún rí àwọn ọkùnrin mẹ́ta míì tí wọ́n ń ya àwọn obìnrin. Ó jọ pé gbogbo wọn mọ ara wọn pẹ̀lú àwọn Reka.
Ọ̀kan lára wọn ní Dean Hill, ẹni ọdún mẹ́rìndínlógójì tó ń ṣiṣẹ́ awakọ̀. Ó ń ya àwọn obìnrin pẹ̀lú ẹ̀rọ ayàwòrán kékeré tó gbé sí àyà, tó sì tún kọjú sẹ́yìn láti ya ẹ̀yìn wọn.
Hill sọ fún BBC pé òun kò se ohun tó burú tàbí lòdì sí òfin nítorí òun kò ya àwọn ibi tó pamọ́ lára àwọn obìnrin àti pé ibi tí gbogbo èèyàn ti lè rí ẹ̀rọ ayàwòrán ló wà.
"Mi ò kí ń ya síkẹ̀tì tàbí ìhòhò ẹnikẹ́ni, àwọn fídíò mi kìí ṣàfihàn ìhòhò", ó sọ nínú àtẹ̀jíṣẹ́ tó fi ránṣẹ́ sí BBC.
Ó ní òun mọ̀ pé àwọn kan ń ya fídíò lọ́nà àìtọ́ ṣùgbọ́n òun kìí ṣe bẹ́ẹ̀.
Ọkùnrin míì tí a rí tí a kàn sí láti ojú òpó ayélujára rẹ̀ náà sọ pé òun kò ṣe ohun tó lòdì sí òfin. Ó ní àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lálẹ́ ni òun ń yà àti báwọn èèyàn ṣe ń rìn kọjá.
Bákan náà ló ní òun ti yọ àwọn fídíò kan kúrò lórí ìkànnì òun.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá kò ì tíì fẹ̀sùn kàn ẹnìkankan fún ìwà ọ̀daràn nínú gbogbo àwọn tí a ṣe ìwádìí wọn yìí.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Manchester, lọ́dún 2024, fòfin gbé ọkùnrin kan fẹ̀sùn pé ó ya àwòrán àwọn obìnrin ní alẹ́.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní irúfẹ́ àkọ́kọ́ rẹ̀ ni èyí ní orílẹ̀ èdè náà. Àmọ́ nínú oṣ[yìí ni wọ́n sọ pé àwọn máa ṣe ìdádúró lórí ẹ̀sùn náà nítorí ibi tí ọwọ́jà òfin dé dúró.
Yíya àwòrán àwọn obìnrin láì mọ̀ lálẹ́ ṣeéṣe kó máa ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó fáwọn èèyàn kan gẹ́gẹ́ bí Ọ̀jọ̀gbọ́n Annabelle Gawer, adarí ẹ̀ka Centre of Digital Economy ní ilé ẹ̀kọ́ gaga University of Surrey ṣe sọ.
Ó ní fídíò tó bá ní wíwó tó lé ní mílíọ̀nù kan le pa £5,000.
Lábẹ́ òfin UK, yíya àwòrán ìta gbangba kìí ṣe ohun tó lòdì sí òfin àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin tí a bá sọ̀rọ̀ ni wọ́n ń bínú pé wọ́n ń fi àwọn pa owó láì mọ̀.
YouTube ti yọ ojú òpó méjì tó jẹ́ ti Florjan Reka lórí ìkànnì wọn lẹ́yìn tí a fi ohun tí a ṣe àwárí hàn wọ́n.
Lójú òpó X, Florjan rọ YouTube láti ṣe àtúngbéyẹ̀wò ìgbésẹ̀ náà nítorí fídíò àwọn obìnrin tó kàn ń rìn kọjá ni òun ń gbé sórí ìkànnì náà.
Ọ̀pọ̀ àwọn fídíò tí a fi ránṣẹ́ sí YouTube ló ṣì wà lójú òpó náà. Iléeṣẹ́ náà àwọn máa tẹ̀lé ìlànà tí àwọn gbé kalẹ̀ àti pé fídíò tó lé ní mílíọ̀nù kan ni wọ́n parẹ́ lórí ìkànnì náà lọ́dún 2025 nìkan.
Àwọn ojú òpó míì ṣì wà lórí ayélujára. Ọkùnrin kan ti pàrọ̀ orúkọ ojú òpó rẹ̀, tí ẹlòmíràn sì ti yọ gbogbo àwọn fídíò rẹ̀ kúrò lórí ìkànnì náà.
TikTok ti yọ ojú òpó mẹ́rin lára àwọn èyí tí a fi ránṣẹ́ sí wọn.
Àwọn èyí tí a fi ránṣẹ́ sì Meta tó ni ojú òpó Facebook àti Instagram. Wọ́n ní àwọn ti yọ àwọn fídíò tó lòdì sí òfin àwọn.
Fídíò Grace àti Sophie wà lára àwọn èyí tí wọ́n ti yọ.
Àmọ́ àwọn obìnrin náà ní ọkàn àwọn kò balẹ̀ nítorí ó ṣeéṣe kó tún gbé fídíò síta lọ́jọ́ iwájú.
























