Ìjọba gbọ́dọ̀ ní àkójọpọ̀ orúkọ gbogbo aráàlú lórí ẹ̀rọ kọ̀mpútà tó bá fẹ́ rẹ́yìn ìgbésùnmọ̀mí - Christopher Musa

Christopher Musa ninu aṣọ iṣẹ ologun rẹ

Oríṣun àwòrán, NA

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Minisita tuntun fun eto abo ni Naijiria, ọgagun Christopher Musa ti sọ pe ko tọ fun ijọba Naijiria ko maa san owo itusilẹ fun awọn ajinigbe tabi ko maa ba awọn agbesunmọmi dunadura.

O tun sọ pe gbogbo akitiyan ijọba Naijiria lati rẹyin awọn agbesunmọmi ajinigbe ko ni so eso rere ti ijọba ko ba ni akojọpọ gbogbo araalu lori ẹrọ ayarabiiaṣa.

Musa lo sọ ọrọ naa lasiko ti awọn aṣofin n fi ọrọ wa lẹnuwo nile awọn aṣofin naa to wa niluu Abuja ki wọn to buwọlu iyansipo rẹ.

Ifọrọwanilẹnuwo ti awọn aṣofin ṣe fun yii lo waye lẹyin ọjọ kan ṣoṣo ti Aarẹ fi orukọ rẹ ranṣẹ ti wọn.

Nigba to n sọro nibẹ, o ni gbogbo ẹka ijọba Naijiria gbọdọ wọgile idunadura pẹlu awọn ajinigbe bo ṣe n waye lawọn orilẹede to ti goke agba lagbaye.

Musa sọ pe "Ko si idunadura kankan pẹlu awọn ọdaran.

"Ti a ba n fun awọn agbesunmọmi ni owo itusilẹ, niṣe la n ro wọn lagbara lati tun lọ ko ara wọn jọ lati pinlẹ ikọlu mii.

"Gbogbo awọn ilu ti wọn dunadura pẹlu awọn agbesunmọmi ni awọn ọdaran naa tun n pada kọlu lọjọ mii."

Ajagunfẹyinti ọhun sọ pe iṣẹ awọn ologun lo jẹ ida 25% si 30% pere lati yanju iṣoro naa, iyọku ni airiṣẹṣe awọn awọn ọdọ atawọn iṣoro mii.

Ọgagun naa ṣalaye siwaju si pe awọn eeyan kan tun ti bẹrẹ ijinigbe tuntun lori omi laarin ala to so ipinlẹ Akwa Ibom pọ mọ orilẹede Cameroon.

O tun sọ siwaju si pe iwakusa lọna aitọ lawọn agbegbe kan ni Naijiria tunbọ n jẹ ki iwa ọdaran gbilẹ si.

Musa tun tun fidi rẹ mulẹ pe awọn ṣọja to n yẹ awọn ọkọ wo loju popo yoo dinku nitori awọn yoo ko awọn ṣọja naa lọ sinu igbo nibi ti wọn ti nilo wọn.

Wo nǹkan méje tó yẹ kí o mọ́ nípa Christopher Musa, mínísítà ètò àbò tuntun

Christopher Musa ninu aṣọ iṣẹ ologun rẹ

Oríṣun àwòrán, NA

Ile igbimọ aṣofin Naijiria ti fontẹ lu ọgagun Christopher Musa gẹgẹ bii minisita fun eto abo lẹyin ifọrọrọwanilẹnuwo oni wakati marun un ti wọn ṣe fun.

Musa, to jẹ olori ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria ana ni awọn aṣofin na buwọlu lẹyin ọjọ kan ṣoṣọ fi Aarẹ fa orukọ rẹ kalẹ.

Ayẹwo rẹ yii lo waye lasiko ti Naijiria n koju ipenija eto abo to mẹhẹ, igbesunmọmi ati ijinigbe lemọlemọ.

Irufẹ iṣẹlẹ naa to waye lẹnu lọlọ yii ni ijinigbe awọn akẹkọọ marundinlọgbọn ni Maga, ipinlẹ Kebbi, pẹlu iroyin pe ko pẹ ti awọn ologun kuro lagbegbe ti awọn ọmọde naa wa ṣaaju ijinigbe ọhun.

Ọgagun Musa ti sọ pe ohun akọkọ ti oun yoo ṣe gẹgẹ bii minisita eto aabo ni iwadii ẹni pato to paṣẹ pe ki awọn ologun kuro lagbegbe ile ẹkọ awọn ọmọ naa ki wọn to ji wọn gbe.

O ni ileeṣẹ ologun kii ṣe ojo ti yoo maa sa fun awọn ọdaran.

Musa sọ pe "a maa wa gbogbo wọn ri pẹlu ajọṣepọ awọn ileeṣẹ agbofinro mii.

Bo tilẹ jẹ pe iha ariwa Naijiria lawọn agbesunmọmi ti n ji awọn akẹkọọ gbe lọ, ijinigbe lawọn agbegbe mii ti di iṣẹ to n pa obitibiti owo wọle fun awọn janduku.

Wayi o, minisita tuntun naa ti ke si ijọba atawọn araalu ki wọn dẹkun sisan owo itusilẹ.

O fi kun pe lawọn ibi ti wọn ba ti san owo itusilẹ, awọn le tọpinpin ibi ti owo ọhun n lọ.

Iwọnyii ni awọn ohun to yẹ ki o mọ nipa ọgagun Christopher Musa

  • A bi Ọgagun Musa lọjọ kẹẹdọgbọn oṣu Kejila ọdun 1967 niluu Sokoto.
  • Niluu Sokoto naa ni Ọgagun Musa ti lọ sile ẹkọ alakọbẹrẹ ati ile ẹkọ girama.
  • Lẹyin to kuro nile ẹkọ girama lo tẹsiwaju ẹkọ rẹ nile ẹkọ giga kan niluu Zaria nibi to ti kẹkọọ gboye lọdun 1986.
  • Lẹyin naa ni Musa wọ ile ẹkọ giga ologun NDA nibi to ti kẹkọọ gboye akọkọ fasiti lọdun 1991.
  • Ọgagun to to gbangba sun lọyẹ ni Musa jẹ, lara awọn ami ẹyẹ to ti gba lẹnu iṣẹ ologun ni ami ẹyẹ Colin Powell lọdun 2012.
  • Lọdun 2023 ni Aarẹ Tinubu yan an gẹgẹ bii olori ileeṣẹ ologun orilẹede Naijiria, ipo yii lo si wa titi di oṣu Kẹwaa ọdun 2025 yii ki o to kuro nibẹ.
  • Tinubu sọ ninu lẹta to kọ sile aṣofin agba wi pe oun ni igboya ati igbẹkẹle ninu Ọgagun Musa lati dari eto aabo orilẹede Naijiria lọna to yẹ.

Tinubu yan Christopher Musa ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ológun Naijiria tẹ́lẹ̀ sípò mínísítà ètò ààbò, lẹ́yìn tí Abubakar kọ̀wé fipò sílẹ̀

Ọgagun Christopher Musa wọ aṣọ ologun, Aarẹ Bola Tinubu wọ agbada olomi aro, o si de fila

Oríṣun àwòrán, Defence headquarters/Bola Ahmed Tinubu/X

Aarẹ Bola Tinubu ti yan Ọgagun Christopher Musa olori ileeṣẹ ologun Naijiria tẹlẹ sipo minisita eto aabo.

Oludamọran aarẹ lori eto iroyin, Bayo Onanuga, lo fidi ọrọ naa mulẹ loju opo X rẹ lọsan an oni ọjọ Iṣẹgun ọjọ keji oṣu Kejila ọdun yii.

Ninu lẹta ti Tinubu fi ṣọwọ si aarẹ ile aṣofin agba l'Abuja, Sẹnẹtọ Godswill Akpabio, fun ibuwọlu ni aarẹ ti ṣalaye pe Musa ni yoo rọpo Alhaji Mohammed Badaru Abubakar minisita eto aabo tẹlẹ to kọwe fipo silẹ lọjọ Aje.

Alhaji Abubakar sọ pe nitori ilera ara oun loun fi kọwe silẹ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Kí nídìí tí Mínísítà fétò ààbò, Badaru Abubakar fi kọ̀wé fipò sílẹ̀?

Badaru Abubakar wọ agbádá, ó jókòó sórí àga, ó ń wo ọ̀ọ́kán

Oríṣun àwòrán, Voice of Nigeria

Mínísítà fétò ààbò Nàìjíríà, Badaru Abubakar ti kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀.

Àtẹ̀jáde kan tí agbenusọ Tinubu, Bayo Onanuga fi sójú òpó X rẹ̀ lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ Kìíní, oṣù Kejìlá, ọdún 2025 ní ìkọ̀wé fipò sílẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ lẹ́yẹ ò sọ́ka.

Onanuga nínú àtẹ̀jáde náà ṣàlàyé pé ààrẹ Tinubu gba ìkọ̀wéfipòsílẹ̀ Badaru, tó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún iṣẹ́ takuntakun tó ṣe lẹ́ka ààbò lásìkò rẹ̀.

Ó fi kun pé ó ṣeéṣe kí ààrẹ fi orúkọ ẹni tó máa rọ́pò Badaru ránṣẹ́ sílé aṣòfin kí ọ̀sẹ̀ yìí tó wá sópin.

Ìkọ̀wéfipò sílẹ̀ mínísítà yìí ló ń wáyé lásìkò tí Nàìjíríà ń kojú ìpèníjà ààbò tó lágbára báwọn agbébọn àti agbéṣùmọ̀mí ṣe ń ṣe ìkọlù lọ́kan-ò-jọ̀kan lẹ́ka àríwá Nàìjíríà.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá nì ààrẹ kéde àwọn ìgbésẹ̀ pàjáwìrì lẹ́ka ètò ààbò lẹ́yìn táwọn agbébọn ṣe àwọn ìkọlù ọ̀tun ní ìpínlẹ̀ Kebbi, Niger àti Kwara.

Jíjí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ márùndínlọ́gbọ̀n gbé ní ìpínlẹ̀ Kebbi àtàwón akẹ́kọ̀ọ́ tí iye wọn fẹ́ ẹ̀ tó ọ̀ọ́dúnrún gbé ní ilé ẹ̀kọ́ St Mary's Catholic School, Papiri, ìpínlẹ̀ Niger jẹ́ ohun tó tún fa awuyewuye àti ìbẹ̀rùbojo lẹ́ka ààbò Nàìjíríà.

Bákan náà ni ìkọlù àwọn agbébọn sí ilé ìjọ́sìn CAC ní Eruku, ìpínlẹ̀ Kwara àti ìjínigbé tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Kogi mú kí àwọn èèyàn máa sọ pé apá ìjọba kò ká ètò ààbò tó mẹ́hẹ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Àtẹ̀jáde tí agbẹnusọ Ààrẹ Tinubu fi léde sọ pé Badaru fipò sílẹ̀ látàrí ìlera rẹ̀ tí kò dúró ire.

Ẹ̀wẹ̀, láti ìgbà tí Badaru ti wà ní gẹ́gẹ́ bí mínísítà fétò ààbò ni ìkọlù àwọn agbébọn ti ń tẹ̀síwájú lẹ́kun ìwọ̀ oòrùn àríwá, tí ìkọlù àwọn Boko Haram sì ń tẹ̀síwájú ní ẹkùn ìlà oòrùn àríwá Nàìjíríà.

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tó ṣe pẹ̀lú BBC lọ́sẹ̀ tó kọjá, Badaru sọ pé ìjọba Nàìjíríà ń sa gbogbo ipá rẹ̀ láti kojú ìpéníjà ààbò tó ń bá Nàìjíríà fínra.

Ó ní ìjọba ti ń ṣe ìwádìí láti mọ ohun tó ṣokùnfà ìdí tí ìkọlù àwọn agbébọn ṣe tún bẹ̀rẹ̀ ìkọlù lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí àti jíjí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbé ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ káàkiri Nàìjíríà.

"Mo fẹ́ sọ àrídájú rẹ̀ pé àwọn ọmọ ogun ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti wá ọ̀nà tí wọ́n fi máa kojú ìṣòro yìí."

Ta ni Badaru Abubakar?

Mohammad Badaru Abubakar ló ti fìgbà kan rí ṣe gómìnà ìpínlẹ̀ Jigawa fún sáà méjì.

Láàárín ọdún 2015 sí 2023 ló fi ṣe gómìnà ìpínlẹ̀ Jigawa.

Lẹ́yìn tó kúrò lórí ipò ni ààrẹ yàn-án sípò Mínísítà fétò ààbò nínú oṣù Kẹjọ, ọdún 2023.

Onímọ̀ nípa ètò ìsúná ni Badaru bó ṣe kẹ́kọ̀ọ́ gboyè "Accountant" ní ilé ẹ̀kọ́ fásitì, Ahmadu Bello University, Zaria.

Bákan náà ló kẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ Policy and Planning Training Institute, Jos, ìpínlẹ̀ Plateau.

Ó tún jẹ́ oníṣòwò tó ní okoòwò káàkiri Nàìjíríà.

Ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́ta ni Badaru Abubakar.