Àkójọpọ̀ ìkọlù tó ti ṣẹlẹ̀ ní Naijiria lẹ́yìn tí Tinubu kéde ìlú ò fararọ lẹ́ka ètò ààbò

Oríṣun àwòrán, AUDU MARTE/AFP via Getty Images/Google
Oriṣiiriṣii ikọlu awọn agbebọn lo ṣẹlẹ ni ọsẹ ti Aarẹ Bola Tinubu ṣe ikede pajawiri lẹka eto aabo lorirẹede Naijiria.
Orilẹede Naijiria n koju oniruuru ipenija lọwọ yii latari oriṣiiriṣii ikọlu tawọn janduku agbebọn n ṣe kaakiri papaa julọ lẹkun ariwa orilẹede yii.
Bi wọn ti n ṣe ikọlu si ile ẹkọ ni wọn tun n ṣekọlu si ile ijọsin kaakiri apa ariwa Naijiria.
Ṣaaju ikede ilu o fararọ Tinubu lawọn ẹgbẹ agbesunmọmi ISWAP ṣekupa awọn ọmogun Naijiria kan to fi mọ ọgagun kan to n jẹ Musa Uba.
Lẹyin naa lawọn agbebọn kan ya wọ ike ijọsin CAC kan niluu Eruku nipinlẹ Kwara nibi ti wọn ti ji awọn olujọsin mejidinlogoji gbe lọ ti wọn si tun pa awọn eeyan nibẹ.
Awọn janduku agbebọn naa tun ṣọṣẹ nile ẹkọ kan nipinlẹ Kebbi ati Niger.
O kudiẹ bayii bayii ko pe ọsẹ kan ti Tinubu kede ilu o fararọ lẹka eto abo, to si paṣẹ fun ileeṣẹ ologun ati ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ lati ṣẹgun awọn agbesunmọmi to n da ilu ru kaakiri.
Amọ, kaka ki ewe agbọn dẹ niṣe lo n le koko sii ọrọ ikọlu agbebọn to n ṣẹlẹ ni Naijiria.
Wọnyii lawọn ikọlu to ti waye lẹyin ikede ilu o fararọ Tinubu lẹka eto aabo.
Awọn agbebọn kọlu ile ijọsin C&S ni Kogi lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kọkanla
Lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kọkanla awọn janduku agbebọn tun ti ya wọ ile ijọsin kan nipinlẹ Kogi nibi ti wọn ti ji pasitọ ati iyawo rẹ pẹlu awọn eeyan mii gbe lọ.
Ile ijọsin ọhun ni a gbọ pe o wa lawujọ Ejiba ni ijọba ibilẹ guusu Yagba.
Oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Kogi kan lo fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fun BBC.
A gbọ wi pe ṣadeedee lawọn janduku agbebọn ọhun ya wọ ṣoọṣi C & S naa ti wọn si bẹrẹ sii yinbọn lera lera.
Iroyin naa sọ pe bayii lawọn olujọsin bẹrẹ si ni sa asala fun ẹmi wọn.
Ẹwẹ, agbẹnusọ ijọba ipinlẹ Kogi, Kingsley Fanwo, ti sọ pe ijọba n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ẹṣọ eleto aabo atawọn fijilante lati doola awọn tawọn agbebọn naa ji gbe lọ nile ijọsin C&S ni awujọ Ejiba.
''Loootọ ni mo gbọ nipa iṣẹlẹ ijinigbe to ṣẹlẹ, awọn ẹṣọ eleto aabo atawọn fijilante ti bẹrẹ iṣẹ lati mawọn janduku agbebọn naa.
Awọn to ṣiṣẹ laabi yii naa mọ pe ipinlẹ Kogi yoo ri pe gbogbo awọn eeyan ti wọn ji gbe lo kuro lakata wọn,'' Fanwo lo sọ bẹẹ fun BBC.
Ikọlu Bwari niluu Abuja lọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Kọkanla
Awọn janduku agbebọn ṣekọlu si agbegbe Gidan-bijimi nijọba ibilẹ bwari niluu Abuja nibi ti wọn ti ji eeyan meje lọ, gẹgẹ bii nkan tawọn olugbe agbegbe naa sọ fun ileeṣẹ tẹlifisan Arise.
Ọkan lara awọn eeyan naa sọ pe Suleiman Shuaibu to jẹ ibatan ọkan lara awọn ọdọbinrin ti wọn ji ọhun sọ pe ọjọ ori awọn ọmọbinrin ti wọn ji gbe bẹrẹ lati ọdun mẹtadinogun si ọdun mẹtalelogun nigba ti ọmọkunrin to wa laarin wọn jẹ ọmọ ọdun mẹrindinlogun.
Awọn o-ṣoju-mi-koro sọ pe ni nnkan boo ago mẹwaa alẹ l'Ọjọru ọsẹ to lọ ni iṣẹlẹ ọhun waye, nigba tawọn janduku ọhun bẹrẹ sii yinbọn soke tawọn eeyan si bẹrẹ sii sa asala fun ẹmi wọn.
Koda, a gbọ pe awọn fijilante to wa lagbegbe baa fẹsẹ fẹẹ nigba ti wọn ri iru nnkan ija oloro to wa lọwọ awọn janduku naa.
Awọn agbebọn ji agbẹ mẹrinlelogun lọ nipinlẹ Niger
Awọn janduku agbebọn tun ṣọṣẹ lawujọ Palaita nijọba ibilẹ Shiroro nipinlẹ Niger nibi ti wọn ti ji eeyan mẹrinlelogun lọ.
Koda, awọn obinrin alaboyun wa ninu awọn eeyan naa.
Ni nnkan bii aago meji ọsan ni iṣẹlẹ ọhun waye nibi tawọn eeyan ti n ṣiṣẹ ninu oko irẹsi.
Awọn to moribọ nibi iṣẹlẹ naa sọ pe awọn agbebọn naa pada ji awọn eeyan gbe, bi tilẹ jẹ pe agbegbe naa ko jina awujọ Erena nibi to jẹ ibudo awọn ọmogun.
Ijọba ipinlẹ Niger fidi iṣẹ ọhun mulẹ, amọ, wọn eeyan mẹwaa ni wọn gbe lọ.
Ẹwẹ, awọn ẹṣọ eleto aabo ti bẹrẹ iṣẹ ni pẹrẹu lati igba ti Tinubu ti kede ilu o fararọ lẹka eto aabo.
Ileeṣẹ ologun ni o le lawọn agbebọn ọdunrun un tawọn tuka ni ibudo wọn lawujọ Chibok ni nnka bii aago mẹta oru.
Bakan naa ni ileeṣẹ ologun tun ti ṣe aṣeyọri kan tabi omiran lawọn ipinlẹ maa papaa julọ lẹkun ariwa Naijiria.















