Ṣé lóòótọ́ ní ayẹta Yorùbá wà, àwọn wo ló le lò ó, kí ni èèwọ̀ rẹ̀ àti ìdí tó fi lè kùnà?

Oríṣun àwòrán, DSS
- Author, Olumide Owaduge
- Reporting from, Lagos, Nigeria
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Ọjọ Aje, ọjọ kẹta, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022 yii ni ileeṣe ọlọpaa ipinlẹ Kwara sọ ninu atẹjade kan pe ọmọde kan yinbọn pa aburo rẹ to jẹ ọmọ ọdun mejila, lasiko ti wọn n dan ayẹta wo.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni Kwara, Okasanmi Ajayi fi lede, o ni ọlọdẹ ni baba awọn ọmọ naa.
O ni lẹyin ti ibọn ọhun dun lara aburo, ni ayẹta naa kọṣẹ, eyi to mu ẹmi ọmọ ọdun mejila naa lọ lẹsẹkẹsẹ.
Okesanmi fi kun pe baba awọn ọmọ naa ti fẹsẹ fẹ bayii, amọ iwadii ti bẹrẹ.
Idi ree ti BBC Yoruba fi kan si awọn babalawo atawọn onimọ nipa iṣẹṣe ilẹ Yoruba, lati mọ boya lootọ ni ayẹta wa.
Irufẹ awọn eeyan wo lo le pese ayẹta fun eeyan, èèwọ wo ló dènà rẹ̀, ọjọ́ ori wo la ti le lo ati idi pataki ti ayẹta fi le kọṣẹ.
Ohun ti wọn sọ ree.
Ṣe lootọ ni ayẹta wa?
Nigba ti BBC Yoruba kan si babalawo kan, Idowu Olukunle Adewole, ni lootọ ni ayẹta to gbona wa nilẹ Yoruba.
Amọ o ni awọn eeyan ti fi ẹsin ati ọlaju fi ọwọ rọ ayẹta sẹyin ni.
Adewole, to tun jẹ Akoda Awo fun ijọba ibile Ọna Ara niluu Ibadan ṣalaye pe, lati aye lailai ni ayẹta ti wa, to si n jẹ bii idan.
BBC Yoruba tun kan si Ọba Ogboni Igba Iwase niluu Ile Ife, iyẹn Oyelade Adeyinka Adisa Arifanlajogun, oun naa dahun pe lootọ ni ayẹta wa nilẹ Yoruba.
O ni “Ayẹta gidi wa nilẹ Yoruba... wipe ko si ayẹta nilẹ Yoruba, ẹ jẹ ka tu danu, ayafi ẹni ti ko ba jogun ba a lọwọ awọn babanla rẹ.”

Oríṣun àwòrán, @YorubaHistory
"Omugọ lo maa n se ayẹta tan, ti yoo dan wo lara eeyan"
Nipa bi eeyan ṣe le dan ayẹta wo, babalawo Adewole sọ pe omugọ lo maa n ṣe ayẹta tan, ti yoo dan wo lara ọmọ eeyan.
O ni “Ẹni to ṣe ayẹta tan, to gbe kọ aburo rẹ lọrun lati dan wo, ori rẹ ko pe, ṣe ko ri igi oko nilẹ ti yoo gbe kọ lati yinbọn lu?”
“Ẹni ibi ni ẹni naa... ara nnkan bii igi tabi ẹranko lo yẹ ko ti dan an wo, to ba ti ṣisẹ, o n tumọ si pe ayẹta naa jẹ niyẹn.
Aṣiṣe nla lo ṣe lati dan ayẹta wo lara eeyan.”
Ọba Ogboni sọ pe “Ki eeyan to le dan ayẹta wo, o yẹ ko fi si ẹran lara fun bii ọjọ mẹta, lẹyin ọjọ kẹta, eeyan le lọ yin oriṣiriṣi ibọn si lara.”
Irufẹ awọn eeyan wo lo le pèèlè ayẹta?
Babalawo Adewole ni “Awọn babanla, atawọn mii ti wọn nbẹ, ti wọn ni iriri lo le peelo ayẹta.
O wa fikun pe o tun ni iwa ti irufẹ ẹni bẹẹ yoo maa wu ki wọn to gbe ogun le lọ lọwọ.”
Nigba ti Ọba Ogboni Igba Iwase nile Ife sọrọ, o ni ẹnikan ṣáá, ko kan le e maa peelo ayẹta.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, ti eeyan ba tilẹ ri iwe oogun ti awọn babanla rẹ ti kọ silẹ, o yẹ ko gbe iwe naa tọ awọn agbagba lọ fun iwadii ni kikun, ko le mọ bi wọn ṣe n lo o.
O ni “Awọn nnkan mii wa ninu elo ayẹta to jẹ pe ti eeyan ba lọ ka lori igi, irufẹ ẹni bẹẹ kọ gbọdọ fẹsẹ kan ilẹ, bi bẹẹ kọ, ayẹta ọhun yoo kọ iṣẹ.”
Ki ni idi ti ayẹta fi maa n kọṣẹ?
Ọba Ogboni Arifanlajogun ni ti ayẹta ba kọṣẹ, o ṣeeṣe ki eeyan ṣe eewọ rẹ ni.
O ṣalaye pe “Gbogbo oogun ti a ni laye lo ni eewọ tirẹ, fun apẹrẹ, ti eeyan ba pari iṣẹ tan.
Ti wọn si sọ fun pe ko gbọdọ ni ibalopọ fun ọjọ mẹtalelogun, to si lọ ni ibalopọ, irufẹ oogun bẹẹ maa bajẹ ni.”
“To ba jẹ pe a n tẹlẹ awọn eewọ yẹn ni, a ko ni ní gbogbo iṣoro ti a n ni laye ode oni.”
Ni ti Babalawo Adewole, o ni ayẹta ti ewe rẹ ko ba pe ko le ṣiṣẹ.
O ni “Ti ewe ba pe, kii fi eeyan pe ọmọ kekere, ti ọmọ kekere ba gbe dani yoo jẹ fun.”
A le fi ayẹta daabo bo awọn ọmọde lọwọ gbọmọ-gbọmọ - Babalawo
Adewole pari ọrọ rẹ pari tọmọde-tagba lo le lo ayẹta niwọn igba ti ewe rẹ ba ti pe.
Bẹẹ naa ni Ọba Ogboni Igba Iwase ni eeyan le gbe ayẹta fun ọmọ rẹ, paapaa laye ode oni ti wọn n ji awọn eeyan gbe yii.
Amọ o yan pe mimọ eewọ irufẹ oogun bẹẹ ṣe pataki.















