Ewé sunko, Ọmọọdẹ yìnbọn pa àbúrò rẹ̀ níbi tí wọ́n ti ń dán ayẹta wò!

Ogun abenu gọngọ lọrun eeyan kan

Oríṣun àwòrán, other

Ọmọ ọdẹ kanni ilu Dutse Gogo nitosi Kaiama nipinlẹ Kwara ti yinbọn pa aburo rẹ lasiko ti wọn n dan ogun ayẹta ti baba wọn ṣẹṣẹ ṣe wo.

Ọmọ ọdẹ naa ti orukọ rẹ n jẹ Abubakar Abubakar pẹlu baba rẹ ati aburo rẹ ti orukọ rẹ n jẹ Yusuf Abubakar gbiyanju lati dan ogun ayẹta naa wo lọjọ Aiku, ki ọrọ to ba ibomiran yọ, ni ewe ba sunko.

"Ọmọ ọdun mejila ni aburo ọmọ ọdẹ ti wọn dan ayẹta wo lara rẹ"

Atẹjade kan ti ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara fi sita ṣalaye pe nnkan bii ọwọ alẹ ọjọ Aiku ni isẹlẹ naa waye, lẹyin eyi ni iroyin de agọ ọlọpaa to wa ni Kaiama.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Ajayi Ọkasanmi ṣalaye pe ọmọ ọdun mejila ni aburo ọmọ ọdẹ ti wọn dan ogun ayẹta wo lara rẹ naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ti bẹrẹ iwadii lori ọrọ naa, awọn si ti da awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ sigboro lati wa ẹgbọn ọmọdekunrin naa, ti wọn sọ pe o ti na papa bora bayii ri.

“Iṣẹlẹ naa waye lẹyin ti wọn ti dira wọn pẹlu ogun ayẹta naa, eyi ọmọ to jẹ ẹgbọn gbe ibọn ṣakabula baba rẹ sita, o si yin in lu aburo rẹ.

Ewe sunko, Yusuf Abubakar, ọmọdekunrin ẹni ọdun mejila fara gbọta, o si ku lẹsẹkẹsẹ.”