''Ọkùnrin 500 fipá bá mi lọ̀pọ̀ kí n lè dé ìlú òyìnbó''

Aworan

Arabinrin kan to n jẹ Ada, ti sọ iriri rẹ lori ohun ti oju rẹ ri lati rin irinajo lọ silẹ Yuroopu.

Bakan naa lo sọ bi awọn ọkunrin to le ni ẹẹdẹgbẹta ṣe fipa ba lọpọ, ti ọpọ ninu wọn si ni arun ibalopọ HIV.

A sọ orukọ arabinrin yii ni Ada, lati da aṣiri bo lori itan aye rẹ to sọ.

Ọdun 2016 lo ko si panpẹ awọn amunisin lẹni ogun ọdun.

Iṣẹ onidiri ni arabinrin yii n ṣe ni ipinlẹ Delta lasiko to pade ọkunrin kan to ni oun ni aburo kan to n ṣe onidiri ni Yuroopu, ti awọn oyinbo si fẹran irun awọn ọmọ Naijiria.

Idi niyii ti Ada se fi ile ati ọna rẹ silẹ, to si bẹrẹ irinajo lọ si ilẹ Yuroopu lati tẹsiwaju ninu iṣẹ onidiri to yan laayo lati Naijiria.

Amọ ko tilẹ beere iwe irina rara nigba to ti mọ pe ilẹ ni awọn ma a gba de ilẹ Yuroopu.

"Inu tirela to n gbe ẹran la gba lati ipinlẹ Niger"

''Irinajo wa bẹrẹ lati ipinlẹ Niger nigba ti a gba ori omi, a la inu oorun to gbona jain jain kọja wọ agbegbe aṣalẹ Sahara, ti a si lo oṣu kan ninu igbo.''

‘’Awakọ ti a wọkọ rẹ gba oju ọna, o tilẹ yẹ ki n ti ku sinu igbo naa amọ ori lo ko mi yọ.’’

''Awa ti a wa ninu ọkọ naa pọ, ti ọpọ wa si wa ni ẹyin ọkọ.''

''N ṣe ni gbogbo wa fi ẹgbẹ kan ẹgbẹ, ti wọn si da Taupaulin bo wa.''

O ni ''ọjọ kan ti awọn ọlọpaa da wa duro lọna wipe ki wọn wo ohun to wa ninu ọkọ, amọ awakọ wa yi oruka ọwọ rẹ, ti wọn si wo ibẹ pe ko si ẹnikankan nibẹ, ayafi ẹran.''

''Lẹyin naa ni a sa lo gbogbo ọgbọn, ti a si de orilẹede Algeria, ti a si wọ ilu Oran.''

''Awọn eniyan to ni arun HIV fi ipa ba wa lopọ.''

Aworan

Kii ṣe Ada nikan lo ti la iru alakọja yii ri, ọgọgọrun awọn ọdọbinrin miran lo ti la iru rẹ kọja, to fi mọ ọkunrin ati obinrin.

Ni Algeria, agbegbe kan wa ti wọn ma n gba lati wọ orilẹede Morocco, ti wọn si ma n duro di alẹ patapata, ki wọn to yọ wọ ibẹ.

Asiko yii ni awọn aṣọbode ko ni si nibẹ, ti wọn a si kọja si ilu Rabat.

Oṣu meji ni wọn ma n lo nibi yii, ti awọn eniyan a si maa fi ipa ba awọn eniyan lopọ lọsan ati lorun.

‘’Amọ ori ko awa yọ ni ilu yii nitori ati di ọmọ ọga, ko si si ẹnikẹni to le fi ọwọ kan wa.’’

‘’Lara awọn to n ba awọn eniyan lopọ nibẹ jẹ akanda, to fi mọ awọn to n ṣe aisan bii HIV, ti awọn miran yoo si tun ku sibẹ.

''Koda ko kan ẹnikẹni ti awọn arinrinajo yii ba loyun nitori awọn miran kii lo rọba idaabobo.''

"Bi mo ṣe bẹrẹ iṣe owo naabi ni Morocco..."

''Lẹyin ti a de Morocco ni wọn fi panpẹ mu mi ni Casablanca, ti wọ̀n si ni a ko ni iwe aṣẹ irinna lati lọ si ibi to wu mi.

Wọn ni mo jẹ obinrin to ṣanwo irinajo mi lati Naijiria de Morocco ni owo.''

''Iye owo to le ni ẹgbẹrun mẹrin Pọun owo ilẹ okeere ni wọn ni mo jẹ fun ọkọ oju omi to gbe mi wa.''

''Iye owo yii ni mo fi ọdun meji ati aabọ san, ki n le lọ ni alaafia.''

''Bakan naa ni a tun san owo ibusun ati ilegbe ni alaalẹ.''

Awọn miran ko mọ bi ọla wọn yoo ṣe ri amọ igbiyanju lo mu wọn tẹ ọkọ leti lọ si oke okun.

Awọn miran de ilẹ ileri Spain ti wọn ni lọkan lati lọ nigba ti awọn miran ku si ọna bii eefin.

Amọ awọn miran bi Ada, ti iwaju ko see lọ, ti ẹyin ko si se pada si fun, wa ni oju kan naa, ti wọn n gbiyanju ni ojoojumọ lati de ilẹ ileri wọn.