"N kò mọ bàbá mi, ìgbéyàwó mi súnmọ́lé, mo ṣì ń wá bàbá mi"

Obinrin ọmọ orilẹ-ede Kenya kan, Namukabo Werungah, to jẹ akọroyin, ti ṣalaye fun BBC ohun ti oju rẹ ri lasiko to n dagba lai mọ baba rẹ.
Werungah ko mọ boya aaye ni baba rẹ ọhun wa tabi o ti jade laye.
Bo tilẹ jẹ pe ọrọ naa kanka lọkan obinrin ọhun, amọ asiko ti igbayawo rẹ n sunmọle lo bẹrẹ si n wa baba rẹ naa kiri.
"Ọpọ ara abule mama mi lo n bu pe o gba oyun mi ni kekere ni"
Eyi si lo mu ki obinrin naa tẹkọ leti lọ si abule ti wọn ti bi, lati ba awọn mọlẹbi iya rẹ sọrọ nipa irufẹ eeyan ti baba rẹ jẹ.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, awọn eeyan bu atẹ lu iya rẹ naa nitori ṣe ni o gba oyun rẹ ni kekere, eyi to lodi si aṣa ilẹ adulawọ.
Werungah ni lati kekere lawọn eeyan ti maa n beere pe nibo ni baba oun wa, amọ oun ko mọ esi ti oun yoo fun wọn.
Lẹyin o rẹyin, o ṣawari baba rẹ, awọn mejeji si yọ mọ ara wọn.
Lẹyin naa lo gba awọn baba ti ko mọ ibi ti ọmọ wọn wa lati ṣawari irufẹ awọn ọmọ beẹ, ki ibaṣepọ to dan mọran le wa laarin awọn mejeji.






