Ransome for kidnappers: BBC Africa Eye ṣèwádìí nípa sísan owó fún àwọn ajínigbépawó

Àkọlé fídíò, Ǹjẹ́ sísan san owó ìdóòlà láti gba àwọn ọmọdé lọ́wọ́ ajínigbé dárá tó? BBC Africa Eye tú àṣírí síta

Iṣẹlẹ ijinigbe lorilẹede Naijiria kii ṣe eyi to farasin mọ loju gbogbo agbaye paapaa bo ṣe n di lemọ lemọ lapa ariwa orilẹede yii.

Eyi to tun wa n wọ awọn eeyan lara gan ni bi awọn ajinigbe ọhun ṣe maa n bere fun owo idoola awọn to wa ni ahamọ wọn eyi to jẹ pe lọwọlọwọ awọn ọmọ ile ẹkọ lo pọ ninu wọn.

Lapapọ o ti le ni ẹgbẹrun kan awọn ọmọ ile ẹkọ tawọn ajinigbe ti ko si ahamọ to fi mọ awọn olukọ ile ẹkọ jakejade iha ariwa orilẹede Naijiria.

Awọn obi ati alagbatọ wọn gan ti gba ile gba ita fun owo lati lee ri awọn ọmọ wọn gba pada.

Fun idi eyi, ọpọlọpọ idile lorilẹede Naijiria lo n bẹru lati ran awọn ọmọ wọn lọ si ile ẹkọ.

Ẹka ọtẹlẹmuyẹ ti ileeṣẹ BBC boju wo o finifini oriṣiriṣi ohun to ti ṣẹlẹ lawọn asiko naa to si n bu bẹntiroo si ina jiji eeyan gbe lroilẹede Naijiria boya sisan owo idoola tun fi awọn ti wọn ji gbe naa si ewu sii ni tabi bẹẹ kọ.