Nuhu Bamaiyi Poly Kidnap: Agbébọn tún ya bo ilé ẹ̀kọ́ Poly ní Kaduna, wọn jí ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ lọ

Abawọle ile ẹkọ

Oríṣun àwòrán, Nuhu Bamaiyi Polytechnic

O kere tan, akẹkọọ kan ti jade laye nigba ti awọn mẹta miran di awati lasiko ti awọn agbebọn ya bo ile ẹkọ Gbogbonse Polytechnic Nuhu Bamaiyi to wa nipinlẹ Kaduna.

Iroyin naa ni awọn isẹlẹ naa waye ni deede aago mejila aabọ idaji oni ọjọ Ẹti.

Gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ awọn olukọ nile ẹkọ naa, Aliyu Musa Kofa ti wi, awọn agbebọn naa yin akẹkọọ meji nibọn, ti wọn si ji mẹta miran lọ ati awọn olukọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Igba kẹta ree ti irufẹ isẹlẹ ijinigbe bayii yoo waye laarin ọdun kan lẹyin ti awọn agbebọn naa ji olukọ kan ati ọmọ rẹ meji losu kọkanla ọdun 2020 ninu ọgba ileẹkọ naa.

Kofa ni ọkan lara awọn akẹkọọ naa tawọn agbebọn ọhun yinbọn pa lo jade laye ni aarọ oni.

Àkọlé fídíò, Ogbomoso: Ẹ kálọ sí Ajilete láti mọ àwọn ibùdó tó mú kí ìlú náà yàtọ̀

Bakan naa lo ni iyawo ọkan lara awọn osisẹ ileẹkọ naa atawọn ọmọ rẹ meji ti gba idande laarọ oni.

Nigba to n fidi isẹlẹ naa mulẹ fun BBC, Kọmisana fọrọ abẹle nipinlẹ Kaduna, Samuel Aruwan ni ijọba yoo kọkọ sewadi ohun to sẹlẹ naa, ki oun to le sọrọ siwaju.

Amọ ọkunrin kan to n gbe nitosi ileẹkọ Gbogbonse naa sọ fun BBC pe ni aajin oru ni oun n gbọ iro ibọn lakọ-lakọ amọ oun kọkọ ro pe ariwo ibọn naa n wa lati ọkan lara ileesẹ ologun to wa nilu Zaria ni.

"Bi mo se n gbọ iro ibọn naa, mo ro pe idanilẹkọ ologun lo n lọ lọwọ, aarọ yii ni mo sẹsẹ gbọ nipa ohun to sẹlẹ."

Àkọlé fídíò, Funmi Aragbaiye: Ọlọ́run ní ohun táwọn olórí wa fẹ́ jẹ ni wọn ń wá