TCN: Naijiria ti ṣetán láti máa pín iná mọ̀nàmọ́ná sí Niger, Togo, Benin ati Burkina Faso

Oríṣun àwòrán, The Electricity Hub
Awọn orilẹ-ede mẹrin kan ni Afrika; Niger, Togo, Benin ati Burkina Faso ti n gbaradi lati ra ina mọnamọna, tawọn ọmọ Naijiria ko lo.
Alaga ati adari agba ajọ to n ri si ọrọ ina mọnamọna ni iha iwọ-oorun Afrika, WAPP, Sule Abdulaziz lo kede bẹẹ fun awọn akọroyin.
Abdulaziz, to tun jẹ adari ileeṣẹ to n ri si ọrọ ina pinpin ni Naijiria, TCN, sọ pe, awọn orilẹ-ede mẹrin naa n lakaka lati ra ina ọhun labẹ asia ileeṣẹ kan ti wọn ṣẹṣẹ n kọ lọwọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìrora iṣẹ́ abẹ ìdí tí mo ṣe pọ̀jù, mò ń kú lọ, mo fẹ́ padà sí bí mo ṣe wà tẹ́lẹ̀ - Bobrisky
- Bí mó bá fojú kan Baba Wande lórí ìtàgé, ṣe ní ẹ̀rù máa ń bà mí - Tafa Oloyede
- Wo ilúbìnrin tí wọn ti ń ní ìbálòpọ̀, bímọ̀ láì ní ọkọ
- Orí mi wú pé àkòkò ìjọba mi ní àṣeyọrí reluwé ń wáyé - Buhari
- Ọlọ́pàá àti ológun kò ní lójú àánú mọ́ fáwọn abàlújẹ́, ìyàtọ̀ yóò wà - Buhari
- Ẹ̀yin òṣèré tíátà, kò sí iṣẹ́ ọ̀fẹ́ mọ́, ẹ sanwó iṣẹ́ tẹ bá gbé fún mi - Funmi Awelewa
- Ẹ̀yin tẹ̀ ń pè fún ìyapa Nàíjíríà, òmùgọ̀ pátápátá ni yín - Obasanjo
- Kàyééfì! Ìyàwó bímọ mẹ́wàá lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, ọkọ kò níṣẹ́ lọ́wọ́
- Sunday Igboho ní òun ṣetán láti dira fáwọn ọ̀dọ́ Ibarapa fún ìpèsè ààbò aráàlú
O ṣalaye pe "Awọn ina ti a o maa ta ni awọn eyi ti wọn ko lo ni Naijiria."
"Awọn ẹrọ ti yoo maa fi ina naa ranṣẹ si wọn yoo maa pese ina ọhun lọna mii fun awọn nikan, nitori naa, kii ṣe lara awọn ina ti awọn ọmọ Naijiria n lo ni a fẹ ko lọ."
Gẹgẹ bo ṣe sọ, Naijiria n reti awọn ẹrọ to n pese ina ti wọn yoo lo lati pin ina bii 330KV lati Naijiria si Niger, Togo, Benin to fi mọ Burkina Faso.
O fi kun pe oju ọna ti wọn gbe ina naa gba yoo gun to n kan bii 875 kilomita.
Abdulaziz fi kun pe awọn ilu kan bii ẹgbẹta ti wọn yoo gbe ina ọhun gba, yoo janfani rẹ nitori awọn naa yoo ri ina lo, kii ṣe pe awọn kan fẹ ko ina lọ silẹ miran nikan ni.
O ni awọn ajọ banki agbaye, ajọ idagbasoke orilẹ-ede France ati banki idagbasoke ilẹ Afrika, AfDB lo n ṣe onigbọwọ eto ọhun.
Abdulaziz ṣalaye pe orilẹ-ede Naijiria ni yoo jẹ anfaani to pọ ju ninu eto naa ,nitori awọn ileeṣẹ apinnaka ni Naijiria ni yoo maa ko ina ọhun lọ s'awọn ilẹ mii.
O pari ọrọ rẹ pe "Lati ibẹ lọ, ọpọ owo ni yoo wọle, awọn eeyan ti ko riṣẹ ṣe naa yoo ri nnkan maa fi pa ọwọ pa."
Ẹwẹ, akọwe agba WAPP, Siengui Appolinaire-Ki sọ pe, iye owo ti iṣẹ naa yoo ba lọ, ko ni din ni $570 miliọnu, ṣugbọn awọn orilẹ-ede tii yoo janfaani iṣẹ naa yoo na ọwọ si iṣẹ ọhun.
O fi kun pe awọn onigbọwọ eto naa yoo na ọwọ si Naijiria atawọn orilẹ-ede ti iṣẹ naa kan kii eto naa le yọri si rere.














