Umoja Women‘s Village: Ìlúbìnrin tó gbajúmọ̀, àmọ́ tí kò fi ààyè gba ọkùnrin

Oríṣun àwòrán, Traveller
Yoruba ni airin jinna ni airi abuke ọkẹrẹ, bii eeyan ba rin jinna, yoo de ibi ti wọn ti n fi odo ibulẹ jẹun.
Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu ilu kan, to jẹ kikida obinrin lo n gbe ibẹ amọ ti wọn ko gba ọ̀kunrin kankan laaye lati maa gbe pẹlu wọn.
Orukọ ilu naa ni Umoja, o si jẹ abule kan ni orilẹ-ede Kenya ti oriṣiriṣi àwọn obìnrin to bọ lọwọ ifiyajẹni ọkùnrin n gbe.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kàyééfì! Ìyàwó bímọ mẹ́wàá lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, ọkọ kò níṣẹ́ lọ́wọ́
- Sunday Igboho ní òun ṣetán láti dira fáwọn ọ̀dọ́ Ibarapa fún ìpèsè ààbò aráàlú
- Àṣìta ìbọn pa ọkùnrin kan ní Ilesa níbi táwọn afurasí ẹlẹgbẹ́ òkùnkùn ti fìjà pẹ̀ta
- Iléesẹ́ Twitter ti ń bá ìjọba Nàìjíríà sọ̀rọ̀ papọ̀- Alhaji Lai Mohammed
- Àjọ EFCC mú àwọn afurasí aàdọ́ta tó ń lu jìbìtì lórí ayélujára ní Ibadan
- Ọ̀gbìn igbó kìí ṣe irúgbìn èṣù, ẹ pa èrò àtijọ́ tì, oríṣun ọrọ̀ ajé ni - Akeredolu
Awọn obinrin nikan ni wọn fi aaye gba lati ma a gbe ni Umoja laisi ọkunrin nibẹ.

Oríṣun àwòrán, INSH
Bawo ni ilubinrin Umoja se waye?
Ọdun 1990 ni obìnrin mẹẹdogun kan da abule naa silẹ, lẹyin ti wọn bọ lọwọ awọn ọmọ ogun ilẹ Gẹẹsi to n fi ipa ba wọn lo pọ.
Diẹ diẹ si ni èrò n pọ si ni abule naa, ti wọn si maa n gba àwọn obinrin to ba wa sa pamọ nitori iwa ipa ninu igbeyawo laaye nibẹ.
Ko yọ àwọn ọmọdebinri naa silẹ, to ba sa kuro ni ilu wọn nitori ki wọn o ma ba fi fun ọkọ.
Bakan naa ni awọn obinrin to ba sa fun abẹ́ dida ati ifipa báni lopọ pẹlu iwa ipa ati ifiyajẹni lọwọ ọkunrin maa n lọ tẹdo si abule naa.
Ẹ̀yà Samburu ni awọn obinrin naa ti wa.

Oríṣun àwòrán, The State
Lara àṣà àwọn eeyan ẹ̀yà naa si ni pe, ko si nkan to buru ninu ki wọn fi ipa ba obinrin lopọ, tabi ki wọn o fi ọmọdebinrin fun ọkọ tabi da abẹ́ fun.
Obìnrin kan ti wọn n pe ni Rebecca Lolosoli, to jẹ ẹ̀yà Samburu, lo jẹ adari àwọn to da abúlé Umoja silẹ.
Lẹyin ti oun fúnra rẹ bọ lọwọ awọn ọkunrin to lu u ni ìlùkulù nitori pe o ni ki wọn da ilu kan ti yoo jẹ ti awọn obinrin nìkan silẹ.
Idi ti wọn fi na Rebecca ni pe ko le jẹ ijiya fun bo ṣe ṣi àwọn obìnrin loju si ẹtọ wọn.
Awọn eeyan ẹ̀yà Samburu jẹ ibatan àwọn ẹ̀yà Maasai, ti wọn si jọ n sọ èdè kan naa.
Ni ẹ̀yà Samburu, awọn ọkunrin lo ma n ṣe ipade apero nípa abule wọn, àmọ́ ti awọn obinrin ma n duro ni ìta ile ibi ti ipade ba ti n waye.
Igba ti wọn ba ni ki obinrin sọrọ nìkan ni wọn gbọdọ sọrọ l'ori ohun to n lọ.
Gẹgẹ bi ìtàn ṣe sọ, ìlú Samburu ni gbogbo àwọn to kọkọ de ilu Umoja ti wa.
Amọ nigba to ya, awọn obinrin ati ọmọdebinrin to gbọ nipa 'aabo' to wa nibẹ bẹrẹ si ni darapọ mọ wọn lati kọ nipa bi wọn ṣe n ṣe òwò.
Bawo ni awọn obinrin nikan se n gbe ile aye nilu Umoja?
Awọn eroja asaraloge, ilẹkẹ àti àwọn nkan igbafẹ ni wọn fi n ṣe iṣẹ aje.
Bakan naa ni wọn tun ma n kọ awọn obinrin ati ọmọdebinrin to wa ni awọn abule ẹ̀yà Samburu to yi wọn ka ni ẹkọ.
Awọn idanilẹkọ yii si lo da lori ewu to wa ninu ṣíṣe igbeyawo ni ọmọde, ati abẹ́ dídá fun obinrin.
Nini àwọn ẹ̀gbà ọwọ, ti ọrùn ati awọn eroja isaraloge mii to jẹ oju ni gbese, jẹ àṣeyọrí pataki ni ẹ̀yà Samburu.
Nibi ayẹyẹ kan ti wọn n pe ni 'beading' ni baba ọmọbinrin yoo ti fun ni awọn ẹgba ọrùn, ti baba naa yoo si yan ọkùnrin àgbàlagbà kan to ba jẹ jagunjagun, lati fẹ ọmọ naa ni iyawo.
Ni Samburu, èèwọ̀ ni ki ọmọdebìnrin loyun, se ni wọn yoo pàṣẹ fun ọdọbinrin to ba loyun pe ko ṣẹ, koda ko jẹ pe o ṣe igbeyawo lọmọde.
Idi ni pe ko ni ni okun fun oyun, nitori irora bi ibalopọ ṣe ba ojú ara rẹ jẹ latari ọjọ ori rẹ to kere fun igbeyawo ati apọju ẹjẹ ti yoo da lára rẹ lasiko ìbímọ.
Bawo ni wọn ṣe n bímọ ni abule Umoja?
Gẹgẹ bi àṣà wọn nilubinrin yii, eewọ ni fun awọn obinrin naa lati ni ọkọ, àmọ́ wọn le mu ọkunrin wá lati abule mii, ko le fun wọn loyun.
Awọn ọkunrin wọnyii lo n ba wọn mojuto nkan ọsin wọn, ojuṣe kan ṣoṣo ti wọn si ni, ni lati fun awọn obinrin naa loyun.
Nitori pe wọn ko faaye gba ọkùnrin lati gbé pẹlu wọn, ibalopọ naa kii ṣe pẹlu agidi, àmọ́ pẹlu suuru, ki wọn le ma a loyun.
Awọn obinrin to dàgbà lo n se akoso abule Umoja, ti awọn ọdọbinrin wọn si jẹ jagunjagun.
Abule naa paapaa ni ile ẹ̀kọ́ alakọbẹrẹ, gbọ̀ngàn àṣà, ati awọn ibudo fun awọn arìnrìn-àjò igbafẹ to ba wa si Igbo igbafẹ Samburu National reserve.
Awọn arìnrìn-àjò naa ni wọn ma n ta àwọn ilẹkẹ ati ẹṣọ ara ti wọn n ṣe fún.





















