Omotola Jalade Ekeinde: Ọ̀nà láti ran Ìyá mi lọ́wọ́ lẹ́yìn ikú Bàbá mi mú mi wá iṣẹ́ lọ lẹ́ni ọdún 15

Àkọlé fídíò, hhhhhh

Gbajugbaja oṣerebinrin ni, Omotola Jalade Ekeinde sọ ibẹrẹ irinajo aye rẹ lẹkunrẹrẹ lasiko to n ṣabẹwo sile iṣẹ BBC.

Omotola ni oun ti ni owo oun lọwọ to pọ ti kii ṣe owo ọkunrin kankan ki oun to ṣe igbeyawo lẹni ọdun mejidinlogun.

O sọ oun ti oju rẹ ri to lẹyin iku baba rẹ ki o to jade ile ẹkọ girama ati ọna lati pese itọju fun aburo rẹ meji ati iya rẹ to ti di opo ọsan gangan lasiko naa.

Omotola

Oríṣun àwòrán, @Omotola

Gbajugbaja oṣere yii ni: ko si ẹnikẹni to le jẹ orukọ Ọmọtola mọ ni 'Trade mark'.

O ni: Mo mọọmọ 'Trademark' Omotola ni nitori pe ọpọ eeyna lo n fi orukó mi ṣe gbajuẹ.

'Omo Sexy' ni mo fẹ 'Trademark' tẹlẹ ṣugbọn ijọba Naijiria ko tii gba a.

Omotola

Oríṣun àwòrán, @Omotola

Nigba ti BBC Yoruba n fi ọrọ wa Omotol;a Jalade Ekeinde lẹnuwo lo ṣalaye pe oun le gba ọmọ oun to ba ti ṣetan to si ni owow lọwọ to le da duro laaye ara rẹ pe ki o lọ ṣe igbeyawo lẹni ọdun mejidinlogun bii ti oun.

Nitori ọgbọn ati iwa ni eeyan nilo pẹlu owo lati fi di lọkọ laya.

Omotola, iya ọmọ gende mẹrin ti wọn ti dagba ṣalaye pe awọn obinrin akọni lo di 'Nollywood'mu bayii nitori pe awọn kan ti fara ṣiṣẹ sẹyin lagbo oṣere NAijiria.

O ni ko yẹ ki oṣerebinrin kankan tun maa ṣo pe ọkunrin kanakan n dunkooko mọ oun mọ lati ri oore ọfẹ lati kopa ninu ere kankan lasiko yii.

Bakan naa ni Omotola sọrọ lori ọrọ to n lọ nigboro pe nkankan wa laarin oun ati gomina ipinlẹ Edo tẹlẹ, Adams Oshiomole ni eyi to ni koda, oun ko ri Adams ri laye oun lojukoroju.

Nipari Omotola gba awọn obinrin ati ọdọ nimọran pe idi iṣẹ ẹni la ti n mọni lọlẹ.