Yollywood: Odunlade Adekola, gbajúgbaja òṣèré tí wọ́n ń jẹ ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́nu

Oríṣun àwòrán, Odunlade Adekola/Instagram
A bí i ní ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n osù kejìlá ọdún 1976. Ọmọ ilu Otun Ekiti, ìpínlẹ̀ Ekiti ni Odunlade.
Òsèré tíátà, olóòtú àti olùdarí eré ní Nàìjíríà ni. Òhun ni alásẹ àti olùdarí ilé isẹ́ fíìmù Odunlade Adekola (OAFP).

Oríṣun àwòrán, odunomoadekola
- Àwọn òṣèré tíátà Yorùbá ọkùnrin táyé ni wọ́n rẹwà
- Ẹ wo báwọn òṣèré tíátà kan yóò ṣe rí lọ́jọ́ ogbó
- Àwọn òṣèré tíátà kan rèé, tí wọn fẹ́ ara wọn, tí ìgbeyàwó wọn sì pẹ́
- Ọ̀pọ̀ òṣèré tíátà tó ń sàìsàn ni kò ṣe dáadáa f'ẹ́gbẹ́ - Jide Kosọkọ
- Iṣẹ́ ọpọlọ ló yẹ ká ṣe nínú tíátà, kìí ṣe àfihàn ara bíbó àbí ìhòòhò wa - Binta Mọgaji

Oríṣun àwòrán, oduomoadekola
Ó bẹ̀rẹ̀ eré tíátà rẹ̀ ní kékeré nípa síse ẹ̀fẹ̀ nínú àwọn ere orí ìtàge ní ìjọ rẹ̀ nígbà náà lọ́hun to si bẹrẹ si ni di gbajugbaja pẹlu ipa rẹ ninu ere "Asiri Gomina wa" lọdun 2003.
Ilu Abeokuta ni ipinlẹ Ogun ni Odunlade Adekola dagba si to si ti lọ ile iwe alakọbẹrẹ to fi mọ ile iwe girama ko to lọ tẹsiwaju nile iwe giga akọṣẹmọṣẹ Moshood Abiola.
- Fáàbàdà! Peter Okoye lóun ò ṣèlérí N60m fún Tacha, Zlatan gbórin tuntun jáde
- Ariwo sọ, wọ́n fọwọ́ òsì júwe ilé fún Tacha lórí ètò àgbéléwò BBNaija
- Kàyééfì rèé! Kábíyèsì fẹnu ara rẹ̀ tú àṣírí àwọn Fulani Daran daran tó ń ṣọṣẹ́ nílùú rẹ̀
- Èèmọ̀ rèé! Àṣírí ilé tí wọ́n ti ń fipá bá àwọn ọmọdékùnrin lò tú síta
- Ta ni 'Mad Melon' ọ̀kan lára àwọn akọrin Danfo Driver tó d'olóògbé?

Oríṣun àwòrán, odunomoadekola
Odunlade Adekola tun lọ ka iwe kun iwe ni fasiti ilu Eko nibi to ti kawe gboye ninu imọ ẹkọ "Business Administration".
Ọdun 1996 gan ni Adekola bẹrẹ iṣẹ fiimu ṣiṣe nigba to dara pọ mọ ẹgbẹ awọn oṣere ni Naijiria.
Lati igba naa, o ti kopa ninu ọpọlọpọ ere ti ko lonka, oun gan ti kọ ọpọ ere o si ti dari ati ṣe agbejade ọpọlọpọ fiimu.
- Lizzy Anjorin: Mi ò bẹ Toyin o! Ẹ̀yin olólùfẹ́ mi àti ẹbí ni mo bẹ̀
- Kemi Olunloyo dá sí ìjà Toyin Abraham àti Lizzy Anjorin
- Mr Latin, Jide Kosọkọ àti Mama Rainbow sọ̀rọ̀ lórí ìjà Toyin ati Lizzy
- Ọkọ Toyin Abraham pẹ́ ọ̀rọ̀ sọ lórí aáwọ̀ láàrin ìyàwó rẹ̀ àti Lizzy Anjorin
- Mi ò fẹ́ dá sí ìjà Toyin ati Lizzy! - Madam Saje

Oríṣun àwòrán, odunomoadekola
Odu ni Odunlade Adekola, ọna to si n gba ṣe ipa kipa ti wn ba fun un maa n jẹ ara ọtọ eyi to mu ki awọn eniyan maa pe e ni ọ̀jẹ̀ òṣèré tó mọ iṣẹ́ rẹ̀.
Kii si aṣadanu ninu kiko ipa rẹ ninu ere eyi si ti mu ki awọn to fẹ́ ki o ba wọn ṣe iṣẹ mii tabi gbe iṣe tabi ọja wọn larugẹ n wa a pẹlu ọpọlọpọ owo.

Oríṣun àwòrán, oduomoadekola
Didi mọlumọọka ti mu ki Odunlade Adekola gba oriṣiriṣi ami ẹyẹ gẹgẹ bi oṣere to dantọ ni oniruuru ọna ninu ere tiata.
Odun o ba a mọ nibi ere ṣiṣe nikan, o tun fi iṣẹ orin kikọ kun un.
Baale ile ni Odunlade Adekola, o gbeyawo, Ọlọrun si fi ọmọ ta igbeyawo rẹ lọrẹ.

Oríṣun àwòrán, odunomoadekola















