Danfo Driver: Mad Melon' ọ̀kan lára àwọn akọrin Danfo Driver

Oríṣun àwòrán, Danfo Drivers, Mountain Black & Mad Melon
Ni ọpọ igba, wọn lee ma fi orukọ ranti eniyan ṣugbọn iṣẹ ti ẹni bẹẹ ṣe le maa fọhun koda bi ẹni na ko ba si ni sakani ibi to ti ṣe iṣẹ naa.
Ni ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kẹsan 2019 ni ariwo he sọ ni agbo ile olorin Raggae kan Oghenemaro Emeofa, ti gbogbo eniyan mọ si Mad Melon ni agbegbe Ajegunle ni ipinlẹ Eko.
Oun ati ikeji rẹ, Mountain Black ni wọn jọ kọ orin "Danfo Driver" to gba gbogbo igboro kan lọdun 1998 ati ọpọlọpọ orin mii.
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀
Ibẹrẹ awọn mejeji ko fibẹẹ dan mọran. Lati ri owo ounjẹ ounjọ, awọn mejeji wa ọkọ moluẹ l'Eko ko to di pe ile iṣẹ orin kan ri ẹbun inu wọn.
Tori na lati dẹrẹba Danfo to n na Ojo si Mile 2 l'Eko, wọn di ọkan lara awọn olorin ọmọ Naijiria lati Ajegunle ti awọn eniyan ti awọn eeyan si ti mọ lagbaye.
Mad Melon ati Mountain Black gba igboriyin kaakiri to bẹẹ ti wọn lo orin wọn lẹgbẹkẹgbẹẹ "African Queen ti olorin 2Face kọ ninu fiimu ilẹ Anerica kan.
Lọdun 2005, wọn tun sun orin wọn Danfo Driver siwaju sii nipa ṣiṣe agbejade awo Danfo Travel: Success Story lati sọ nipa bi wọn ṣe bọ ninu iṣẹ si aṣeyọri.
Lara orin wọn mii ti wọn tun kọ ni "Kpolongo" eyi to gbe wọn rinrinajo kuro ni Naijiria lọ silẹ Yuroopu lọdun 2006.
Latari eyi, wọn ti kọrin ni Athens, Sweden, UK, Germany, Spain, Italy, Switzerland atawọn orilẹede mii kaakiri agbaye.












