Benue Grave Site: Àwọn afurasí náà jẹ́wọ́ bí wọ́n ṣe máa ń bo àṣírí wọn

Ibojí òkú

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ajọ ọlọpaa Benue fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ fun awọn oniroyin

Ajọ ọlọpaa ni ipinlẹ Benue ti wu oku awọn eeyan mọkanla jade ninu iboji kan ti awọn ajinigbe sin wọn si.

Iboji naa ni awọn ọlọpaa ṣawari rẹ lagbegbe Gbatse, ni ijọba ibilẹ Ushongo, ni ipinlẹ lẹyin ti ọwọ ajọ ọhun tẹ awọn ajinigbe mọkanla.

Awọn ajinigbe naa ni ajọ ọlọpaa ni wọn jẹwọ pe iboji naa ni wọn ma na sin awọn ti wọn ba si.

Alukoro ajọ ọlọpaa ni ipinlẹ naa, Catherine Anene fi idi ọrọ yii mulẹ fun awọn oniroyin.

Adari ikọ agbofinro "Operation Zenda" to mu awọn afurasi naa, ni marun un ninu awọn afurasi ọhun ti na papa bora, ti wọn si ti n wa wọn bayii.

Ajọ ọlọpaa ni, awọn ọdaran naa lo ma n pa awọn eeyan lọna lati bo aṣiri wọn, lẹyin ti ti wọn ba ti ja wọn lole tan.

Nibayi, awọn ẹbi awọn ti ọrọ naa ṣẹlẹ si ti kesi ajọ ọlọpaa lati sa ipa wọn lọna lati rii pe wọn wa okodoro ọrọ naa, ki wọn si fi awọn aje ọrọ na ba ṣimọ lori jofin.