Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kaduna láwọn kò lè ṣọ pé èèyàn 66 kú ní Kajuru

Oríṣun àwòrán, El-Rufai
Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ni ipinlẹ Kaduna lawọn ko le fidi ọrọ mulẹ pe eeyan mẹ́rìndínláàdọ́rin lo padanu ẹmi wọn ninu ikọlu to waye niijọba ibilẹ Kajuru nipinlẹ Kaduna.
Ẹni to jẹ agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ naa Yakubu Sabo sọ fun BBC pe Kọmisana ọlọpaa nipinlẹ ọhun yoo ba awọn akọrọyin sọrọ nipa rẹ lọjọ aiku.
Nigba ti akọroyin bere lọwọ pe ki o tilẹ salaye ohun ti ọlọpaa mọ nipa iṣẹlẹ naa, o ni ọga ohun yoo sọ gbogbo rẹ nigba ti o ba ba awọn akọroyin sọrọ.
Lọjọ ẹti ni Gomina ipinlẹ Kaduna fiikede sita pe awọn agbebọn pa awọn eeyan Fulani mẹ́rìndínláàdọ́rin lawọn agbegbe kan ni ijọba ibilẹ naa.
Amọ, awọn eeyan kan to wa ni ipinlẹ naa ti lodi si ohun to sọ.
Ọgbẹni Ishaya Chinoko to jẹ ọga ajọ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri ni agbegbe iwọ oorun Naijiria sọ fun BBC pe ohun ko mọ wi pe iru nnkan bẹẹ ṣẹlẹ.
Ọga ajọ to n ja fun ẹtọ ọmọniyan tẹlẹ ni Naijiria ọjọgbọn Chidi Odinkalu naa da si ọrọ naa pẹlu bo ṣe ni ohun ko ro wi pe ootọ ni pe iṣẹlẹ naa waye.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Bakan naa ni iwe iroyin Punch lawọn ba olori awọn ọmọ lẹyin Kristẹni lorileede Naijiria sọrọ ti alaga ẹgbẹ ni ipinlẹ Kaduna Joseph Hayab si sọ ninu atẹjade pe Gomina lo ọgbọn ẹwẹ lati tanawọn ọmọ Naijiria ati awọn onwoye lati ilẹ okere ni.
Ipinlẹ Kaduna jẹ ipinlẹ kan lariwa Naijiria ti ija ẹlẹsinmẹsin ati ẹlẹyamẹwa ti wọpọ laarin awọn darandaran Musulumi ati awọn agbẹ Kristẹni to wa lagbegbe naa.
Bakanna ni Gomina ipinlẹ Kaduna sọ laipẹ yii pe awọn ara ilu okere to ba fẹ toju bọ eto idibo Naijiria yoo jẹ iyanwọn niṣu.
Amọ ṣa o ti ṣalaye pe itunmọ ọrọ ti ohun sọ kọ ni yẹn.













