Omoyele Sowore: 'Fi ṣowore sílé kí ó tó pẹjù tàbí kí o ṣewọn

Oríṣun àwòrán, Omoyele Sowore
Ile ẹjọ giga apapọ ti kilọ fun Ọga agba ajọ DSS Yusuf Bichi lati tẹle aṣẹ ile ẹjọ pe ki wọn fi Omowole Sowore sile lẹyin ti o ti gba idalare ti o si ti pari gbogbo eto to yẹ nipa gbigba oniduro.
Ile ejọ yii lo kọ lẹta janranjanran ranṣẹ pada si ajọ naa ni ọjọbọ ọsẹ yii pe ajọ naa n tapa si aṣẹ ile ẹjọ to si le e mu wọ ẹwọn lairo tẹlẹ.
Ni ile ẹjọ ba paṣẹ pada pe ki wọn o fi Ṣoworẹ silẹ laarin wakati merinlelogun lẹyin ti ile ẹjọ ti daa silẹ ki o maa lọ.
Ṣe ni ọjọru Ọsẹ yii ni agbẹjọro rẹ, Fẹmi Falana ti lọ si ile iṣẹ ajọ naa lati ri Soworẹ sugbọn ti gbogbo akitiyan rẹ jasi pabo.
Ṣugbọn ọrọ gbẹyin yọ ni ọjọbọ ọsẹ yii nigba ti awọn Oṣiṣẹ ajọ naa ko fi aaye gba Falana lati wọle si inu ọgba wọn.
Nigba ti Falana de ẹnu ọna ile iṣẹ ajọ naa ni wọn ba bẹrẹ si i da riboribo lojuna lati maa ṣe jẹ ko ri onibara rẹ, Aguru Soworẹ lo sọ fun BBC bẹẹ.
Otẹsiwaju pe gbogbo ẹbi wọn si ti wa ni idaamu lori ọrọ naa.
Aburo rẹ yii ṣalaye pe Idaamu nla ni gbogbo rogbodiyan yii jẹ fun, iyawo, awọn ọmọ ati gbogbo ẹbi rẹ pata.
O wa sọ wi pe ohun ti ẹgbọn ohun n la kọja lọwọ awọn ajọ yii mu ipaya bawọn ni pataki lẹyin ti ile ẹjọ ti ni ki o maa lọ sile.
Ninu alaye rẹ lo ti ni ohun itiju lojẹ pe ijọba to n kede idajọ ododo gan naa ni ko fi apẹẹrẹ rere lelẹ ti ko si le fi aṣẹ ile ẹjọ lele to jasi pe ko si ijọba tiwa n tiwa.
Agbẹjọro Soworẹ miiran,Marshal Abubakar sọ wi pe bi ajọ naa ṣe n kọ eti ikun si ọpọ idajọ ile ẹjọ ti n pọ lapọju, ti ko si bu iyi kun Orilẹ ede yii.














