rAPC: Àwọn èèkàn olóṣèlú APC kéde ẹgbẹ́ tuntun

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Igun kan ni ẹgbẹ oṣelu APC ti ya sọtọ pẹlu orukọ tuntun ti wọn pe ni Reformed All Progressive Congress, rAPC.
Ni Ọjọọru ni wọn kede ẹgbẹ yii ti wọn si yan Onimọẹrọ Buba Galadima gẹgẹ bii alaga rẹ.
Ninu ọrọ ti alaga tuntun na a ba awọn oniroyin sọ nilu Abuja, Galadima ṣalaye pe gbogbo akitiyan lati ba awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu APC sọrọ lo ja si pabo.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Onimọ ẹrọ Galadima woye pe ẹgbẹ oṣelu APC ti ja awọn eeyan orilẹede Naijiria kulẹ ni ọdun mẹta to fi wa lori oye.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Alaga rAPC ni idojuti nla gbaa ni APC mu ba awọn eeyan to bẹẹ to fi jẹ wi pe ọpọ lo n tọka sii pe o buru ju iṣejọba to le kuro nipo lọ.
"Awọn smọ Naijiria gbe ijọba le APC lọwọ pẹlu ireti pe yoo mu ileri rẹ gbogbo ṣẹ. O bani ninu jẹ lati sọ eyi pe lẹyin iṣejọba ọdun mẹta, ofo ọjọ keji ọja ni ireti wa ja si."
Ohun ti awọn eeyan n sọ ni pe awọn igun nPDP to darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC lati ẹgbẹ oṣelu PDP ṣaaju idibo 2015 ni wọn n ṣe agbatẹru igun rAPC yii.
Bi ako ba ni gbagbe bi awọn eekan kan lẹgbẹ oṣelu PDP pẹlu ṣe bẹrẹ ẹhonu tiwọn niyi, eyi to mu wọn kuro ni ẹgbẹ oṣelu naa.












