Iléẹjọ́: Ẹ̀sùn Buhari ni fífi ẹ̀mí sòfò àti ìnákúná owó
Ile-ẹjọ giga ijọba apapọ nilu Oshogbo ti f'ọwọ si aṣẹ lati kan nipa fun Ile Aṣofin Agba l'Abuja lati bẹrẹ bi wọn yoo ṣe yọ Aarẹ Muhammadu Buhari nipo lori awọn ẹsun to tapa si iwe ofin Naijiria.
Adajọ Maureen Onyetenu lo paṣẹ naa l'Ọjọru lẹyin aba ti alaga ẹgbẹ awọn agbẹjọro Kanmi Ajibola ẹka ti ilu Ilesha to tun jẹ ajafẹtọ ọmọniyan.
Ẹ ranti pe awọn ajafẹtọ ọmọniyan kan kọwe si ile asofin agba l'Abuja ni bi oṣu mẹta ṣẹyin lati bẹrẹ ilana ti wọn yoo fi yọ Aarẹ Buhari loye lori ifẹmi eeyan ṣofo ati nina owo laigbaṣẹ lati ọdọ awọn aṣofin.
Wọn tun f'ẹsun kan Buhari pe ko ni iwe ẹri to le fi ṣe Aarẹ Naijiria
Ṣugbọn awọn ajafẹtọ ọmọniyan naa m'orile ile-ẹjọ ki adajọ le paṣẹ f'awọn aṣofin ki wọn le yọ Aarẹ Buhari lẹyin ti wọn kọ eti ikun si iwe ti wọn kọ si wọn.

Oríṣun àwòrán, @AsoRock
Wọn tun f'ẹsun kan Buhari pe ko ni iwe ẹri to le fi ṣe Aarẹ orilẹede Naijiria.









