Ondo Election Tribunal: APC jáwé olúborí ní ìdìbò sílé asojúsòfin

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Agbẹjọro fun Gboluja Ikengboju to jẹ asofin to n ṣoju ẹkun Okitipupa/Ilajẹ ni ipinlẹ Ondo n'ile Igbimọ Asofin, Olumide Ogunjẹ ti ni awọn ko fara mọ idajo ile ẹjọ to n gbẹsun to nii ṣe pẹlu eto idibo ni Naijiria.
Eyi ko sẹyin bi ile ẹjọ́ se wọ́gilé ìbò tó gbé Ikengboju Gboluga tó ń sojú ẹkùn ìdìbò Okitipupa/Irele nítorí ó jẹ́ ọmọ orílẹ̀èdè méjì, ti wọn si gbe e fun Albert Akintoye to ṣe ipo keji ninu eto idibo ọdun 2019.
Ogunje lasiko to n ba BBC sọrọ ni wi pe Asofin Ikengboju ni asẹ labẹ ofin orilẹede Naijiria lati dije dupo bi o ti le jẹ ọmọ orilẹede meji, amọ to jẹ orilẹede Naijiria ni wọn ti bi oun ati awọn obi rẹ.
O ni awọn n duro de adajo lati fun awọn ni iwe idajọ rẹ, ki awọn le lọ si ile ẹjọ kotẹmilorun fun igbẹjọ ti wọn naa.
Amọ, Agbẹjọrọ fun Albert Akintoye,Adamson Adeboro ni ẹjọ to yẹ ni adajọ da nitori Gboluga sọ fun ile ẹjọ wi pe oun ti jẹjẹ fun Ilẹ Gẹẹsi(UK) gẹgẹ bi ile oun, ti oun yoo si tẹlẹ gbogbo asẹ wọn.
Kíni òfin sọ nípa asòfin tó bá jẹ́ ọmọ orílẹ̀èdè méjì?
Ofin naijiria se alakalẹ lẹsẹẹsẹ lori ẹni to lasẹ lati dije dupo lorilẹede Naijiria fun ipo asojusofin ni Ile Igbimọ Asofin Naijiria.

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Gẹgẹ bi ofin Naijiria se la a kalẹ, ọmọ bibi Naijiria ni asẹ lati dije dupo lorilẹede Naijiria.
- Ko si ohunkohun ninu iwe ofin Naijiria to sọ wi pe ọmọ orilẹede Naijiria ti wọn bi si Naijiria, ti iya ati baba rẹ si jẹ ọmọ ilẹ Naijiria, ko ni asẹ lati dije dupo si Ile-Igbimọ Asofin Naijiria.
- Ofin Naijiria Sections 25-28 sọrọ nipa ofin to de ki eniyan jẹ ọmọ orilẹede meji.
- Section 25 sọ wi pe ọmọ ti wọn ba bi si orilẹede Naijiria, to tun ni iwe ilẹ miiran ni asẹ labẹ ofin lati dije dupo.
- Amọ iwe ofin naa ko faye gba ẹni ti wọn ko ba bi si Naijiria, ti iya ati baba rẹ ko si jẹ ọmọ orilẹede Naijiria lati dije dupo lorilẹede Naijiria.
- Bakan naa ni iwe ofin Section 66(1) fofin de ẹni to jẹjẹ fun orilẹede miran lati dije dupo ti o ba rufin ẹka ofin (Sections 25-28).
Asòfin PDP Ondo fìdírẹmi torí ó jẹ́ ọmọ orílẹ̀èdè méjì
Ṣaaju iwadii BBC Yoruba yii, ile ẹjọ to n gbọ ẹsun idibo ni ipinlẹ Ondo ti sọ wi pe oludije ni ẹgbẹ oselu APC, Albert Akintoye lo jawe olubori ni idibo sile asofin Naijiria, lẹyin to wogile idibo Ikengboju Gboluga to n soju ẹkun idibo Okitipupa/Irele ni ipinlẹ Ondo.
Ile ẹjọ naa wọgile idibo to gbe Gboluga ti ẹgbẹ oselu PDP wọle nitori Wọn fi ẹsun kan pé o jẹ ọmọ orilẹede meji(Uk ati Naijiria).

Oríṣun àwòrán, Others
Ile ẹjọ ni o lodi si ofin ki oloselu to jẹ ọmọ orilẹede miiran yatọ si Naijiria, ki o dije dupo si Ile Igbimọ Asofin, gẹgẹ bi ẹsẹ ofin Section 66 (1) ti iwe ofin orilẹede Naijiria.
Amọ agbẹjọro asofin naa, Olumide Ogunje ni awọn n lọ si ile ẹjọ kotẹmilọrun.
Labẹ ofin, Gboluga ṣi lẹ́tọ̀ọ́ lati wa ni ipo titi ti ile ẹjọ kotẹmilọrun ati ile ẹjọ to gajulọ ba da ẹjọ naa.














