Ebola: Ènìyàn méji ló ti kú lórí àìsàn Ebola lórílẹ̀èdè DRC

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ènìyàn méjì ni Ebola ti pa ní orílẹ̀-èdè DR Congo láàrin oṣẹ̀ mẹ́jì, Goma to kún fọ́fọ́ fún ọ̀pọ̀ àwọn ní wọn ti rí ènì ti ó ni ààrun náà.
Ní bayìí ibẹru bojo ní àwọn ènìyàn Rwanda wá nítori ìlú Goma pààlà pẹlú Rwanda ti àwọn ènìyàn sì tí ń rò ó pé àisàn náà le tan ju bó ṣe yẹ lọ.
Ní òwúrọ̀ ọjọ́run ni ọkunrin awakùsà kan kú ní Goma níbi ti ènìyàn tó le ni miliọnù meji ń gbé.
- Ọmọ Yorùbá tó bá ti rú òfin, ẹ gbé e jàntò - Oluwo
- Israel Adebajo: Ìlúmọ̀ọ́ká oníṣòwò tó fi òkò Stationery Stores pa ẹyẹ púpọ̀
- 'Nàìjíríà, ṣọ́ra, ogun ń sọ ilé ọlá di ahoro!'
- Kò sí ìwé ìrìnnà 'VISA' fáwọn ọmọ Naijiria tó hùwà àìtọ́ nígbà ìdìbò
- 1.2m dọlà ni obìnrin yìí ń gbà tó bá kọ ǹkan sí ojú òpó Instagram rẹ̀
O lé ni ènìyàn ẹgbẹ̀jọ ènìyàn tó ti kú nítori àìsàn Ebola láti ìgbà to ti bẹ́ sílẹ̀ ní nínú oṣù kẹrin ọdún 2018 ní àwọn abúle DRC.
Àjọ WHO tí kéde pé ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ni ọ̀rọ̀ Ebola yìí lọ́sẹ̀ tó kọja.
Ìgbà mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní àjọ WHO tí ló ìrú ìkéde yìí tó fi mọ àsìkò ti Ebola gba gbogbo ìhà Ìwọ̀-òòrun Afirika láàrin 2014 -2016 tó pa ènìyàn tó lé ni ẹgbẹ̀rún mọkànlá.

Ẹni tí ìṣẹ̀lẹ̀ ọhun tún bẹ̀rẹ̀ lóri rẹ̀ báyìí wá láti ìhà ìlà-òòrun arewa Ituri ti wọ́n si gbe e lọ si ilé ìwòsàn Kizba ní àgbègbè Goma lójọ kẹtàlá osù keje.
Lẹ́yìn èyí ni wọn ri àwọn àmì Ebola bii ki ẹ̀jẹ̀ máa ya, wọ́n ṣe àyẹwò àbájade àyẹwo yii ló fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Ebola ni . O gbẹmi mi ni ọjọ́rú.
Ní báyìí, àgbègbè méji ni Ebola n dà láàmú ni DR Congo, North Kiv àti Ituri, Goma ni olúlùú Kivu tó sì pààlà pẹ̀lú ìlú Gisenyi tó wà ni Rwanda.












