Ogedengbe Agbógun Gbórò, Akọni tó ń dẹ́rù ba ikú...

Ogedengbe

Oríṣun àwòrán, @Ooduavoice1

Àkọlé àwòrán, Ogedengbe Agbogungboro

Akinkanju Balogun ni Saraibi Ogedengbe to tun jẹ Obanla ilu Ijesha (Oba-Ala Ogedengbe ti Ileṣa Kinni).

Wọn a maa pe e ni alajẹ Ogedengbe Agbogungboro.

Ilu Atorin ni Ilesha, ipinlẹ Oṣun ni Eleduwa ti fi Ogedengbe ta awọn obi rẹ alagba Apasanforijiwa ati iyaafin Falupo lọrẹ.

Ilu yii ko ju iwọn ogun kilomita lọ si Ileṣa tii ṣe ilu iya rẹ.

Oke Oriṣa ni ilu baba rẹ eyi ti ko fi bẹẹ jinna ju bi Atorin naa ṣe ri si Ileṣa lọ ti wọn si jọ wa ni ijọba ibilẹ kan naa, Atakomosa East Local Government Area.

Awokọṣe rere ti oun funra rẹ di itan to si tun gbe aṣa ga lati igba ewe rẹ titi to fi wọ kaa ilẹ ni Ogedengbe.

Ọmọ Ijeṣa ni ere - Ogedengbe gboya ninu ilu rẹ o si ni ifẹ aiṣẹtan fun awọn ara ilu Ijeṣa bi o tilẹ jẹ pe o jẹ ẹnikan ti ko gba igbakugba ti ko si bẹru ẹnikẹni.

Àkọlé fídíò, Kayefi BBC Yorùba: Bàbá ọmọ, Mọ́ṣúárì, Ọlọ́pàá kẹ́jọ́ rò nípa òkú ọmọ tó pòórá

Igbakuugba ti ogun ba de, ile logun ba a tori gudugudu ni ko figba kan turaa lẹ lati doju ija kọ ẹnikẹni to ba tọja rẹ kii sii kaarẹ afi to ba bori ija naa.

Ẹni ti gbogbo ọkunrin fẹ ba dọrẹ ni bẹẹ si ni bi obinrin ko o lọna, wọn a ni beleyi o jẹ ọkọ ẹni ṣebi a ṣi jẹ ale ẹni.

Àkọlé fídíò, Ikogosi-Ekiti: Ilu ti omi tutu ti dapọ mọ gbigbona

Awọn oye ti wọn fi da a lọla nigba aye rẹ ko kere rara:

  • Balogun ilu Ileṣa
  • Seriki Ajanaku ti Ijeṣa
  • Ọgagun agba ikọ Ogun Ekiti Parapọ
  • Obanla ti Ijeṣa (Oba-Ala Ogedengbe ti Ileṣa Kinni)

Ìbí àti dídàgbà Ogedengbe:

Ohun to wu ni lori ninu itan akinkanju yii ni wi pe ki wọn to bi i ni Ifa ti fọhun pe oun ni yoo jẹ olugbala ilu Ijeṣa.

Wọn bi i bi wọn ṣe n bi gbogbo ọmọ to ku to si dagba gẹgẹ bi ọdọ to ja fafa ninu iṣẹ ṣiṣe.

Àkọlé fídíò, Mo máa n forin mi kìlọ̀ ìwà ìbàjẹ́ láwùjọ ni -Hameen

Eyi fi han pe o jẹ alagbara ọmọ to si tayọ awọn ẹlẹgbẹ ni gbogbo ọna.

Bi wọn ba jọ wọya ija, afi ko fẹyin wọn janlẹ ni gbogbo igba - eyi lo bi orukọ OGEDENGBE ti wọn fun un tori orukọ abisọ rẹ gan ni Saraibi.

Nigba to dagba, Ogedengbe doju ọpọ ifẹhonu ija han kọ awọn ara Ibadan ti wọn n fiya jẹ awọn ara Ijeṣa.

Lasiko kan ninu ifẹhonu ija han yii ni wọn ra a mu ti wọn si gbe e lọ Ibadan.

Àkọlé fídíò, Widows Day 2019: Mo máa ń sá kiri wá owó ilé ni -Opó

Kii ṣe ẹni to kọla tẹlẹ, lataari eyi lawọn ara Ibadan bu ila si oju rẹ ki wọn to tu u silẹ.

Ninu ikọ ogun ilu Ibadan, Ogedengbe ja fitafita titi to fi di Ọgagun o si wa pada lati lọ dari ikọ ogun ti ilu Ijeṣa.

Àkọlé fídíò, Ǹjẹ́ o mọ pàtàkì igi tó wà ní àyíká rẹ bí?

Ogun Jija Ogedengbe:

Lẹyin eyi, o ko ọpọlọpọ ọmọ ogun to pọ jọ ti wọn si doju ija kọ ilu Ibadan lọpọlọpọ igba.

Kii ṣe Ibadan nikan, o tun ba iṣẹ ogun jija rẹ de Ekiti, Akoko nibi to ti ta ọpọ wọn lẹru leyii fi jade ninu oriki rẹ pe "O ṣọkọ Ekiti ṣọkọ Akoko".

Àkọlé fídíò, Ọ̀ṣun Oṣogbo 2018: Ulrich Salazar wálé ọdún láti New York

Koda o tun gbe iṣẹ ogun jija rẹ ipinlẹ ti o n jẹ Edo lonii.

Ṣe ni Ọba ilu Benin ni lati tu u loju pẹlu ọpọlọpọ ilẹkẹ, ẹru, atawọn ohun pataki miiran pe ko ma gbe ogun de ọdọ awọn eeyan oun.

Àkọlé fídíò, AFCON 2019: Àwọn ọmọ Naijiria sọ̀rọ̀ lórí ìdíje Madagascar àná

Lẹyin eyi lo pada si ilu Igbara Oke lati tẹdo sibẹ. asiko yii kan naa ni awọn ara Ibadan tun dide ogun ti Ogedengbe si gba lati jẹ Balogun Ijeṣa ati Ekiti lati koju ilu Ibadan.

Ija yii le gan an to bẹẹ to to ọdun mẹsan an ko to dawọ duro.

Àkọlé fídíò, International Day Against Drug Abuse and Trafficking: ìdí ti mo fi ń mu oògùn olóró

Ọgagun Bower to jẹ Kọmiṣọnna Ọlọpaa ilu Ibadan nigba naa lọhun lo pari aawọ ogun yii lọdun 1886.

Gbogbo iwa akinkanju yii lo sọ Ogedengbe di akọni niluu rẹ to si fi di ọkan lara awọn ọkunrin to pataki ju lọ ni ilẹ Yoruba, orilẹ-ede Naijiria ati ilẹ Afirika.

Eyi ri bẹẹ nitori kii ṣe awọn ilu mẹrin taa ti darukọ yii nikan ti Ogedengbe ti jẹ gbajugbaja.

Àkọlé fídíò, Ijinigbe: BBC ṣe ìwádìí bí ikọ̀ IRT ṣe ń gbéjà ko awọn ajinigbe lójú

Ko da, o kan Ife, Ilorin to fi di wi pe ọta wa pọ to fẹ doju ija kọ ilu Ibadan.

Ogun ti Ekiti-parapọ gan an waye lẹyin ti wọn jagun ṣẹgun ogun Kiriji miran laarin ọdun 1877 - 1892. Ogun nla ni Ogun Kiriji jẹ ninu itan Yoruba.

Lati jẹ ki awọn ilu to parapọ lati jẹ ọwọ ogun kan naa wọ ara wọn daadaa,

Àkọlé fídíò, COZA: Ọpọ èrò ló jáde ṣe lòdì sí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ Fatoyinbo

Ogedengbe fẹ iyawo kaakiri gbogbo ibi to ti lọ jagun.

Itan sọ pe o le ni iyawo mọkandinlọgọrun ti Ogedengbe fẹ kaakiri ilẹ Yoruba.

Àkọlé fídíò, Itan Omi Erin

Itan kan tun sọ wi pe lasiko ogun kan, wọn bẹ Ogedengbe lori ṣugbọn o fi agba han iku bẹẹ si ni ara rẹ rin lọ lati gbe ori rẹ pada to si gbe e le ọrun ara rẹ.

Eyi mu ki awọn ọta rẹ tubọ maa wariri fun un tori wọn wo o pe ki wa lo lee pa Ogedengbe bi bibẹ lori ko ba lee ran an lọ salakeji.

Àkọlé fídíò, Kunle Afolayan: èmi kò fẹ́ fi ogún sílẹ̀ fún ọmọ mi

Ọrọ pọ ninu iwe kọbọ nipa Ogedengbe Agbogungboro, ko si ṣe sọ tan nitori akọni ti ko ṣee gbagbe ni nilẹ kaarọ o jiire ni.

Titi di oni, ami idanimọ to wa niwaju ile Ogedengbe ni ida lati ran ni leti asiko jijẹ akọni ti wọn bẹẹ lori to si tun ye e.

Àkọlé fídíò, Ẹrin Ijesa, Ọ̀ṣun Oṣogbo, àwọn ibùdó ìgbafẹ́ tí ó níi ṣe pẹ̀lú omi ní ilẹ̀ Yorùbá