BBNaija 2019: Ta làwọn ọmọ Yorùbá tó ń kópa nínú ètò BB Naija

Oríṣun àwòrán, @seyiawolowo
Lori ayelujara orukọ Awolowo tun ti di ohun ti awọn eeyan n jẹ lẹnu.
Amọ kii ṣe nitori Baba Obafemi Awolowo ti gbogbo wa mọ bi ẹni mọ owo, ọmọ ọmọ rẹ kan Seyi Awolowo laye n sọrọ nipa rẹ.
Seyi Awolowo wa lara awọn ọmọ Naijiria to nkopa ninu eto idaraya ilumọọka nii, BB Naija.
Lati igba ti eto naa bẹrẹ ti o si foju han ni awọn eeyan ti n ṣe eemo ohun to mu ki ọmọ ọmọ Awolowo lọ darapọ mọ eto naa.
Ọmọ ọgbọn ọdun ni Seyi Awolowo ti a si gbọ pe o jẹ oluda ile iṣẹ silẹ. Lara ohun ti wọn kọ nipa rẹ loju opo BB Naija, wọn ni o figba kan fẹ gbẹmi ara rẹ.
Nigba ti wọn bere ohun ti yoo fi owo to ba jẹ lori eto naa ṣe, Seyi ni oun yoo da owo naa sidi owo t'oun n ṣe. O fi kun un pe oun yoo ran awọn ile alaini naa lọwọ.
Awọn ọmọ Yoruba miiran wo lo n kopa pẹlu rẹ lori BBNaija?
Khafi
Ọmọ ipinlẹ Ekiti ni Khafi Kareem ti o si jẹ ọlọpaa nilu Ọba.
Khaffi a ma sọ ede maarun to fi mọ Yoruba ṣugbọn Yoruba rẹ ko dan mọran daadaa.

Oríṣun àwòrán, @KhafiKareem
Fọnran fidio yii ṣe afihan rẹ nibi ti o ti n gbiyanju lati sọ Yoruba lasiko ọdun Keresimesi ni ọdun 2016
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Khafi ni oun to le mu ki oun kuro lori eto naa ni ki wọn fi dandan mu oun lati ṣe nkan to niṣe pẹlu ibalopo.
Esther
Agbẹjọro ni Esther Agunbiade to wa lati ipinlẹ Eko.
O ni igbadun, owo ati iriri to wa lori eto naa ni oun wa wa to si ni oun fẹran ounjẹ pupọ.

Oríṣun àwòrán, Instagram/ts_esther
Oun ni agbẹjọro akọkọ ti yoo kopa lori eto naa.
Ọmọ ọdun mejilelogun ni Esther ti o si kawe gboye ninu imọ nipa ofin lati fasiti Olabisi Onabanjo.
Mike
Ipinlẹ Eko naa ni baale ile yi to jẹ elere idaraya to si tun jẹ olokoowo aladani ti wa.
Mike da ile iṣẹ to n ṣe siga silẹ nilu Ọba ti o si figba kan fẹ ṣoju Naijiria nibi idije Commonwealth lọdun 2018.

Oríṣun àwòrán, @aireyys
Awuyewuye waye nipa iṣẹlẹ yii ṣugbọn Mike ni awọn pada yanju rẹ.














