COZA: Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ ni ṣọ́ọ́ṣì COZA láàrọ́ yìí

Modele ati Biodun Fatoyinbo

Oríṣun àwòrán, Instagram/modele fatoyinbo

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Saaju ni Busola Dakolo aya gbajugbaja olorin Timi Dakolo fẹsun kan Pasitọ Biodun Fatoyinbo ti ijọ COZA pe o fipa ba oun lo pọ nigba kan.

Lẹyin eyi ni ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria sọrọ sita pe iwa ifipabanilopọ gbọdọ di ohun igbagbe ni awujọ wa.

Pasito Biodun Fatoyinbo to da ijọ COZA silẹ fi atẹjadee sita pe irọ ni ẹsun naa nitori oun ko fipa ba ẹnikẹni lo pọ ri laye ounCOZA: Mi ò fípá bá obìrin lò pọ̀ rí láyé mi - Pásítọ̀ Fatoyinbo.

coza
Àkọlé àwòrán, Awon obinrin ti n pe siwaju ijo COZA

Awọn obinrin ti pejọ pọ siwaju ijọ COZA ni Guzape ni Asokoro ni Abuja to jẹ olu ilu Naijiria fún iwọde lori ọrọ ifipabanilopọ.

coza
Àkọlé àwòrán, Pasito kuro nipo re

Ni ipinlẹ Eko, awọn eniyan ti n korajọ pọ lati ṣe iwọde lodi si ifipabanilopọ.

Opopona Mobolaji Bank Anthony ti ijọ COZA wa ni ipinlẹ Eko ni wọn pejọ pọ si fi n ṣe iwọde pe ko yẹ ki a gbọ iru eyi ninu ijọ Olorun.

coza
Àkọlé àwòrán, Ni ipinlẹ Eko, awọn eniyan ti n korajọ pọ lati ṣe iwọde lodi si ifipabanilopọ

Àwọn agbofinro ti dé sí ṣọ̀ọ̀sì COZA ni Eko.

coza
Àkọlé àwòrán, Aw#on agbofinro lo duro senu ona soosi COZA ni Eko

Àwọn agbofinro ti dé sí ṣọ̀ọ̀sì COZA ni Eko

Ojo ti bẹrẹ ni Ikeja nibi ti awọn eniyan ko ara wọn jọ si lati ṣe iwọde lori ọrọ ifipabanilopọ adari ijọ COZA.

coza
Àkọlé àwòrán, Pelu ojo to n ro naa ni awon eniyan si duro si fun iwode naa

Gbogbo awon to jade ninu ojo ni Eko n pariwo 'No to Rape' ni.

coza
Àkọlé àwòrán, Ariwo "No to Rape" ni wọn n pa ni iwọde ipinlẹ Eko

Ariwo " No to Rape" ni àwọn olùwọ́de ń pa nipinlẹ Eko nínú òjò.

coza
Àkọlé àwòrán, Awon eniyan kan n satileyin fun Busola Dakolo

Ero pupọ lo ti kun ita ile ijọsin Commonwealth of Zion Assembly nipinlẹ Eko.

Iroyin to n kan BBC lọwọ ni pe awọn ọmọ ijọ COZA nikan ni wọn n jẹ ko wọle inu ile ijọsin laarọ yii lati jọsin.

coza
Àkọlé àwòrán, Ariwo ifipabanilopọ gbọdọ dopin ni wọn n pa ni Abuja.

Iroyin ni, wọn n beere ibeere nipa ijọ naa lọwọ awọn olujọsin to n wọle ki wọn le mọ boya ọmọ ijọ ni wọn ni tootọ ki wọn to jẹ ki wọn wọle.

Bakan naa ni wọn tun n lo àwọn ami idanimọ ara ọkọ ayokẹlẹ fi da ogidi ọmọ ijọ mọ.

coza
Àkọlé àwòrán, Ni Asokoro ni tokunrin tobinrin ti jade wa fun iwode lodi si pasito COZAyii

Awọn ikọ #Churchtoo ni wọn n ṣeto iwọde ti Abuja ti wọn fi ni ki pasitọ Fatoyinbo fipo rẹ silẹ.

Loju ti wọn, wọn gba pe ko yẹ ki ẹsun ifipabanilopọ jade ni ile ijọ Olorun rara.

coza
Àkọlé àwòrán, Ifipabanilopo ni esun ti awon eniyan Naijiria setan lati gobgun ti bayii

'Pasitọ rẹ kìí ṣe Olorun rẹ' ni àkọ́lé ìwọ́de kan ni Abuja.

Iroyin ni sibẹ awọn olujọsin n wọ lọ sile ijọsin COZA ni nitori igbagbọ wọn.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Eyi ni iroyin tuntun to jade pe awọn agbofinro

Àwọn agbófinró ń gba ńkan sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn olùjọ́sìn ni COZA Abuja bii iwe jọ́tà, atawọn ohun eelo ikọwe silẹ.

Àkọlé fídíò, International Day Against Drug Abuse and Trafficking: ìdí ti mo fi ń mu oògùn olóró

Bakan naa ni iroyin to n tẹ wa lọwọ nsiyi sọ pe awọn oṣiṣẹ ni ijọ COZA ni Abuja ti duro lati ma fi aaye gba awọn oluwọde lati wọle rara.

coza
Àkọlé àwòrán, E ko le wonu ijo wa ni COZA Abuja

Modele Fatoyinbo to jẹ iyawo Pasitọ Biodun Fatoyinbo ti wọn fẹsun kan lori ifipabanilopo ti sọrọ.

coza

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Modele yari pe kò ṣeeṣe fun ọkọ oun lati fipa ba ẹnikẹni lo pọ

O ni ọkọ oun ko lee fipa ba ẹnikẹni lo pọ nitori oun jẹri ọkọ oun.

coza
Àkọlé àwòrán, Isin oni ti pari ni COZA nigba ti Pasitọ Biodun Fatoyinbo ba awọn ọmọ ijọ sọrọ.

Awọn oluwọde n hó lé awọn ọmọ ijọ COZa lori ni Eko bi wọn ṣe n tu jade.

Isin oni ti pari ni COZA nigba ti Pasitọ Biodun Fatoyinbo ba awọn ọmọ ijọ sọrọ.

coza
Àkọlé àwòrán, Ariwo gee lori awon omo ijo lati enu awon oluwode

Àwọn olùwọ́de ń hó lé àwọn ọmọ ijọ COZA ni Eko bi wọ́n ṣe n jáde.

Modele Fatoyinbo, ìyàwó Biodun Fatoyinbo ti wọn fẹ́sùn kàn ni COZA ni kò ṣeéṣe fún ọkọ òun láti fipá bá ẹnikeni lòpọ̀.

fatoyinbo

Oríṣun àwòrán, @others

Àkọlé àwòrán, Ẹ ma ba ẹnikẹni ja nitori ọrọ mi

Nigba ti Pasitọ Biodun Fatoyinbo de sinu ijọ loni, o ki gbogbo awọn eniyan rẹ ku aduroti lasiko yii.

O gba wọn nimọran lati ma fun ẹnikẹni lesi nipa iṣẹlẹ ẹsun yii.

Sugbon ko waasu rara ninu isin toni.

O ni oun ti fa ọrọ ẹsun naa le awọn agba igbimo ijọ lati ṣe iwadii to yẹ ati awọn ẹni iwaju ti oun n wo.

Àkọlé fídíò, Widows Day 2019: Mo máa ń sá kiri wá owó ilé ni -Opó