Àabo ilẹ̀ Yoruba: Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ dára ṣùgbọ̀n ọ̀ràn lè tibẹ̀ jáde

Darandaran kan wa ninu igbo pẹlu awọn maalu rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty/LUIS TATO

Orọ eto aabo ipinlẹ Yoruba méféefa ti gba apero awọn gomina ati ori ade bayii.

Nibi apero ti awọn gomina ipinlẹ Yoruba pe ni Ibadan ni wọn ti fẹnuko pe nini awọn agbofinro ipinlẹ ti ṣe pataki lasiko yii.

Lẹyin ipejọpọ awọn gomina ilẹ Yoruba - ipinlẹ Oyo, Ogun, Ekiti, Osun, Eko ati Ondo - lori ọrọ aabo, ni paapaa, ọrọ ijinigbe to ti n gbilẹ ni agbegbe wọn, onimọ nipa ọrọ aabo kan, Patrick Agbamu ti ni wahala ti idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ yoo dasilẹ le ju ogun ti wọn fẹ ko ṣẹ lọ.

Agbamu sọ fun BBC Yoruba pe ko ṣeeṣẹ ki awọn ipinlẹ ti ko tii le san owo oṣu awọn oṣiṣẹ wọn ko le ṣakoso ọlọpaa Ipinlẹ.

O ni wahala ni yoo da silẹ ti awọn gomina ba bẹrẹ si ni jẹ ọlọpaa ni owo.

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Aabo to peye gbọdọ wa fawọn olutọju alaisan

Onimọ naa ni yatọ si eyi, idagbasoke ko ti i de ba ọrọ oṣelu ni Naijiria de ibi ti wọn fi le gbe iṣakoso ileeṣẹ ọlọpaa le awọn gomina lọwọ.

Ọrọ aabo ilẹ Yoruba ati ijinigbe to n gbilẹ ni agbegbe naa ti di ọrọ nla lọwọlọwọ bi awọn ọdaran darandaran ṣe bẹrẹ si ni ṣọsẹ.

Aarọ Ọjọru (oni) ni iroyin kan wi pe awọn ajinigbe da ọkọ elero mejidinlogun kan duro ni ọju ọna Akurẹ si Ado-Ekiti, ti wọn si ji awọn mẹwaa ninu ero inu ọkọ naa gbe.

Igba ti BBC Yoruba kan si kọmiṣọna fun ọlọpaa ni Ipinlẹ Ondo Undie Adie, o ni oun ko tii gbo nipa ọrọ naa.

Ẹgbẹ Afẹnifẹre ṣe ipade pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari ni ọjọ Iṣẹgun, ọrọ aabo wa lara ohun ti wọn ba aarẹ naa sọ.

Wọn ke pe aarẹ lati fi kun awọn agbofinro to wa ni agbegbe naa.

Àkọlé fídíò, International Day Against Drug Abuse and Trafficking: ìdí ti mo fi ń mu oògùn olóró

Agbamu ni ti orilẹ-ede Naijira ba gba ọlọpaa ipinlẹ laaye, ti ẹgbẹ oṣelu to wa lori aleefa ba ni aawọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu alatako ninu ipinlẹ kan naa, ko si bi ojuṣaaju ko ṣe ni wa ninuu bi awọn ọlọpaa naa yoo ṣe ṣe iṣẹ wọn.

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

Àkọlé fídíò, Widows Day 2019: Mo máa ń sá kiri wá owó ilé ni -Opó