Ile igbimọ asofin Naijiria da ijiroro lori aabo duro

Oríṣun àwòrán, @NGRSenate
Ile igbimọ asofin agba ti orilẹede Naijiria ti da ipade ijiroro ọlọjọ meji lori ọrọ aabo duro.
Ipade na ti o yẹ ki o waye lọjọ kini, osu keji si ọjọ karun osu keji ọdun yi, ni gbọngan ti o wa ni Ile-Ijọba, ni wọn gbekalẹ pẹlu iranwọ ile-isẹ aarẹ.
Atẹjade ti wọn fi s'ita wi pe, nitori eto isinku igbakeji aarẹ Naijiria tẹlẹri, Alẹx Ekwuẹmẹ ti wọn fẹ ẹ se lopin ọsẹ, lofa isunsiwaju ipade gbogboogbo naa.

Oríṣun àwòrán, AFP
Gẹgẹ bi ọrọ adari ẹgbẹ ti o pọ julọ nile igbimọ asofin, asofin Ahmed Lawan, sisun ijiroro lori eto aabo siwaju yoo faye silẹ fun awọn asofin agba lati fi gbogbo ara ko'pa ninu eto isinku igbakeji aare tẹlẹri naa.
Lawal sọ wipe ile-igbimọ yoo polongo ọjọ tuntun ti wọn ba mu fun ipade ijiroro lori eto aabo naa.








