Afenifere: Ìgbà wo ni Bola Tinubu di ọmọ ẹgbẹ Afenifere?

Kii ṣe ojulowo ọmọ ẹgbẹ afẹnifẹre lo lọ si Abuja lọdọ Buahri -Odumakin
Lẹyin ti iroyin sọ pe Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣe ipade pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ Afẹnifẹre, agbẹnusọ ẹgbẹ naa, Yinka Odumakin ti ni awọn ayederu ọmọ ẹgbẹ Afẹnifẹre lo lọ ibi ipade naa.
Odumakin sọ fun BBC Yoruba wi pe: "Afenifẹre ko ṣe ipade kankan pẹlu Buhari.
Igba wo ni Bola Tinubu, to ko awọn eniyan lọ iwaju Buhari di aṣoju Afẹnifẹre?
Tinubu ko awọn ọmọ ẹgbẹ APC rẹ lọ bẹ aarẹ wo ni. Ko si ohun to kan awa Afenifere nibẹ"
A ti kọkọ mu iroyin naa wa wi pe, ẹgbẹ Afẹnifẹre beere nibi ipade naa idi ti Buhari ṣe yọ Adajọ agba ana ni Naijiria, Walter Onnoghen niṣẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ṣugbọn Afẹnifẹre ni awọn to lọ ibi ipade naa, ba ọrọ ara wọn lọ ni.

Oríṣun àwòrán, others
Nigba ti akọroyin wa ran Odumakin leti wi pe, Baba Ayo Fasanmi wa ninu ipade naa, o ni Baba Fasanmi kii ṣe ọmọ ẹgbẹ Afẹnifẹre nitori pe ko wa si ipade ẹgbẹ naa mọ.
Lori ipade awọn gomina ilẹ Yoruba lori ọrọ aabo ti wọn ba Buhari sọrọ le lori, Odumakin ṣalaye pe, ipade ẹ̀tàn ni wọn n ṣe.
O ni awọn ti o mọ nipa ọrọ aabo ilẹ Yoruba bii adari ẹgbẹ OPC, Aarẹ Gani Adams, lo yẹ ki wọn gbọ lẹnu rẹ, ni eyi ti wọn ko gbọ lati ẹnu wọn.
Buhari ṣepade pẹlu ọmọ ẹgbẹ Afẹnifere
Ninu ipade naa Buhari ṣalaye kikun lori idi ti oun fi yọ olori oko eto idajọ Naijiria ni ṣe, iyẹn Walter Onnoghen lori ẹsun ajẹbanu.
Lẹyin ti wọn ni ki Onnoghen lọ rọọkun nile ni o ba kuku kọwe ifẹyinti funra rẹ lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu karun un, ọdun yii.
Aarẹ Buhari ni ko dun mọ oun ninu lati yọ Onnoghen ṣugbọn nigba ti iwadii fihan pe owo gọbọi ni wọn ba ninu asuwọn rẹ.
O ni: o maa n yamilẹnu irufẹ ẹri ọkan ti awọn eniyan Naijiria ni, nigba ti iwọ ti o n sọ awọn eniyan sẹwọn ko tun le tẹle ofin.
Ati pe Onnoghen mọ ohun to le ṣẹlẹ si aikede dukia oun gẹgẹ bi adajọ agba ni Naijiria.
Buhari ni oun yoo maa tun ọrọ oun sọ lori gbigbogun ti iwa jẹgudu jẹra nitori eyi jẹ iṣe oun lati igba ti oun ti wa nijọba ologun Naijiria.
Ko si ẹni ti ọwọ́jà igbogunti iwa ajẹbanu mi ko ni kan ti aṣiri wọn ba ti tu.
Senetọ Olabiyi Durojaye tó jẹ aarẹ Afẹnifẹre ki Buhari ati Osinbajo igbakeji rẹ ku oriire wiwọle wọn leekeji.
O gboriyin fun ijọba fun yiya June 12 sọtọ ni ọjọ iṣejọba awa ara wa ni Naijiria.
Wọn kii ku iṣẹ ti ijọba n ṣe lori ọkọ oju irin ati ọna marosẹ Ibadan.
Durojaye ni oun to ku ti iran Yoruba fẹ lasiko yii ni pe ki wọn gbajumọ iṣoro to n koju eto aabo Naijiria.
O ni ọrọ eto ẹkọ wa n fẹ amojuto paapaa ọrọ airiṣẹ ṣe awọn ọdọ.
Ni ipari wọn ni ojutu wahala Naijiria ni ki ijọba ri si ọrọ ina mọnamọna ati eto ọgbin fun idagbasoke to yẹ.















