Amoṣun: Mo gba àṣẹ lọ́wọ́ Jonathan láti dá iléeṣẹ́ aláàbò sílẹ̀ àti ríra ohun ìjà olóró

Ibikunle Amosun

Oríṣun àwòrán, @SIAmosun

Gomina ana nipinlẹ Ogun, Sẹnetọ Ibikunle Amosun, ti fesi lori iroyin kan to n ja rainrain nilẹ.

Iroyin na n jà kiri lori awọn oju opo ikansira ẹni lori ayelujara pe, oun ra ọpọ ohun ija oloro pamọ saaju eto idibo gboogbo to kọ̀ja, lati da rugudu silẹ nipinlẹ Ogun.

Atẹjade kan ti agbẹnusọ fun Ibikunle Amosun, Rotimi Durojaye fọwọsi kede pe, ti ko ba si ẹsẹ, ẹsẹ kii dede sẹ.

O ni aifararọ eto aabo ti Amosun ba nilẹ lasiko to tẹwọgba ọpa asẹ lati tukọ ipinlẹ Ogun losu Karun un, ọdun 2011, lo fa sababi bo se ra awọn ohun ija oloro naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Ṣé ẹ̀yin lè ṣe jú àwọn tó f'àmì sí Awọlumatẹ?

Amosun ni, lọdun 2011, isoro nla kan gboogi to n ba ipinlẹ Ogun finra ni aifararọ eto aabo, ipaniyan nitori oselu, ipani nipakupa lainidi to pọ nigba naa, eyi to mu kawọn ileesẹ nlanla dẹnu kọlẹ, ti ọrọ aje ipinlẹ Ogun si dorikodo.

Àkọlé fídíò, Widows Day 2019: Mo máa ń sá kiri wá owó ilé ni -Opó

O fikun un pe ọpọ ile ifowopamọ lo gbe ilẹkun wọn ti nitori eto aabo to mẹhẹ nigba naa, ti ko si sẹni to lee sun, ti yoo di oju mejeeji lasiko ọhun.

Amosun salaye pe, niwọn igba to si jẹ pe ko lee si idagbasoke nibiti rudurudu ba wa, idi ree ti oun fi se agbekalẹ ajọ ẹdawo fun eto aabo nipinlẹ Ogun, Ogun State Security Trust Fund, STF.

Àkọlé fídíò, Tomomewo Favour: olóṣèlú kìí ṣe ọ̀daràn tàbí alágbèrè

Atẹjade naa fikun pe, Amosun tun tọ aarẹ orilẹ-ede yii nigba naa, Goodluck Jonathan lọ, lati beere asẹ fun agbekalẹ ajọ OP MESA, ti wọn si ra awọn ohun ija fun wọn pẹlu owo gọbọi.

Koda o fikun un pe, ọọfisi oludamọran feto aabo fontẹ lu rira ọkọ ijagun mẹtala, ibọn AK 47 ẹgbẹrun kan, ẹwu ayẹta ẹgbẹrun kan, awọn ohun ija lorisirisi to to miliọnu meji, ọta ibọn ẹgbẹrun kan, ate ayẹta bii ẹẹdẹgbẹta, to fi mọ awọn ohun eelo ibaraẹnisọrọ lorisirisi.

Ibọn ati ọta ibọn

Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy

Amosun ni irọ to jinna sootọ ni pe wọn tete fa awọn ohun ija oloro naa le awọn ọlọpa lọwọ, ki gomina tuntun to fẹ gba akoso, Dapọ Abiọdun ma baa ri wọn.

O ni ohun to panilẹrin ni iroyin eke naa nitori pe Dapọ Abiọdun gan lo jẹ eeyan kan gboogi to ta ọpọ awọn ohun ija naa, paapa awọn ọkọ ijagun .

Àkọlé fídíò, International Day Against Drug Abuse and Trafficking: ìdí ti mo fi ń mu oògùn olóró

Amosun wa rọ awọn araalu lati kẹyin si iroyin eke to n lọ kiri naa pe ohun ko ohun ijagun pamọ nitori pe ko si awo kankan ninu awo ẹwa nipa awọn ohun ija oloro naa.

Àkọlé fídíò, Mo máa n forin mi kìlọ̀ ìwà ìbàjẹ́ láwùjọ ni -Hameen

O fikun pe oju awọn akọroyin si ni ohun fa awọn ibọn AK 47 naa le awọn ọlọpa lọwọ, ti awọn ohun ijagun yoku si wa ni ipamọ nile ijọba ipinlẹ Ogun, eyi to wa labẹ abojuto awọn agbofinro.