Ǹjẹ́ tí o kò bá jẹ sààrì ṣáájú ààwẹ̀ lè ṣe àkóbá fún ìlera rẹ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Saari jẹ ounjẹ ti awọn musulumi ma n jẹ ni idaji ṣaaju ki wọn to bẹrẹ awẹ fun ọjọ naa.
Jijẹ ounjẹ ni asiko saari wa ni ilana Islam ṣugbọn ko jẹ dandan ki eeyan tabi olujọsin jẹ ounjẹ ni asiko yii.
Aṣẹ jijẹ ounjẹ ni asiko jẹ ohun ti wọn n pe ni 'mustahabbi', eyi to tumọ pe gbogbo eeyan lo gbọdọ jẹ ounjẹ ni asiko yii, ṣugbọn to ba jẹ, ko tumọ si pe o ti da ẹsẹ.
Ẹwẹ, awọn eeyan kan wa ti wọn ko ki n jẹ saari lasiko awẹ fun ọpọ idi
Ṣugbọn ibeere ti a fẹ ṣalaye ni bawo ni ai jẹ saari ṣe le ṣakoba fun ilera rẹ?
A gbe ibeere yii lọ ba Dokita Hassan Ibrahim ti ile iwosan Biba nipinlẹ Kaduna.
Dokita ni o ṣeeṣe ki ai jẹ Saari ṣe akoba fun ilera ẹni to ba n gba awẹ nitori o ni aṣiko ti ara eeyan le wa lai si ounjẹ, ti eeyan ko ba jẹ ounjẹ ni awọn aṣiko yii, ounjẹ le maa tete daa ni ara.
"Ounjẹ ti a n jẹ ni idaji yii wa fun wakati mẹrin akọkọ, lẹyin eyi ni ara yoo ma lo ohun iṣa loore to ti fi pamọ si ara tẹlẹ.
"Ti eeyan ko ba jẹun, ara yoo bẹrẹ si ni ma lo awọn nnkan to ti fi pamọ tẹlẹ, idi ree ti ara awọn eeyan bẹẹ fi ma gbona," Dokita ṣalaye.
O fikun pe ti eeyan ba jẹun lasiko saari, o ni Ibukun ni fun iru eeyan bẹẹ nitori ago ara rẹ yoo ri nnkan gbe ara le.
"Irẹwẹsi yoo ba awọn ago ara eeyan ti ko ba jẹ saari. Ti eeyan ba jẹ saari, ara rẹ yoo ji pepe, ti yoo ṣe alekun fun alaafia.
"Ai jẹ ṣaari le ṣekoba nla fun ago ara eeyan," dokita ṣalaye.
N jẹ mumu omi nikan to fun Saari?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Dr. Hassan Biba ni ohun to da ju ni pe ki eeyan po omi naa pọ pẹlu nnkan mii lasiko awẹ, to ri omi ṣe koko.
"Imọran to da ju ni ki eeyan jẹ ounjẹ lẹyin ti o ba mu omi tan. Ko pọn dandan ki eeyan jẹ ounjẹ pupọ, nitori o le ma ṣe anfani fun ago ara ," Dr Hassan sọ.
O fikun pe o ṣe ara loore ki eeyan jẹ ounjẹ to kun fun eroja protein.
Jẹ awọn ounjẹ bii wheat, barley, ẹwa, tabi lentils.
"Ti o ba jẹ awọn bayii, wọn ki n tete da ni ago ara, ti yoo se ara loore fun igba pipẹ lasiko awẹ." Dokita ṣalaye.
Bakan naa lo gba ni imọran pe ki awọn eeyan yago fun ounjẹ to ni ọpọ suga ninu lasiko awẹ, paapa lasiko saari.


























