Àwọn ajínigbé jí ọkọ àti ìyàwó gbé lọ nílùú Abo l'Akure, aráàlú ṣe ìfẹ̀hónúhàn lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìjinigbé tó ń wáyé léra léra

Kaka ki ewe agbọn dẹ, ṣe lo n le koko si lọrọ awọn janduku agbebọn ti wọn tun ji tọkọ taya gbe lọ ni Ilu-Abo nijọba ibilẹ Akure nipinlẹ Ondo.
Ni ọjọ Ẹti ọsẹ yi ni awọn agbebọn ṣekọlu si Aafin Alagamo tilu Agamo ti wọn sẹkupa ọba ilu naa, Ọba Kehinde Falodun ni ijọba ibilẹ Akure kan naa.
Eyi lo mu ki awọn ara ilu naa se ifehonuhan ni owurọ oni ọjọ Abamẹta, ọjọ kokanlelogun oṣu keji ọdun 2026, lati kepe ijọba ki wọn le wa ojutuu si ọrọ ijinigbe ati ikọlu awọn agbebọn to n ṣẹlẹ lera lera ni agbegbe naa.
Awọn olugbe Ilu-Abo fi ẹhonu han bi wọn ṣe gbé igi di opopona marose Akure si ilu Ọwọ ati awọn opopona miran to wa ni ayika ilu naa.
Awọn ara ilu naa sọ pe awọn yoo ri daju pe gbogbo ilu mọ isoro eto abo ti awọn n koju.
Wọn dẹbi ru Gomina Lucky Aiyedatiwa pe ṣe ni o ka ọwọ gbera lori ọrọ abo naa to si jẹ pe loorekoore ni awọn agbebọn yi n wa si ijọba ibilẹ Ariwa Akure lati sọsẹ.
Kí ló ṣẹlẹ̀ gan an?
Awọn olugbe agbegbe naa to ba ileeṣẹ BBC Yoruba sọrọ salaye pe ní asalẹ ọjọ Ẹti ni awọn gbọ iro ibọn.
Wọn ni ki awọn to mọ ohun to n sẹlẹ, awọn agbebọn naa ti ji tọkọ taya gbe lọ.
Awọn araalu naa salaye pe ọta ibọn ba okunrin kan to jẹ aladugbo awọn tọkọtaya naa.
Awọn olugbe Ilu-Abo ni awọn ko le sun, ko le wo mọ latari okan o jọkan ikọlu, ipaniyan ati ijinigbe to n waye lemọ lemọ ninu ilu naa.
Wọn salaye pe ọjọ ti pe ti awọn esọ alaabo ati ijọba Ipinlẹ Ondo ti n se ileri lati fopin si iṣẹlẹ ijinigbe ni agbegbe naa, sugbọn titi di akoko yi, ko si riri ti wọn ri.
Kí ni àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò sọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ijinigbe yìí?
Alukoro ileeṣẹ Ọlọpaa Ipinlẹ Ondo, Jimoh Abayomi, ẹni to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ salaye pe, ní deedee ago mẹwa ku isẹju marundinlogun ni ogunjọ oṣu Keji ni awọn gbọ nipa iṣẹlẹ naa.
O salaye pe awọn agbebọn ṣekọlu si ọgbẹni Jamiu Olawale ati aya rẹ, ti wọn jẹ olugbe adugbo Olaribigba ni Ilu-Abo.
Alukoro naa sọ pe awọn tọkọ taya naa ṣeṣẹ de lati ibi isẹ ninu ọkọ ayokele Camry wọn lasiko ti awọn agbebọn naa de ti wọn si ji wọn gbe lọ.
O salaye pe ibi ti wọn gbe wọn wọ ni ko tii di mimọ si ẹnikẹni.
Ọgbẹni Abayomi salaye pe ibọn ba arakunrin kan Patrick Ilumaro ẹni to jẹ aladugbo tọkọ taya naa.
O sọ pe iwaju ile rẹ lo wa lasiko ijinigbe naa, ti ọta ibọn si lọ ba nibẹ, Arakunrin naa wa nile iwosan bayi nibi ti o ti n gba itọju.
Alukoro Ọlọpaa sọ pe kete ti iṣẹlẹ naa waye, ní Kọmisọna Ọlọpaa nipinlẹ Ondo Adebowale Lawal ti ko awọn esọ alaabo lọ ilu naa lati wọ gbogbo igbo ati awọn ibi ti awọn ajinigbe naa le wa.
O sọ pe awọn esọ alaabo ti ń ṣe isẹ lati ri daju pe wọn doola ẹmi awọn tọkọtaya naa, ki wọn si fi awọn agbebọn naa jofin.
Bakanna, ọga agba ajọ Amotekun nipinlẹ Ondo, Adetunji Adeleye, ẹni tó sabewo si ilu naa parọwa si awọn olugbe ilu yi, pẹlu aridaju pe omi alaafia yoo ru ninu ilu naa laipẹ.
O sọ pe Ajọ naa ati awọn esọ alaabo miran ti ń ṣe isẹ lati fopin si ijinigbe ati ikọlu nijọba ibilẹ Ariwa Akure.



























