Ekiti: Lẹ́yìn t'áwọn kan gba òmìnira, wọ́n tún jí òṣìṣẹ́ kánsù míràn gbé

Agbebọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Iru ijinigbe yii gbilẹ nipinlẹ Ondo to muleti ipinlẹ Ekiti ni 2018.

Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Caleb Ikechukwu sọ pe lootọ ni awọn ajinigbe tun ji awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ mi i gbe nipinlẹ naa.

Ikechukwu sọ fun BBC Yoruba pe ni ọjọ Aje, ọjọ keje Osu kinni ni awọn ajinigbe naa gbe awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ Gbọnhin kan, ati awakọ rẹ gbe, ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpaa ti doola awakọ naa lọjọ Aje yii kan naa.

Ṣaaju ni iru iṣẹlẹ yii waye ni ọjọ keji oṣu kinni ọdun 2018 nibi ti awọn ajinigbe ti ji awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ Emure to wa nipinlẹ Ekiti gbe.

Awọn mejeeji ọhun, ni wọn gbe loju ọna to so Ikẹrẹ, Isẹ ati Emure pọ, ni nnkan bi aago mẹjọ alẹ.

Ṣugbọn wọn pada gba ominira lẹyin ọjọ perete.

Iru ijinigbe yii gbilẹ nipinlẹ Ondo to muleti ipinlẹ Ekiti ni 2018, paapa loju ọna to lọ lati ilu Ọwọ si Ikarẹ-Akoko, ti awọn kan si n fi ẹsun kan pe awọn daran-daran Fulani lo wa nidi iṣẹlẹ naa. Ileeṣẹ ọlọpaa tako eyi.