Amnesty International: Àwọn agbófinró ń fìyà jẹ àwọn èèyàn púpọ̀ jù ni Nàìjíríà

olopaa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Amnesty International: Àwọn agbófinró ń fìyà jẹ àwọn èèyàn púpọ̀ jù ni Nàìjíríà

Ajọ to n mojuto ọrọ alaforijin ni agbaye ti a mọ si Amnesty International ni awọn eleto aabo Naijiria ṣi n fiya ti ko tọ jẹ awọn eeyan.

Atẹjade ti Amnesty International fi sita ni ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu kẹfa ló sọ eyi di mimọ.

Wọn sọọ nibi ayajọ isami ọjọ awọn ti a fiya jẹ lọna aitọ lagbaye.

Pataki atẹjade naa ni lati pe akiyesi ijọba Naijiria si koko pe awọn oṣiṣẹ eleto aabo Naijiria n fiya jẹ awọn eniyan lọna aitọ.

O ni ki wọn fopin si ifiyajẹni ti ko ba ofin mu.

Amnesty International ti Naijiria ti ni awọn ṣi n gba iroyin to fidi ẹ mulẹ pe awọn oṣiṣẹ eleto aabo n gbe igbesẹ ti ko yẹ lati wadii ọrọ.

Wọn ni ohun to n dun awọn ni pe ijọba Naijiria ko gbe igbese lati mojuto awọn iṣẹlẹ wọnyii.

Amnesty International gba pé eyi n jẹ ki awọn agbofinro lọ laijiya ẹṣẹ wọn.

Àkọlé fídíò, ọ̀gá ọlọ́pàá sọ̀rọ̀ lórí SARS

Wọn ni nitootọ ni: 'Nitootọ ni Naijiria ti gbe ofin kalẹ lori gbigbogun ti iwa ifiyajẹni lọna aitọ loṣu kejila ọdun 2017.

Sibẹ iroyin ni àwọn ọlọpaa SARS ṣi n lo ipa ninu iwadii.

Àkọlé fídíò, Agbenusọ fun ile isẹ ọlọọpa ni ipinlẹ Ondo ni iwadii ti bẹrẹ ni pẹrẹwu lori isẹlẹ naa.

Osai Ojigho to jẹ adari Amnesty International ni Naijiria ni ni ko tii si ẹni ti ijọba mu ti wọn de foju ẹ wina ofin ninu awọn oṣiṣẹ eleto aabo wọn.

Àkọlé fídíò, International Day Against Drug Abuse and Trafficking: ìdí ti mo fi ń mu oògùn olóró