Mo kọ́kọ́ takú láti fẹ́ Bimpe àmọ́ ìdí rèé tí mo ṣe fẹ́ ẹ - Lateef Adedimeji

'Ó sàn kí ẹ pa mí ju kí n fẹ́ òṣèré lọ, àmọ́ nkan tó jẹ́ kí n fẹ́ Bimpe rèé'

Lateef ati Adebimpe

Oríṣun àwòrán, Others

Fun igba akọkọ, gbajugbaja oṣerekunrin, Lateef Adedimeji, ti sọrọ nipa bi igbeyawo oun ati Adebimpe ṣe waye.

Oṣu Kọkanla, ọdun 2021 ni awọn gbajumọ osere mejeeji ṣe igbeyawo lẹyin ọpọlọpọ gbọyi-sọyi iroyin pe wọn n fẹ ara wọn.

Ni ọpọlọpọ igba si ni awọn mejeeji ti ṣẹ̀ pe ko si nkankan laarin awọn to jọ ọrọ ifẹ yatọ si iṣẹ ati pe awọn jẹ ọrẹ.

Eyi lo mu ko jẹ iyalẹnu fun ọpọlọpọ awọn ololufẹ wọn ati awọn mii, nigba ti wọn kede ọjọ ayẹyẹ igbeyawo wọn.

Amọ Lateef Adedimeji ti wa salaye idi tawọn mejeeji se fẹra wọn lasiko to kopa nibi eto ijiroro kan pẹlu awọn ọdọ, eyi ti gbajugbaja akọrin, Shola Allyson ṣe.

"Wara wara ni sinima ti mo ba se pẹlu Bimpe maa n ta ju eyi ti mo ba se pẹlu awọn miran lọ"

Ninu ọrọ rẹ niwaju ọpọ alejo to wa nibi eto naa, Adedimeji sọ pe oun ko ni erongba rara lati fẹ iyawo to jẹ oṣere bi t’oun.

O ni koda, oun ma n sọ pe “o pe mi ki ẹ pa mi, ju ki n fẹ ẹni to n ṣe iṣẹ tiata ti mo n ṣe”.

Adedimeji ṣalaye pe ọrẹ ni oun ati Bimpe, ti ko si si erongba lati jọ jẹ ololufẹ lọkan awọn rara.

“Ṣugbọn awọn oriṣiriṣi iṣẹlẹ n ṣẹlẹ laarin wa, eyi to n fihan pe kadara wa papọ.

“Fun apẹẹrẹ, awọn fiimu ti emi ati Bimpe ba jọ sẹpọ ma n ni aṣeyọri ju eyi ti mo ba da sẹ lọ tabi ṣe pẹlu ẹlomii.”

“Eyi jẹ ki n ma a ro pe, iru ki leyi? Amọ sibẹsibẹ, mi o gbero lọkọlaya pẹlu rẹ.”

Lateef sọ pe yatọ si pe Adebimpe naa jẹ oṣere, o ni nkan mii to tun wa nibẹ ni pe idile Musulumi ni oun ti wa, ti Bimpe si jẹ Kristiẹni.

“Baba mi ko gbọdọ gbọ pe ẹlẹsin Kristiẹni ni mo fẹ ẹ fẹ ni iyawo, bẹẹ naa ni ọrọ ri nile awọn Bimpe naa.

"Iya mi n kaya soke pe se n ko le se bii ọmọkunrin, ni ko jẹ ki n mu iyawo wa sile"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lateef Adedimeji fikun pe sugbọn nkan yi pada nipa iha ti awọn mejeeji kọ si ọrọ ifẹ nibi iṣẹ sinima kan ti wọn jọ ṣe.

Lateef Adedimeji sọ pe nibi ti awọn ti n ya fiimu Ige, to jẹ ti Toyin Abraham, ni ẹnikan to da bi iya fun wọn ti kọkọ sọ asọtẹlẹ pe wọn yoo fẹra wọn.

Amọ oun n ro o pe ‘’ki ni iya yii ri, to fi n sọ asọtẹlẹ bayii’’’.

Lẹyin ti wọn pari sinima yii, ni iya Lateef pe e lọjọ kan nipa ọrọ iyawo.

O ni iya oun pe oun ni owurọ ọjọ kan pe ṣe oun ko le ṣe gẹgẹ bi ọmọkunrin ni tabi oun ni iṣoro kankan, ti oun ko fi tii mu iyawo wale.

“Iya mi ni bo se Bimpe ti ẹ jọ n ṣe fiimu ni, ṣa a mu wa sile.

“Amọ ibẹru ohun ti baba mi yoo sọ nipa rẹ ṣi wa ni ọkan mi."

O ni oriṣiriṣi iṣẹlẹ lo ṣẹlẹ lẹyin asiko naa, ko to o di pe awọn mejeeji bẹrẹ si ni fẹ ara wọn.

Bakan naa lo ni nigba to ya, pẹlu ibẹru ni oun fi sọ fun baba oun pe Bimpe ni oun fẹ ẹ fẹ.

Ọrọ naa kọkọ dori agba baba rẹ kodo, amọ nigbẹyin, o ni ọrọ ẹsin awọn mejeeji to yatọ ni nkan.

Bakan naa si ni ọrọ se ri ni ọdọ awọn obi Adebimpe naa.

Lateef ati Adebimpe

Oríṣun àwòrán, Adebimpe/Instagram

"O se pataki ki takọ-tabo se akiyesi isẹlẹ to ba n waye si wọn lasiko ti wọn ba n fẹ ara wọn"

Ṣugbọn nigbẹyin, ẹbi mejeeji fi ọwọ si pe ki wọn o fẹra wọn lai fi ti ẹsin ọtọọtọ ṣe.

Lateef Adedimeji sọ pe igbeyawo awọn ko ni nkankan sẹ nipa ẹsin amọ iṣẹda.

O ni o ṣe koko ki awọn ọdọ to ba fẹ ni ọkọ tabi iyawo ṣakiyesi awọn iṣẹlẹ to n ṣẹlẹ laarin wọn.

O kadi ọrọ rẹ nilẹ pe, o ṣeeṣe ki oun ma ri iru atilẹyin, ibawi, ati imoriwu ti Adebimpe n ṣe fun oun lori iṣẹ tiata, to ba jẹ pe ẹlomiran ni oun fẹ.