Orí kó Lateef Adedimeji yọ lọ́wọ́ ikú òjijì, ló bá mú orin ọpẹ́ sẹ́nu

Oríṣun àwòrán, Instagram/Lateef Adedimeji/screenshot
Gbajumọ oṣere tiata, Lateef Adedimeji ti sọrọ sita pe diẹ lo ku ki oun ba ijamba ọkọ lọ lọjọ diẹ sẹyin ki ori to ko oun yọ. Adedimeji tu ọrọ yii sita lasiko to fi n fi orin ọpẹ sita lati fi imore han fun Ọlọrun loju opo Instagram rẹ.
Adedimeji ṣalaye pe niọjọ diẹ sẹyin ni ijanu ọkọ oun kan ṣa dede ja lori ere ṣugbọn ti ori ko oun yọ lọwọ ijamba iku ojiji.

Oríṣun àwòrán, Instagram/lateef adedimeji/screenshot
“Iyin ni fun Ọlọrun alagbara. Melo ninu ore rẹ ni mo le ka tan? mo dupẹ fun ifẹ rẹ, mo dupẹ fun idile mi, mo dupẹ fun iyawo mi, O ṣeun ti o gba mi la, ti mo fi moribọ lọwọ iku lọjọ diẹ sẹyin nigba ti ijanu ọkọ mi kọṣẹ silẹ, ore ọfẹ rẹ ni...” Iṣẹlẹ yii n waye pẹlu bi ayajọ ọdun kan ti Lateef Adedimeji gbe aya rẹ, Mo Bimpe niyawo ṣe ku si dẹdẹ.








