Tinubu ṣé ìpàdé pẹ̀lú àwọn ádárì Mùsùlùmí Ibadan, ìlérí tó ṣe fún wọn rèé

Tinubu

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Lẹyin ti akojọpọ awọn Kristẹni kan ni Ibadan gbadura fun un, oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress, Asiwaju Bola Tinubu ti ṣepade pẹlu awọn adari Musulumi niluu Ibadan kan naa.

O ṣe ileri pe ti wọn dibo fun oun lọdun 2023 gẹgẹ bii aarẹ, iṣejọba oun yoo mu ilọsiwaju ba eto ọrọ aje orilẹede Naijria

Tinubu ṣo eleyi nigba to ṣe ipade pọ awọn adari Musulumi lati Guusu Iwọ-Oorun ni Ibadan, olu ilu ipinlẹ Oyo, lọjọ Aiku ọsẹ yii.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ Tinubu, Tunde Rahman fi lede fun awọn akọroyin lẹyin ipade naa, Tinubu ni orilẹede Naijria ko gbọdọ gbe ọkan le nnkan alumọni nikan lati mu ilọsiwaju ba eto ọrọ ajẹ .

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

“Ti a ba ṣe bayi, ayipada yoo de ba orilẹede wa, ti awọn eeyan to ba fẹ sisẹ yoo si ri anfani naa pẹlu.

Sugbọn a nilo lati ṣe arawa lọkan, ki a si ran awọn eyan ti wọn ko ri iranwọ lọwọ, "ẹ jẹ ka ran wọn lọwọ."

Bakan naa, Tinubu rọ awọn adari ẹsin naa lati rii pe awọn alatilẹyin oun jade lati dibo ninu eto idibo aarẹ lọdun to n bọ, ki wọn si rii pe wọn dibo fun olori to ni oye ati iriri lati tukọ orilẹede Naijiria.

“Mo rọ yin lati sọ awọn alatilẹyin pe ki wọn jade dibo, ki wọn si dibo fun olori to ni oye ati iriri, eyi ti yoo mu alaafia ati ifọkanbalẹ wa si orilẹede Naijiria.

“Mo n ṣe ileri fun yin pe maa rii pe mo ṣa gbogbo ipa lati rii pe a wa ojutu si awọn nkan yii, ti ẹ dibo fun mi lọdun 2023.

Tinubu nìkan ló lè ṣe é, Àjọ Krìstẹ́nì ṣé àkànṣe àdúrà fún Tinubu n'Ibadan

Aworan

Oríṣun àwòrán, BOLATINUBU/FACEBOOK

Ọtun-Apesinọla ti ilẹ Ibadan, Oloye Dotun Sanusi ni ọjọ Satide ko awọn Kristẹni kaakiri ipinlẹ Ọyọ jọ lati gbadura fun oludije ṣipo aarẹ ti ẹgbẹ All Progressives Congress (APC), Asiwaju Bola Ahmed Tinubu. Ṣaaju ni awọn Musulumi ni ipinlẹ Ọyọ ti pejọ si ibi kan naa lati gbadura ati lati fọwọ si Tinubu gẹgẹ bi oludije ti wọn fẹ fun ibo aarẹ 2023. Bakan naa, awọn ẹlẹṣin abalaye yoo pejọ ni Satide to n bọ, ọjọ Ketadinlogun Oṣu Kejila lati gbaruku ti oludije ṣipo aarẹ Bola Tinubu, ki wọn si gbadura fun aṣeyọri erongba rẹ.

Awọn to wa nibi akanṣe eto adura naa ni alaga ẹgbẹ onigbagbọ Christian Association of Nigeria, (CAN) nilu Ibadan, igbakeji alaga rẹ, awọn alaga ẹgbẹ onigbagbọ ni Lagelu, Ido, Ibadan South West, Ibadan North, Ibadan North West, Egbeda, Akinyele, Oluyole, Ibadan South West bakan naa.

"Kii ṣe tori ere ara mi ni mo ṣe ni Tinubu lo le ṣe e"

Nigba to n sọrọ nibi akanṣe adura naa. Sanusi, ẹni ti Mogaji Nurudeen Akinade ṣoju wipe ki awọn ọmọ orilẹede yii ma fi ẹsin tabi eleyameya ṣee ki orilẹede yii le tẹsiwaju. O ni Bola Ahmed Tinubu nikan ni o le mu idagbasoke bá orilẹede Naijiria.

Sanusi ṣakiyesi pe gbogbo ohun ti oun n ṣe fun Bola Tinubu ko ṣẹyin ifẹ si orilẹ-ede yii kii ṣe fun ere ara ẹni.