Rògbòdìyàn ìlú sí ìlú gbẹ̀mí káńsílọ̀ àti fijilanté l’Ondo

Oríṣun àwòrán, afp/getty images
Rogbodiyan ilu si ilu kan to waye laarin ọjọ Ẹti, ọjọ kẹsan an si ọjọ Abamẹta ọjọ kẹwaa oṣu kejila nilu Kajọla ti Koseru nijọba ibilẹ Odigbo, nipinlẹ Ondo ti gbẹmi awọn eeyan ti ko din ni meji.
Ọpọ dukia pẹlu ere oko ni awọn janduku bajẹ lasiko rogbodiyan naa.
Bawo ni iṣẹlẹ naa ṣe waye?
Gẹgẹ bi atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo, SP Funmilayọ Ọdunlami-Omisanya fi sita ṣalaye pe wahala naa bẹrẹ nigba ti awọn ọkunrin meji ti wọn fi iboju bo oju ara wọn kọlu obinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Julianah Alaba Abẹjoye loko rẹ to wa lagbegbe Ogbontiba nitosi Kuseru.
Ibọn ṣakabula oloju meji ni wọn yin si obinrin naa, ṣugbọn ori koo yọ o si sa asala fun ẹmi rẹ pẹlu ọgbẹ ni apa ati itan rẹ. Wọn fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti ni agọ ọlọpaa ẹkun Kajọla ki wọn to gbe e lọ si ile iwisan fun itọju.
Nigba ti o di agogo mẹwaa lọjọ Satide lawọn ọdọ lati ilu Ayetoro ya bo ilu Kuseru lati gbẹsan.
Awọn ọdọ naa da ina sun ibudokọ awọn ọlọkada, ohun ọsin, awọn ọkada, bẹẹni wọn si ge ọpọlọpọ igi ọgẹdẹ lulẹ.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn agbofinro ti wọn da si agbegbe naa lati da alaafia pada ri awọn oku awọn fijilante ni afin balẹ ilu Kuseru ti wọn ni awọn ọdọ naa ṣeku pa lasiko ikọlu naa.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Kansilọ ati fijilante ni wọn pa- Amọtẹkun
Iroyin abẹle sọ pe kansilọ to n ṣoju wọọdu koseru ati fijilante kan ti wọn ni orukọ rẹ n jẹ Kayọde ni wọn pa.
Ninu ọrọ ti amugbalẹgbẹ fun gomina ipinlẹ Ondo lori ọrọ abo, Oloye Adetunji Adelẹyẹ to tun jẹ ọga agba ikọ Amọtẹkun nibẹ ṣalaye pe wọn ti ko awọn oku naa lọ si ile igbokusi.
Oloye Adelẹyẹ ni ko si oṣiṣẹ agbofinro Amọtẹkun kankan to fara kaasa ikọlu naa, to si tun fi kun un pe alaafia ti pada jọba ni agbegbe naa bayii.
“Dukuu ọjọ pipẹ ti wa ni Koseru laarin idile Oluku ti ikalẹ ni Okitipupa pẹlu awọn agbẹ Ọyọ /Ọṣun to n gbe nijọba ibilẹ Odigbo. Agbẹ paraku lawọn Ọyọ/Ọṣun yii, ọpọ igba ni wọn si ti n ja lori ọrọ ilẹ.












